BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ilé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé dàwó, èèyàn méjì kú, mẹ́ta dèrò ilé ìwòsàn
Akojọpọ awọn adoola ẹmi lati ajọ Red Cross, NEMA, ileeṣẹ adoola ẹmi ipinlẹ Anambra, SEMA, ileesẹ panapa, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn adoola ẹmi miran ni wọn wa nibẹ.
Ọmọ Nàìjíríà míràn tún kú sọ́wọ́ ọlọ́pàá ní South Africa; Ìjọba Nàìjíríà fárígá, pè fún ìwádìí kíkún
Tẹ o ba gbagbe, South Africa ti n le awọn ajeji rẹpẹtẹ kuro nilẹ naa o ti pẹ, paapaa awọn alawọ dudu ti wọn jẹ ọmọ Africa bii tiwọn, lori ẹsun pe wọn ko je kawọn riṣẹ ṣe niluu abinibi awọn.
Àlàyé rèé lórí bọ́wọ́ ṣe tẹ afurasí sọ́jà tó ń ta aṣọ ọmọ ogun Naijiria fún áwọn agbésùnmọ̀mí
Afurasi naa, Mohammed Yusuf pẹlu nọmba 23NA/84/1939 Private to n ṣiṣẹ pẹlu ẹka ileeṣẹ ologun to n ran aṣọ awọn ọmogun niluu Eko ni wọn mu ni nnkan bii ago mẹfa aabọ lopin ọsẹ to kọja lẹyin iṣẹ iwadii kan ti ileeṣẹ ologun ṣe.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,07
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Àlàyé rèé lórí bí eégún Olóòlù ṣe dé Ibadan, ìdí tí kìí fi wọ bàtà tàbí fojú kan obìnrin
Ní kété tí ènìyàn bá ti dárúkọ eégún Oloolu ní Ibadan, kálukú yoo máa forí gbárí, torí ẹ̀rù àti agbára tó wà lára rẹ̀
Fàákája láàrin ọlọ́pàá àti iléeṣẹ́ ọmogun oju-omi l'Osun lórí àwọn jàndùkú tó fẹ́ gba gáréèjì, àwọn tọ́ọ̀gì tún jí káàdì ìdìbò kó lọ
Olugbe ilu Okuku kan, Gbadebo, sọ fawọn akọroyin pe ṣadeede lawọn janduku naa ya wọ ile ẹkọ ti INEC ti n pin kaadi idibo naa.
Fídíò, Àdó olóró àwọn ajínigbé pa Shuaibu aṣọ́gbóọba lásìkò tó ń lé àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé ní Oriire, àwọn ẹbí rẹ̀ pariwo síta, Duration 5,16
Shuaibu atawọn eeyan kan lo kọkọ gbiyanju lati le awọn ajinigbe naa ki wọn si gba awọn ti wọn ko pada.
Àfiwé owó oṣù àwọn ṣọ́jà Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ wọn lórílẹ̀èdè míràn ní Áfíríkà
Ilọpo mẹjọ ni owo oṣu awọn ọgagun lorilẹede Naijiria fi kere si ti awọn akẹgbẹ wọn lorilẹede South Africa.
America kìlọ̀ fáwọn ọmọ Nàìjíríà tó tún jẹ́ ọmọ America láti má ṣe lo ìwé ìrìnná míràn yàtọ̀ sí ti orílẹ̀èdè náà láti wọlé tábì jáde l'America
Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi lede loju opo X rẹ lọjọ Aiku, ni wọn ti kede pe eyi kan gbogbo ọmọ oniluu l'America pẹlu, titi kan awọn ọmọde to ba ti jẹ ọmọ oniluu meji.
Ẹ wo ilé ìwòsàn táwọn aláboyún ti ń bímọ sórí ẹní
Ile iwosan alabọde Badawa ti dẹnu kọlẹ lati bi ọdun mẹwaa ti atẹgun ojo ti ba apa kan ile iwosan naa jẹ.
Olórí àwọn tó ń pèsè owó fún ẹgbẹ agbésùnmọ̀mí ISWAP ní Naijiria jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ọmọ ogun
Ninu atẹjade kan, ileeṣẹ ọmọ ogun sọ pe igbesẹ afurasi naa lo n waye lasiko ti pupọ awọn agbesunmọmi bi tirẹ bẹrẹ si n jọwọ ara wọn fun ileeṣẹ ọmọ ogun.
Àwọn olùgbé Akure pariwo lórí òórùn tó gbalẹ̀ kan, ìjọba bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri ọrọ ayika ti fidi rẹ mulẹ pe iwadii ti fi han pe oorun yii ko ṣẹyin awọn eeyan kan ti wọn n da idọti lọna aitọ sina odo to n ṣan.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fọ́nrán bí Abacha ṣe kú wà lọ́wọ́ mi, arúmọjẹ lásán ni ìtàn táwọn kan ń kọ sínú ìwé kiri - Al-Mustapha, olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò fún Abacha
Latigba ti iku Ọgagun Abacha ti jade sita, ni ariyanjiyan ti wa kaakiri agbaye, paapaa nilẹ Naijiria to ti jẹ adari, ti awọn eeyan ko si gbagbe titi di asiko yii.
