Kàyééfì: Nítorí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, àwọn jàǹdùkú ṣekú pa Bàbá, Ìyá àti ọmọ mẹ́rin n'Ibadan

Àkọlé fídíò, Kàyééfì: Àwọn afurasí tó ṣekú pa mọ̀lẹ́bí kan ni Ibadan jẹ́wọ́
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Awọn afurasi mẹtẹẹta lo jokoo nilẹ yii, lasiko ti awọn ọlọpaa n fi oju wọn han fun awọn akọroyin

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ idile kan ti awọn afurasi ọdaran lọ ṣeku pa mọ inu ile lọjọ kan naa nigboro ilu Ibadan, ipinlẹ Oyo.

Adugbo ti wọn n pe ni Abule Oloba to wa nijọba ibilẹ Lagelu, Ibadan lawọn idile naa n gbe, ibẹ si lawọn janduku naa ti lọ ṣeku pa wọn.

Aadọta naira la gbọ pe o da wahala silẹ, to fi di pe awọn janduku wọnyi lọ ṣe ikọlu sile awọn idile naa.

Ṣugbọn ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi mẹta to lọwọ ninu iku awọn idile naa, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori wọn.

Bá wo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni awọn afurasi mẹta naa yabo ile awọn oloogbe ọhun pẹlu nnkan ija oloro.

Hammed Akinbami, Akinbami Ojo ati Pandonu Edward ni awọn afurasi tọwọ tẹ naa.

Nnkan bi agogo meje alẹ ọjọ naa ni Hammed ati awọn yooku ko ada, ibọn, kumọ ati nnkan ija oloro miran lọ ka Ifeanyi Chukwu, iyawo ati awọn ọmọ rẹ mọle.

Esun ti a gbọ pe wọn fi kan Ifeanyi Chukwu, ẹni tọpọ mọ si Baba Chike ni pe, o ba ẹrọ ibanisọrọ Ojo Akinbami jẹ.

Bi wọn ṣe de ile Ifeanyi lọjọ naa, la gbọ pe Hammed ti yinbọn fun un, ti wọn si ni Ojo ati Pandonu la kumọ mọ iyawo rẹ lori.

Loju ẹsẹ ni awọn mejeeji ti ku, paapaa nigba ti wọn ko tun ri iranlọwọ lati ibikibi.

Lẹyin eyi la gbọ pe awọn mẹtẹẹta de awọn ọmọ wọn meji lọwọ ati ẹsẹ, ko to di pe wọn lọ ju wọn sinu odo Osun to wa nitosi ile wọn.

Ṣaaju asiko yii, ko to di pe wọn lọ ju oku awọn ọmọ naa sinu odo, la gbọ pe wọn ti ji ẹgbẹrun lọna igba naira ninu ile wọn.

Yatọ si eyi, wọn tun ji ọkada alupupu to jẹ ti Ifeanyi ati awọn nnkan miran ninu ile wọn, ko to di pe wọn ba ti wọn lọ.

‎Bí àsírí ṣe tú

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi gbogbo adugbo naa ṣe tobi to, ko sẹni to mọ pe nnkan aburu ti ṣẹlẹ si Ifeanyi ati idile.

Ọjọ mẹrinla lẹyin iṣẹlẹ naa la gbọ pe awọn ara adugbo naa ṣẹṣẹ mọ pe Ifeanyi, iyawo ati awọn ọmọ rẹ ti doloogbe.

Ọkan lara awọn to maa n ba Ifeanyi gbe ọja lọ ta, ni wọn lo kofiri oku awọn eeyan naa ninu ile wọn, ti wọn si ti wu kọja sisọ.

Ẹni naa ni wọn lo lọ sile wọn lati ba Ifeanyi gbe ọja Ireke to n ta lọ sọja. Igba ti yoo fi wọnu ile, lo ṣakiyesi pe nnkan n run bi oku ẹran to ti ku.

Ẹni naa lo ke gbajare si gbogbo awọn ara adugbo naa, ko to di pe wọn lọ fi to ọlọpaa leti.

Loju ẹsẹ ni wọn lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii.

Nibi ti iwadii ti n lọ lọwọ, la gbọ pe wọn ti kofiri ọkada alupupu to jẹ ti Ifeanyi nile Hammed, eyi lo jẹ ki wọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa.

Bọwọ ṣe tẹ Hammed, lo ti bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, nitori pe kii ṣe oun nikan loun ṣiṣẹ buruku naa, bi ko ṣe pe awọn mẹta ni.

Ọrọ ti wọn sọ pe Hammed sọ, lo pada jẹ ki ọwọ tẹ awọn meji yooku, ti wọn si ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa bi wọn ṣe ṣeku pa Ifeanyi ati awọn eeyan rẹ.

Kí làwọn èèyàn sọ?

Ọkan lara awọn agbalagba agbegbe naa, Olugbade Adefemi nigba to n ba BBC sọrọ, ṣalaye pe inu oṣu Kẹta, ọdun yii ni awọn ilu ti lọ ba oloogbe naa lati bere idi to fi kọ ile ahere to n gbe sẹgbẹ odo Osun.

O ni awọn sọ fun un pe inu ilu lo yẹ ko kọ ile rẹ si, ṣugbọn to sọ pe Baale lo ti fun oun ni ilẹ.

Lati bi ọdun mẹwaa sẹyin la gbọ pe Ifeanyi ti wa ni abule Oloba, to si n da oko sibẹ.