Gomina Seyi Makinde la n fi ẹsun kan pe o da ibẹru oselu silẹ tori o ti pasẹ fawọn awakọ ero pe ki wọn maa lo ami idamọ ẹgbẹ oselu APM nikan soso lẹnu isẹ wọn - APC Oyo

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat
Se ni ọrọ di boo lọ, ko yago fun mi ni adugbo Molete nilu Ibadan nigba ti awọn janduku kan ya bo awọn mọto ipolongo ibo Alhaji Oriyomi Hamzat to jẹ oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oselu Accord, to tun jẹ gbajumọ agbohunsafẹfẹ ati oludasilẹ redio Agidigbo FM.
Oriyomi, gẹgẹ bi awọn ololufẹ rẹ se maa n pe e, lo n de lati ilẹ UK, ti awọn ọmọ ẹgbẹ oselu rẹ si lọ kii kaabọ pada sile nilu Ibadan pẹlu ọkọ ipolongo ibo rẹ, tawọn eeyan naa si tun wọ asọ idamọ ẹgbẹ oselu Accord, to ni awọ Yẹlo.
Jàǹdùkú kọlu áwọn olólùfẹ́ Oriyomi Hamzat, wọn ṣá wọn ní àdá, gún ìgò, sọ wọn ní òkúta, èèyàn kan kú, ọ̀pọ̀ tó farapa dèrò ilé ìwòsàn
Gẹgẹ bi awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn se wi, owurọ ọjọru ana ni isẹlẹ naa waye ni adugbo Molete nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ oselu Accord to lọwọọwọ si lati fi tijo tilu pade Oriyomi.
Amọ se ni awọn janduku ya bo wọn, wọn n ju okuta lu wọn, gun wọn ni igo, sa wọn ni ada, ti wọn si ba awọn mọto ipolongo ibo fun Oriyomi jẹ.

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat
"Lara awọn eeyan to kọ lu wa lo de fila ẹgbẹ oselu APM ti wọn n se ipolongo ibo fun Odidiomo"
Nigba to n pẹtu si awọn ololufẹ rẹ ninu, Oriyomi Hamzat rọ wọn lati mase gbẹsan ikọlu naa pada.
Ninu fidio kan ti Oriyomi se lori ayelujara lori isẹlẹ naa, eyi to gba ori ayelujara kan, lo ti mu fila kan lọwọ, eyi to jẹ fila ẹgbẹ oselu APM ti wọn kọ ipolongo ibo fun Odidiomo si lara.
Oriyomi ni ninu awọn eeyan to da awọn ọmọ ẹgbẹ Accord lọna, lawọn ti ba fila naa lori wọn.
"Koda, ninu iwadii wa, a ri pe awọn eeyan to lọ da Remi Oseni lọna nijooni, naa lo wa da awa naa lọna.
Ẹ jọọ, ẹ jọọ, ki la n fa, to to bayii, ẹyin naa wa nipo ọlẹ lanaa, ki ẹ to di alagbara lonii, ẹ bẹru Ọlọrun." Oriyomi lo sọ bẹẹ ninu fidio naa.