Mo Bimpe lérí láti gbé àwọn tó ní Lateef Adedimeji kọ́ ni bàbá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sílé ẹjọ́
Lori ayelujara ni iroyin to ni Lateef Adedimeji kọ ni baba awọn Ibẹta ti n tan kalẹ
Kókó ìpàdé Sẹ́nẹ́tọ̀ Folarin pẹ̀lú Ààrẹ Tinubu lórí awuyewuye nípa olùdíje sípò gómìnà fẹ́gbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Oyo
Ipade naa ni wọn lo da lori erongba lati fi opin si gbogbo aawọ, wahala ati ikunsinu to wa laaarin awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo, ṣaaju eto idibo gomina to fẹẹ waye ninu oṣu Keji, ọdun 2027.
Ọlọ́pàá mẹ́rin tó bèèrè owó ẹ̀yìn lọ́wọ́ awakọ̀ lọ́nà márosẹ̀ Ọrẹ si Benin wọ gàù, ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí wọn
Gẹgẹ bi kọmandi ọlọpaa Ondo ṣe wi loju opo X, wọn ti mọ awọn ọlọpaa to wa ninu fidio yii, iwadii ati igbesẹ to yẹ si ti bẹrẹ lorii wọn.
Mi ò lérò pé mo lè dé ipò Ìmáàmù ìlú Ilorin, àmọ́, mo ti máa ń rí àwọn àpẹẹrẹ kan tipẹ́ - Ìmáàmù Ilorin tuntun
Imaamu Ilorin tuntun fikun ọrọ rẹ pe awọn musulumi ko gbọdọ jẹ ki ero awọn ọta Islam to maa n sọ pe ẹsin jagidijagan ni ẹsin Islam ṣẹ mọ wọn wa lara.
Ìbanilórúkọjẹ́ lẹ̀sùn ìkówójẹ tí wọ́n fi kàn mí, Oluomo sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tílé aṣòfin Ogun fagilé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan adarí ilé tẹ́lẹ̀
Ile tun fẹnuko nibi ijokoo wọn lonii Ọjọru niluu Abeokuta wi pe iyọnipo rẹ ti di ikọwefiposilẹ bayii.
Wo ìdí tí Trump ṣe kọ lẹ́tà, kan sáárá sí Tinubu lórí gbígbógun ti ìgbéṣúmọ̀mí
Agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga ninu atẹjade kan to fi soju opo X rẹ ni Trump kan saara si Tinubu lorukọ awọn ọmọ Naijiria.
Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin buwọ́lu àbádòfin fún ìdásílẹ̀ ọlọ̀pàá ìpínlẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà
Eyi waye l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu Keje ọdun 2026 yii.
Ìwádìí BBC rèé lórí ẹ̀sùn àjẹbánu ₦44m táwọn aṣòfin Ondo fi kan Olórí ilé tí wọ́n fi ni kó fipò sílẹ̀
Awọn aṣofin naa fun olori ile aṣofin ti i ṣe Abẹnugan wọn; Olamide Oladiji,ni gbedeke di ọjọ Aiku, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2026 lati kọwe fipo rẹ silẹ bibẹẹkọ awọn maa yọ nipo.
Ẹ̀yin agbébọn, Iru Ekun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láwọn igbó tó wà lẹ́kùn Gúúṣù Kwara, ẹ tètè para mọ́, gbogbo ìlẹ̀ Ìgbómìnà ni máà dé - Sunday Igboho
BBC News Yoruba bawọn peju sibi eto naa to bẹrẹ ni nnkan bi ago meji abọ Ọsan, tawọn eeyan ẹkun Gusu Kwara si peju si lọpọ yanturu.
Ngozi Nwosu, gbajúmọ̀ òṣèré tún ń bẹ̀bẹ̀ fún ₦30m láti ṣiṣẹ́ abẹ mẹ́ta, lẹ́yìn ọdún 13 tó lọ fún ìtọ́jú àìsàn ní Germany
Lati bi ọsẹ mẹta sẹyin la gbọ pe oṣerebinrin oloyinbo nni ti wa nile iwosan, to si ti na ọpọlọpọ owo lati fi tọju ara rẹ, ṣugbọn to jẹ pe agbara rẹ ko gbe awọn owo itọju to n san naa mọ.
