Kò sí ààyè fún ọkùnrin láti wọ yẹtí tàbí di irun wá sí Mọṣalaṣi wa mọ́- Shiekh Ayanbadejo Muftaudeen

Oríṣun àwòrán, @others
Imaamu agba Ilẹ Ijebu nipinlẹ Ogun, Sheikh Muftaudeen Ayanbadejo ni iroyin ti gba igboro kan pe o ti fopin de ki ọkunrin to dirun bi obinrin tabi to wọ yẹti si eti rẹ wa maa kirun Jimo ni Mọṣalaṣi ni Ijebu.
Ikede naa sọ pe ofin yii yoo bẹrẹ si ni fẹsẹ mulẹ lati ọjọ Eti, ojọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2026 yii.
Bakan naa ni Sheikh tun sọ pe ko tọna lati maa lo ẹrọ alagbeka ibanisọrọ lasiko irun Jimọ.
Tabi ki ẹni to ya 'Tattoo' si ara maa ṣi ara silẹ wa si mọsalasi ti ko si ni jẹ ki ọkan awọn to n kirun ni tosi rẹ papọ sinu adua ti wọn n gba.
Imaamu agba naa ni pe ẹnikẹni to ba jẹ Olujọsin tootọ ko yẹ ko maa gbe foonu dani lasiko ti adura ba n lọ lọwọ ni mọṣalaṣi.
Ati pe ẹnikẹni to ba n tẹ foonu lasiko adua ni wọn yoo gba foonu naa lọwọ ẹ titi irun kiki yoo fi pari.
Kini o ṣokunfa ofin tuntun yii?
Imaamu agba naa ni wọn sọ pe o dara ki ọkan gbogbo olujọsin papọ lasiko adua ninu mọṣalaṣi.
Ati pe ko ni si aifọkansin lasiko irun kiki ti ko ba ti si foonu lọwọ awọn to n kirun tabi to n ṣe adua.
Ofin tuntun yii ni ọpọ eeyan ti n sọ nipa rẹ lori ayelujara lasiko yii.
Bi awọn kan ṣe n gboṣuba kare fun Imaamu agba naa ni awọn miran n sọ pe iwa lẹsin kii ṣe bi eeyan ba ṣe ri tabi mura.
Kini o tun wa ninu atẹjade ofin naa?
Imaamu tun sọ pe ko si aaye fun ọkunrin to ba di irun gigun, to ba ya 'Tattoo'tabi irun Dada ati ọwọ da ti oloyinbo n pe ni 'Dread'.
Ọọfisi Imaamu tun fi atẹjade sita pe igbesẹ yii kii ṣe lati ba ẹnikẹni ninu je tabi lati dẹyẹ si ẹnikẹni rara.
Sugbọn igbesẹ naa wa lati da ikọni ati ọwọ pada sinu Mọṣalaṣi ni.
Paapaa lati da nkan pada si bi wọn ṣe n ṣe e tẹle nigba nni ti aye fi n roju ti aye fi n raye. ki onikaluku le maa fi ayọ gbadura to wa gba ko si kirun bi ilana Islam ṣe laa kalẹ laisi wahala.
Adari ifitonileti ni Mọṣalaṣi Ijebu naa, Omowe Oyekolade Oyesanya salaye kikun ninu atẹjade to fi sita pe igbesẹ ofin Imaamu agba yii ni lati da ààtò pada sinu mọṣalaṣi ni.
Pe ki ẹnikẹni ma fi ṣe ibinu rara nitori pe a ko le sọ pe aye di aye ọlaju ki a wa maa fi oju egbo tẹ ilẹ..
Bẹẹ, aibọwọ fẹnikan bo ti yẹ naa lo kuku sun igbeaye ẹda di bo ṣe di lasiko yii.



