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat
"A ri ẹni ti wọn sa lọrun, a ri ẹni ti wọn gun ni gbogbo ara, ti wọn si wa nile iwosan nile iwosan bayii"
Lara awọn obinrin meji to wa ninu ọkọ ti awọn janduku naa kọlu, ninu fidio kan ti Oriyomi Hamzat gbe sita naa, salaye bi isẹlẹ ikọlu naa se waye.
Ọkan ninu awọn obinrin naa nigba ti awọn de ori afara Molete, awọn janduku n ju igo si awọn ninu mọto, ti wọn si tun n ju okuta.
"Nigba ti a fẹ maa sọkalẹ, tori sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ wa, nigba ti a ri pe wọn ti ko igo ati aga de ọdọ wa, ba se ka sọkalẹ bayii, bi wọn se bẹrẹ si ni sa mi ni ada niyẹn ni apa.
A sa ri ibi sa, awọn kan wa ni ara wa, ti wọn wa nile iwosan bayii, awọn mẹta ni wọn se lese, a ri ẹni ti wọn sa lọrun, a ri ẹni ti wọn gun ni gbogbo ara, ti wọn si wa nile iwosan nile iwosan bayii." Obinrin naa, ti ko darukọ ara rẹ lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat
"Wọn n na wa, ti wọn si n sa wa ni ada, koda, ọkan ninu wọn mu ọbẹ ẹlẹnu meji lọwọ, o fẹ fi gun mi, mo sare mu ọbẹ naa dani, lo se ya mi lọwọ"
Ninu ọrọ obinrin keji, oun naa salaye bi awọn janduku yii se saa ni ada, ti ọwọ rẹ si wu.
"Sadede la ri pe wọn n lẹ igo, a ko tiẹ kọkọ mọ ohun to sẹlẹ, wọn ti ilẹkun ọkọ mọ wa, a ko ri aaye sọkalẹ, wọn sa n lẹ igo amọ nigba to ya, wọn n fi ada sa mọto wa, wọn sa gilaasi mọto naa titi to fi fọ.
Bẹẹ ni wọn n na wa, ti wọn si n sa wa ni ada, koda, ọkan ninu wọn mu ọbẹ ẹlẹnu meji lọwọ, o fẹ fi gun mi, mo sare mu ọbẹ naa dani, lo se ya mi lọwọ.
A rọ ijọba ipinlẹ Oyo pe ko dakun, ko wa nnkan se si nnkan to n sẹlẹ yii, tori ko ni dara, ko jẹ inu fu, aya fu, la maa fi se ipolongo ibo.
Ifẹ ọga wa, Oriyomi la ni, ti a fi lọ pade rẹ, kii se pe a se jagidi-jagan kankan, ko si ẹni to mura pe nnkan bayii yoo sẹlẹ, a ko ja, a ko ta, jẹjẹ wa la n lọ.
To ba di ọjọ miran, ti Oriyomi ba n jade se ipolongo ibo, maa tẹle o tori mo nifẹ rẹ. Obinrin keji yii lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat
Gomina Seyi Makinde la n fi ẹsun kan pe o da ibẹru oselu silẹ tori o ti pasẹ fawọn awakọ ero pe ki wọn maa lo ami idamọ ẹgbẹ oselu APM nikan soso lẹnu isẹ wọn - APC Oyo
Wayi o, ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti fesi lori ikọlu to waye sawọn ọmọ ẹgbẹ oselu Accord to lọ pade oludije sipo gomina wọn, Oriyomi Hamzat.
Atẹjade ti ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo fisita lọjọru eyi ti akọwe ipolongo fun ẹgbẹ naa, Olawale Sadare fisita, wa rọ awọn ileesẹ agbofinro lati se iwadi lẹkunrẹrẹ nipa ikọlu naa.
APC l'Oyo koro oju pupọ si iwa jagid-jagan naa, eyi to ni o mu ki ọpọ alatilẹyin Oriyomi fi ara gba ọgbẹ, ti wọn si wa nile iwosan, eyi ti ko yẹ ka fi ọwọ rọ sẹyin.
"Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ to n se akoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, PMS, la gbọ pe wọn kọlu awọn eeyan naa ati mọto wọn, ti wọn si n fi ada sa awọn ololufẹ Oriyomi .
Gomina Seyi Makinde si la n fi ẹsun kan pe o da ibẹru oselu silẹ tori o ti pasẹ fawọn awakọ ero pe ki wọn maa lo ami idamọ ẹgbẹ oselu APM nikan soso lẹnu isẹ wọn."
Atẹjade naa wa mu wa si iranti nipa awọn isẹlẹ ikọlu mẹta ọtọọtọ to waye ni ọsẹ to kọja sawọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC ni adugbo mẹta nilu Ibadan.
APC wa naka abuku ssawọn afurasi janduku naa pe awọn lo wa nidi biba awọn patako ikede awọn ẹgbẹ alatako jẹ, to fi mọ fifa iwe alẹmọgiri ya atawọn ohun eelo ipolongo ibo miran.
A n beere lọwọ Oriyomi Hamzat fun ẹri to daju lati fidi awọn ẹsun to fi kan Odidiomo mulẹ laarin ọjọ mẹta pere bi bẹẹ kọ, ko tọrọ aforijin tabi ko foju bale ẹjọ - APM igun Odidiomo
Ẹgbẹ oselu APM ti wa fesi lori ẹsun ti wọn fi kan an pe oun lo n se onigbọwọ fun awọn janduku to kọlu oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oselu Accord, Oriyomi Hamzat.
Atẹjade kan ti ẹgbẹ oselu APM fisita ni igun to n polongo ibo fun Odidiomo ti sẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan pe oun lo wa nidi ikọlu naa.
Tolu Mustapha, tii se agbẹnusọ fun igun to n seto ipolongo ibo fun ẹgbẹ oselu APM ni awọn ẹsun idaluru naa ko lẹsẹ nlẹ, to si tun jẹ iwa ibanilorukọ.
Atẹjade naa wa koro oju si fidio to n ja rain lori ayelujara ọhun, to si salaye pe ẹsun ti wọn fi kan Hon. Adedeji Dhikrullahi Olajide Odidiomo, kii se otitọ rara.
Igun to n polongo ibo fun Odidiomo labẹ ẹgbẹ oselu APM wa n beere lọwọ Oriyomi Hamzat fun ẹri to daju lati fidi awọn ẹsun to fi kan Odidiomo mulẹ laarin ọjọ mẹta pere bi bẹẹ kọ, ko tọrọ aforijin tabi ko foju bale ẹjọ.
Lara awọn eeyan to farapa lasiko ikọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ Accord ni Azeez Tajudeen, ẹni ogoji ọdun, to gba ọgbẹ nibi oju ọtun rẹ, to ku sile iwosan - Ileesẹ Ọlọpaa Oyo
Bakan naa, ileesẹ ọlọpaa tipinlẹ Oyo ti fesi lori ikọlu to waye sawọn ọmọ ẹgbẹ oselu Accord to lọ pade oludije sipo gomina wọn, Alhaji Oriyomi Hamzat.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Olayinka Ayanlade wa fidi isẹlẹ naa mulẹ pe lootọ ni awọn janduku ya bo awọn ololufẹ oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu Accord naa.
Atẹjade naa ni iwadi ti bẹrẹ ni pẹrẹ nipa isẹlẹ naa eyi ti Kehinde Ibikunle fi to ileeọ̀ẹ ọlọpaa leti.
Atẹjade naa ni lara awọn eeyan to farapa ni Azeez Tajudeen, tii se ẹni ogoji ọdun, to gba ọgbẹ nibi oju ọtun rẹ, ni kete ti wọn si gbe de ile iwosan lo jade laye.
Ileesẹ ọlọpaa wa tẹnumọ pataki eto aabo lasiko irufẹ iwọde bayii, to si pasẹ fawọn asaaju ẹgbẹ oselu atawọn oludije wọn lati maa fi to ileesẹ ọlọpaa leti to ba ku ọjọ meji ti wọn fẹ jade sita gbangba ki wọn le seto aabo to peye fun wọn fun aabo.




























