Kò pẹ́ tí Toluwanisings kọrin tán níbi ìpàtẹ orin ẹ̀mí ló ṣubú lulẹ̀ – Amúgbálẹ̀gbẹ́

Toluwanisings ree nigba to wa laye, o de fila pẹlu aṣọ funfun to tun ni awọ olomi aro ninu, o lo aago sọwọ, bẹẹ lo n rẹrin musẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹsẹ ko gbero nile gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Toluwasings to wa ladugbo Oluwakehin, agbegbe Alakia niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo.

Aarọ Ọjọru, ọsẹ yii ni akọrin ẹmi naa, Olayemi Bayonile Bolaji jade laye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Irọlẹ Ọjọru naa ni iroyin iku rẹ ti jade sori ikanni ayelujara kaakiri, to si n ṣe gbogbo eeyan to ti gbọ orin rẹ daadaa ni kayeefi

Amugbalẹgbẹ Toluwanisings, Babadunni Gbolahan sọ fun BBC pe ko si nnkan to ṣe akọrin ẹmi naa laaarọ ọjọ, ko to di pe o deedee ṣubu.

Gbolahan sọ pe Toluwanisings ṣẹṣẹ kọrin tan nibi ipatẹ orin kan to waye niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo, ti ko si ṣebi ẹni pe nnkan n ṣe oun.

"Ko si nnkan to ṣee laaarọ Ọjọru, nitori pe o ṣẹṣẹ kọrin tan nibi ipatẹ orin kan to waye niluu Ibadan ni," Gbolahan sọ bẹẹ fun BBC.

O ni ṣadede lo ṣubu lulẹ, ti wọn si gbiyanju lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn to jẹ iyalẹnu pe ko ni ye e.

"O kan deedee ṣubu lulẹ ni, wọn si du ẹmi rẹ. Awọn ile iwosan ti wọn gbe e lọ, wọn lawọn dokita wa ni iyanṣẹlodi," amugbalẹgbẹ kọminu.

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe, "Pẹlu oniruuru adura ti a gba, sibẹ, ko si ohun ti a fẹẹ ṣe. Ile iwosan ti wọn gbe e lọ to meje si mẹjọ niluu Ibadan yii."

Ìpalẹ̀mọ́ ètò ìsìnkú bẹ̀rẹ̀

Gbolahan tun sọ siwaju pe nigba ti ko si nnkan ti wọn le ṣe mọ, ti awọn dokita si ti fidi rẹ mulẹ pe ẹlẹmin ti gba a, o loju ẹsẹ lawọn ti gbe e lọ si mọṣuari.

O lawọn mọlẹbi rẹ ti bẹrẹ eto, paapaa ipade lori igbesẹ to kan, nipa bi wọn yoo ṣe fi eeru fun eeru, ati erupẹ fun erupẹ.

Gbolahan ni abajade ipade awọn mọlẹbi ni yoo sọ igba ati akoko ti wọn yoo fi ilẹ bo o.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ti ẹ ko ba gbagbe, ninu oṣu Keje, ọdun yii ni akọrin ẹmi naa ti dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ori to ko o yọ ninu ijamba ọkọ.

Ibi ti Toluwanisings ti lọ kọrin ẹmi lo ti n bọ, ko to kkagbako ijamba ọkọ pẹlu ọkan lara awọn ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

Gbajumọ olorin naa gbe awọran bi ọkọ rẹ ṣe bajẹ to han gbogbo awọn ololufẹ rẹ, to si n rọ wọn lati ba a dupẹ.

'Mùsùlùmí ni mí kí n tó fi ayé mi fún Jésù, Fuji ni mo fi bẹ̀rẹ̀ orin', àwọn ohun tí o kò mọ̀ nípa Toluwanisings

Toluwanisings wọ aṣọ olomi aro, o mu gbohungbohun dani

Toluwanisings ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Olayemi Bayonile Bolaji jẹ ọmọ ilu Ikirun, nipinlẹ Osun.

O ni lẹyin ti oun pari ikẹkọọ girama ni oun kuro niluu Ikirun bọ si ilu Eko.

Nigba to de ilu Eko lo lọ sile ẹkọ Yaba Tech nibi to ti kẹkọọ nipa imọ ile eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Estate Value.

