Kò sí ẹni tó ní ìrírí tó mi nínú àwọn ta jọ ń díje sípò gómìnà Kwara - Danladi, olùdíje APC

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu Danladi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oludije sipo gomina ni ipinlẹ Kwara lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Saliu Yakubu Danladi ti sọ pe ko si oludije kankan to ni iriri to oun ninu gbogbo awọn ti wọn jọ n dije sipo naa.

Danladi sọ eyi lasiko to n kopa nibi ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba lori erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Kwara nibi eto idibo ọdun 2027.

Danladi to n fesi si ẹsun pe gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq lo fa a kalẹ gẹge bi oludije lati rọpo rẹ nigba ti saa rẹ ba pari lọdun to n bọ.

O sọ pe kii ṣe pe gomina lo fa oun kalẹ ati pe oun kaju oṣuwọn lati tukọ ipinlẹ Kwara bi oun ba ni anfaani lati di gomina nibi eto idibo naa.

Saliu Yakubu Danladi jokoo lori aga, o na ọwọ mejeeji siwaju

O ṣalaye pe iriri oun gẹgẹ bi olori ile aṣofin ipinlẹ Kwara lati ọdun meje sẹyin ti fun oun ni ọgbọn ati oye ti oun nilo lati fi ṣe gomina.

"Ti mi o ba kaju oṣuwọn, awọn ọrẹ mi, awọn akẹgbẹ mi mẹtalelogun ti mo jẹ olori wọn lati ọdun meje ti maa yọ mi nipo.

"Fun eeyan kan lati ṣakoso ẹka aṣofin fun bii ọdun meje ati aabọ lai si wahala tabi ifanfa kankan, o tumọ si pe onitọhun dangajia."

Danladi tun sọ pe nigba ti awọn eeyan ba n sọrọ nipa pipoju owo, o ni ṣe lẹnu iṣẹ ni, iṣakoso ilu tabi lori imọ ẹkọ.

"Ninu gbogbo awọn ti n jọ n dije sipo gomina yii, pẹlu iriri ti mo ti ni ta lo ti ṣe nnkan ti mo ti ṣe ninu wọn, mo ni iriri ju gbogbo wọn lọ.

"Ti wọn ba si n sọrọ nipa imọ ẹkọ, mo ni gbogbo iwe ẹri ti eeyan nilo lati fi tukọ ipinlẹ Kwara.

Ko si idi ti ile aṣofin ati igbimọ alaṣẹ yoo maa ni aawọ ti ajọṣepọ to daa ba wa laaarin wọn

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n fesi lori ibeere pe nnkan ti gomina ba fẹ nikan ni ile aṣofin ipinlẹ Kwara maa n ṣe, Danladi ni ọpọ igba ni awọn ti maa n jiroro pẹlu igbimọ alaṣẹ lori ohun ti wọn ba fẹ gbe wa sile aṣofin.

O ni eyi lo fa a ti awọn kii fi pẹ lori awọn ijiroro bẹẹ mọ, tawọn si maa buwọlu oun tio igbimọ alaṣẹ n beere fun.

O sọ pe eyi n fi ajọṣepọ to dan mọran to wa laaarin igbimọ alaṣẹ ati ile aṣofin ipinlẹ Kwara mulẹ.

"Ti gomina ba n ṣe ohun to tọna, ki nidii ti tawọn aṣofin yoo ṣe maa ni aawọ pẹlu ijọba?

"Ti o ba n ṣe ohun ti ko tọna, a maa gba a ni imọran lati gbe ohun to tọ wa sile aṣofin. Ko si ohun ti gomina gbe wa sile aṣofi ti wọn ko ti ba ile aṣofin sọrọ ṣaaju ki wọn to gbe e wa.

"To ba jẹ ohun ti a ko mọ tẹlẹ ni a kan n buwọlu, wọn le maa pe wa ni ile aṣofin to kan n fi ontẹ lu ibeere ijọba ti wọn pe ni rubber stamp."

Olori ile aṣofin naa tun sọ poe gbogbo ipinlẹ Kwara ni idagbasoke wa, to si woye pe ko yẹ kawọn eeyan kan maa pe ile aṣofin ni "rubber stamp".

O tẹsiwaju e gbogbo awọn aṣofin lo ni nnkan ti wọn le tọka si gẹgẹ bi ohun idagbasoke ti wọn ṣe ni gbogbo wọodu mẹtalelaaadọwa to wa ni ipinlẹ Kwara.

Eto aabo, igbagbarawọni atawọn igbayegbadun ni maa mojuto ni ọdun akọkọ ti mo ba di gomina

Danladi ṣalaye pe ti oun ba di gomina ipinlẹ Kwara, awọn nnkan mẹta ti oun maa gbajumọ ni eto aabo, igbagbarawọni atawọn igbayegbadun ki nnkan le rọrun fawọn araalu.

O ni ko si bi idagbasoke ṣe maa wọ ilu nigba ti ko ba si eto aabo to peye, ti alaafia ko si ni ilu naa.

"Laisi alaafia, o maa ṣoro lati mu idagbasoke wọ ilu."

O fi kun pe oun maa tẹsiwaju lori awọn ibi ti ijọba to wa lode ti ṣe daadaa nigba ti oun yoo pọnkun akitiyan ni awọn ọna ti ijọba to wa lode ko i tii de.

Bakan naa lo fi kun pe gbigbe agbara wọ awọn eeyan lati le ṣiṣẹ kaju oṣuwọn ṣe pataki si mimu idagbasoke ba ilu.

O ni awujọ ti ko ro awọn eeyan rẹ lagbara n gọ sabẹ ika kan ni, ti ilọsiwaju ko si le awujọ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe ṣiṣe awọn akanṣe iṣẹ lori igbayegbadun awọn eeyan ni nnkan kẹta ti oun maa gbajumọ ti oun ba ni anfaani lati de ipo gomina ipinlẹ Kwara.

O ni oun maa ṣaridaju rẹ pe awọn akanṣe iṣẹ naa wọ gbogbo ẹka paapaa julọ lori eto ẹkọ, ilera ati eto ọgbin nitori oun gbagbọ pe gbogbo awọn nnkan yii ni yoo mu ipinlẹ Kwara ni ilọsiiwaju.

O tun sọrọ lori bi yoo ṣe pese aaye to rọrun fawọn olokoowo lati gbe okoowo wọ ipinlẹ Kwara, ti ipinlẹ Kwara yoo kuro lara awọn ipinlẹ to jẹ pe awọn oṣiṣẹ ijọba nikan ni wọn ni laisi ileeṣẹ kan gboogi nibẹ.

O sọ pe eyi ti n yipada lati bii ọdun meje sẹyin pelu awọn akanṣẹ iṣẹ ti gomina ti gbe wọle ti oun yoo si gbajumọ idokoowo lẹka eto ọgbin ti oun ba ri anfaani lati di gomina Kwara.

Danladi tun ba BBC News Yoruba sọrọ lori irinajo, bo ṣe di olori ile aṣofin ipinle Kwara lẹni ọdun mẹtalelọgbọn.