Adeleke gbẹ́sẹ̀ lé ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò l‘Osun, pàṣẹ fún ọlọ́pàá láti ṣoro fún ẹni tó bá tàpá ṣófin
Ọjọbọ, ọsẹ yii ni Gomina Adeleke gbe aṣẹ naa kalẹ, lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn olori eleto aabo nipinlẹ naa.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Obasanjo àti Osoba sọ òkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ìbò 2003, àṣírí ọ̀pọ̀ ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ tú àti ìdí táwọn gómínà AD ṣe pàdánù sọ́wọ́ PDP
Ni ọdun 2018 ni Osoba ninu atẹjade kan ti sọ pe Obasanjo ṣe ẹtanjẹ fun gbogbo awọn gomina to wa labẹ ẹgbẹ oṣelu AD ni ẹkun guusu iwọ oorun Naijiria eyi to mu ki awọn padanu ipo awọn ninu idibo naa.
Wo àwọn àyípadà tó máa wáyé sí ètò ààbò bí Ààrẹ Tinubu ṣe buwọ́lu àfikún ẹkùn iléeṣẹ́ ológun di méjìlá
Yatọ si afikun si ẹkun ileeṣẹ ologun naa, Aarẹ tun kede gbigba awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun mejidinlọgbọn sẹnu iṣẹ, lati ṣafikun si awọn to wa nilẹ tẹlẹ.
APC àti Makinde ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ láti dènà EFCC láti ṣe ìwádìí ìṣúná Oyo
EFCC lo gbe akanṣe iwadii dide lati ṣe agbeyẹwo awọn owo iṣẹ akanṣe ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe jáde.
Ilé ẹjọ́ gba onídùúró Blessing CEO pẹ̀lu ₦20m lórí ẹ̀sùn jìbìtì ₦69.15m
Tẹ o ba gbagbe, ẹsun meji ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu jibiti lilu ni sọrọsọrọ ori ayelujara naa n jẹjọ rẹ, eyi ti kootu pe ni ₦69.15 ni wọn ti fi aaye beeli silẹ fun un wayii.
Wo àwọn nǹkan mẹ́fà tó ti yípadà lẹ́yìn ìdìbò 2023 tó le nípa lórí ìdìbò 2027
Ọdun mẹrin mii tun ti de tawọn eeyan yoo tun maa dibo pẹlu gbogbo ayipada to ti waye lẹka oṣelu ati eto ọrọ aje Naijiria. Awọn ofin eto idibo ti yipada, ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lọwọ ti mu alekun bai bi ti ọwọja wọn de tẹlẹ, tawọn oludibo naa si n koju ipenija ọtun paapaa lori igbeaye, aisi aabo ati ina ọba ti ko duro ire.
Oluwo dá ẹgbẹ́ lọ́balọ́ba lẹ́kùn ìdìbò Ìwọ̀ oòrùn Osun sílẹ̀, di alága láéláé, àwọn ọba míì fi èrò wọn hàn
Oluwo ni awọn ọba to wa ni ẹkun iwọ oorun Osun ni wọn woye pe o yẹ ki iṣọkan wa laaarin gbogbo wọn, ti wọn si da labaa lati da igbimọ naa silẹ.
Ọlọ́pàá mẹ́rin tó gbégi dínà lójú pópó fi tipá gba rìbá N57,000 lọ́wọ́ ọ̀gá àjọ tó ń gbógun tìwà àjẹbánu, ICPC, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ
Lasiko yii, alaga ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, ICPC, Musa Aliyu ni awọn ọlọpaa kan fọwọ ṣikun ofin gbe nilu Abuja, ti wọn si fi ẹsun titapa si ofin kan an, leyi to jẹ ki wọn beere owo lọwọ rẹ.
Wo gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa WAFCON 2026
WAFCON ọdun yii yoo bẹrẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje ọdun 2026.
Ọkùnrin tó gbé aláìsàn wá sílé ìwòsàn Adeoyo n'Ibadan yarí pé kò sí dókítà lẹ́nu iṣẹ́, ó yájú sí Nọ́ọ̀sì, ẹgbẹ́ àwọn Nọ́ọ̀sì fọnmú
Loju ẹsẹ ti wọn sọ fun ọkunrin naa pe ko si dokita lẹnu iṣẹ ni alẹ ọjọ naa, lo ti sọ ọrọ ọhun di ariwo, to si bẹrẹ sii ṣe ikọlu si nọọsi to ba lẹnu iṣẹ.
Kí ni ipa tí ìdásílẹ̀ ibùdó ológun tuntun ní Omu-Aran, Kwara, yóò ní lórí àwọn ajínigbé, àgbésùnmọ̀mí àti aráàlú? Àwọn onímọ̀ sọ̀rọ̀
Atẹjade kan ti Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq fi soju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Keje sọ pe ilu Omu-Aran ni ijọba ibilẹ Irepodun ni ibudo ọmọ ogun naa maa wa.
ICPC ṣàwárí ayédèrú òṣìṣẹ́ 908 láwọn iléeṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà àádọ́ta, ọlọ́pàá pọ̀ nínú wọn
Alaga ICPC, Musa Adamu Aliyu (SAN) fidi eyi mulẹ fun BBC.













































































