"Àwọn ọlọ́pàá ló wá kìlọ̀ fún wa pé ká kúrò nílé nítorí bandiiti, oṣù karùn-ùn rèé tí a ti ń wọ àwọ̀sùn kiri"Pasitọ Omoleyin

Oríṣun àwòrán, Pastor Isaac Omoleyin
Baale ile lasan kọ ni Alagba Isaac Omoleyin, pasitọ to n jinyinrere Oluwa tun ni niluu Idofian, ipinlẹ Kwara.
Amọ lati oṣu Karun-un ọdun 2026 yii lo ti dẹni ti ko le wọ inu ile rẹ sun mọ, nitori ibẹru awọn bandiiti to ni ọlọpaa kilọ rẹ fawọn.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun BBC News Yoruba, Ajihinrere Omoleyin sọ pe:
"Iyawo mi ni ile awọn ọmọ alailobi, ibẹ ni awa naa n gbe. Ni ọgbọnjọ oṣu Karun-un ni awọn ọlọpaa de, ti wọn waa sọ fun wa pe awọn bandiiti n bọ lagbegbe wa, pe a ni lati file silẹ laaarin wakati kan.
" A sare n ko awọn ọmọ ikoko to ṣi wa ninu ibusun ta a tẹ wọn si, iyawo mi gbe, emi naa gbe, sibẹ wọn ṣi ṣẹku.
"A ṣaa kuro bi wọn ṣe ni kilọ fun wa.Oru yẹn la de igboro, igboro naa ni a ti wa latigba yẹn."
Alagba Omoleyin tẹsiwaju, pe ọjọ kẹta lẹyin tawọn kuro nile ni awọn bandiiti lọọ ṣọṣẹ niluu abinibi oun ti i ṣe Iluge, ti won si pa awon eeyan nibẹ.
O fi kun un pe awon ọmọ to ti n gbe nile oniyara pupọ wa di ẹni tawọn n pin kiri bayii, oun pẹlu idile oun ko si nile lori mọ.
"Niṣe ni mo n sun kiri, mi o nile. A kọ lẹta si ọlọpaa pe ṣe a ti le pada sile, wọn ni awọn naa ko ti I mọ, awọn ṣi n wo o lọwọ."
Baba naa sọ pe idi niyẹn tawon si fi n duro nigboro, wọ awọsun titi digba ti ọlọpaa yoo tun fun awọn ni iyọnda lati pada sile.
" O ti su mi, mo fẹ pada sile mi." Bẹẹ ni Alagba Omoleyin wi.

























