Ìdí rèé tí a fi yọ orúkọ Ladi Adebutu olùdíje ẹgbẹ́ PDP kúrò nínú orúkọ àwọn olùdíje sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun - INEC ṣàlàyé

Oludipo sipo gomina fẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun, Ladi Adebutu, wọ aṣọ buba funfun pẹlu ẹrọ gbohungbohun lọwọ rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria, INEC, ti ṣalaye idi to fi yọ orukọ oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, Ladi Adebutu, atawọn oludije mii kuro ninu orukọ awọn oludije ti yoo kopa ninu eto idibo ọdun 2027.

INEC ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ẹgbẹ oṣelu Adebutu atawọn awọn oludije mii tọrọ kan kuna lati fi orukọ wọn ranṣẹ si ajọ naa gẹgẹ bi ofin eto idibo Naijiria ṣe la a kalẹ.

Ajọ eleto idibo Naijiria sọrọ yii lẹyin awuyewuye to jẹyọ nigba ti INEC ko gbe orukọ Adebutu atawọn oludije mii jade pẹlu orukọ awọn oludije mii to n dupo osẹlu kan tabi omiran ninu eto idibo ọdun 2027.

Minisita eto ibaraẹnisọrọ tẹlẹ, Isa Pantami naa ke gbajare wi pe INEC ko gbe orukọ oun jade gẹgẹ bi oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Gombe.

INEC kuna lati gbe orukọ Pantami jade lẹyin to wọle idibo abẹnu eyi ti ileẹjọ paṣẹ wi pe ki o waye lati mọ oludije sipo gomina nipinlẹ Gombe labẹ asia ẹgbẹ PDP.

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣelu PDP ẹka ti ipinlẹ Ogun ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu alatako APC wi pe oun lo ko ajọ INEC ni papa mọra lati yọ orukọ Adebutu kuro ninu orukọ awọn oludije sipo gomina fun eto idibo ọdun 2027 to n bọ.

Bakan naa ni gbajugbaja agbẹjọro ati ajafẹtọọ, Inibehe Effiong, ke pe INEC wi pe ko gbọdọ ṣegbe lẹyin ẹgbẹ osẹlu kankan gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.

Idajọ ileẹjọ to ga julọ ni a tẹle lori awọn oludije ti a yọ orukọ wọn kuro - INEC

Alaga eto iroyin ati igbimọ ilanilọyẹ fun INEC, Mohammed Kudu Haruna, ṣalaye ninu atẹjade ti ajọ naa fi sita pe ayọkuro orukọ Adebutu ati Pantami ko ṣẹyin idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kesan an ọdun yii laarin ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ati INEC eyi to fontẹ lu abala 77(5)–(7) ofin eto idibo Naijiria ti ọdun 2026.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Abala ofin eto idibo naa sọ pe gbogbo ẹgbẹ oṣelu gbọdọ fi orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to fi mawọn oludije ranṣẹ si INEC ni gbedeke asiko kan.

Bakan naa ni ileẹjọ to ga julọ tun fontẹ lu gbedeke ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹrin si ọjọ kẹwaa oṣu Karun un ọdun 2026 yii gẹgẹ bii ọjọ ti gbogbo ẹgbẹ oṣelu gbọdọ fi orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to fi mọ awọn oludije sipo oṣelu ranṣẹ si INEC.

INEC ni ileẹjọ to ga julọ tun fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ oṣelu to ba kuna lati fi orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ranṣẹ laarin akoko yii ko ni lanfaani lati ni oludije sipo oṣelu ninu eto idibo to n bọ.

Ajọ INEC ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wi pe idajọ ileẹjọ to ga julo yii lawọn tẹle lati gbe orukọ awọn oludije sipo gomina jade ti awọn si yọ orukọ awọn kan kuro.

INEC tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ti gbe orukọ awọn oludije sipo aarẹ ati sile aṣofin agba l'Abuja jade lati ọjọ kejila oṣu Kẹsan an ọdun 2026, eyi tii ṣe ọjọ kẹtala ṣaaju idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Ajọ eleto idibo Naijiria fikun ọrọ rẹ pe abala 32(2) ofin eto idibo Naijiria ti ọdun 2026 sọ pe ẹgbẹ oṣelu to ba gbagbọ pe INEC yọ orukọ oludije rẹ kuro lọna aitọ ni anfaani ọjọ mẹrinla lati fi to INEC leti.

INEC wa kede ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹwaa yii gẹgẹ bii gbedeke ọjọ tawọn ẹgbẹ oṣelu bẹẹ ni lati kan si i.

Ajọ INEC tun fidi rẹ mulẹ pe oun ko ni kaarẹ lati maa tẹle ilana ofin ati ṣiṣe agbekalẹ eto idibo ti ko ni eeru ninu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post