Ninu ifọrọwalẹwo kan to ṣe pẹlu gbajumọ oṣere, Biola Adebayo, Talk to B, sọ pe inu ẹsin Islam ni wọn bi oun si ati pe orin Fuji gan—an ni oun fi bẹrẹ.

O ni Sodiq ni orukọ musulumi oun ki oun to yipada si esin Igbagbọ.

O sọ pe lati bii ọdun mejila ni oun ti n kọrin ko to di pe Ọlọrun lo Woli Arole fun oun lati di ilumọọka.

Ọjọ kẹjọ oṣu Keje ni wọn bi i (A ko ri akọsilẹ ọdun).

Akọrin ẹmi ati adari isin ni awọn eeyan mọ ọn si.

Toluwanisings maa n kọ orin fawọn eeyan lati ọwọ ara rẹ (Song writer).

Ọpọlọpọ orin rẹ wa loju opo ayelujara bii Instagram ati Tiktok, awọn eeyan si mọ ọn bii ẹni mowo lawọn oju opo naa pẹlu bi wọn ṣe maa n lo awọn orin rẹ fun adura loju opo adani wọn.

Lara awọn orin to ti ṣe ni "Unreserved Praise, A Very Big God, Onibuore, E Lagbara, ati Owo Re Meji Meji.

Ni nnkan bii ọsẹ meji ṣeyin ni o ṣe ayẹyẹ ọdun marun-un to ti ṣe igbeyawo pẹlu iyawo rẹ Itohan.

Ọmọ meji ni Ọlọrun fi ta idile wọn lọrẹ, ti ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Irọrun ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun meji ni ọsẹ to kọja.

Wo àwọn gbajúmọ̀ tó ti selédè lẹ́yìn Toluwanisings

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati igba ti iroyin iku Toluwanisings ti jade ni awọn eekan ilu, awọn olorin ẹmi, awọn onitiata ti n kọrin aro lẹyin rẹ.

Niṣe ni olukaluku wọn n sọrọ nipa bi iroyin iku naa ṣe ba wọn lojiji, ti wọn si n gbadura ki Ọlọrun tu iyawo ati idile rẹ loju lori adanu wọn.

Akọrin ẹmi Adeyinka Alaseyori kọ soju opo Instagram rẹ pe awọn n da Ọlọrun lejọ lori iku akọrin Toluwanisings pẹlu bi awọn ṣe n daro rẹ.

Gbajumọ oṣere Wumi Toriola ninu atejade kan to fi soju opo X rẹ juwe iku akọrin naa bi oun to ṣoro lati tẹ mọra, to si gbadura ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.

Akọrin Bidemi Olaoba sọ pe ọkan ọpọ awọn lo gbọgbẹ lori iku Toluwani, pẹlu pe bi ohun to ṣẹlẹ ko ye ẹnikẹni, ṣugbọn awọn gba fun Ọlọrun.

Woli Agba ni tirẹ sọ pe adanu nla ni iku Toluwanisings jẹ, to si gbadura ki Ọlọrun tu awọn ẹbi, ọrẹ atawọn agkẹgbẹ rẹ loju.

Akọrin ẹmi mii, Paul Tomisin juwe Toluwanisings bii oniwairẹlẹ to maa n ṣatilẹyin fun awọn akegbẹ rẹ ni gbogbo igba koda bi ko ba maa kọrin nibi eto wọn.

Dare Justified sọ pe iṣẹlẹ naa ba awọn lojiji, ti iku naa si jẹ ohun ti awọn ko gbagbọ pe o le waye lasiko yii.

Gbajumọ oṣere, Jaiye Kuti gbadura ki Ọlọrun gba abọ akọrin ẹmi to jade laye naa, to si ṣafihan ara rẹ bo ṣe n kọrin rẹ.

Akọrin miiran, Pelumi Deborah sọ pe ni ṣe ni awọn jọ n rẹrin, ṣere papọ ni ọjọ mẹta sẹyin ti awọn pade, to si sọ pe bi maa ri laipẹ ṣe di o di gbere laaarin igba perete.

Bimpe Akintunde ti ọpọ mọ si Wasila Coded gbadura ki Ọlọrun tu iyawo atawọn ọmọ rẹ loju.