Àwọn èèyàn Igbokoda ké sí ìjọba lẹ́yìn òórùn tó gba ìlu kan nítorí ọkọ̀ òfúrufú ọmọ ogun tó já síbẹ̀

Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Orimisan Aiyedatiwa, igabkeji rẹ ati ọga ologun nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni Igbokoda
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn olugbe ilu Igbokoda nipinlẹ Ondo ti ke gbajare si ijọba ipinlẹ naa lẹyin oorun to gba agbegbe ti baalu ileeṣẹ ọmọ ogun, NAF, ja si niluu ọhun.

Ori ade ilu naa, Ọba Afolabi Odidiomo sọ fun ileeṣẹ iroyin Premium Times pe oku awọn eeyan to ri sinu omi naa lẹyin ti baalu ọhun ja ti ba omi ti awọn n mu jẹ, eyii si le fa ajakalẹ arun fun awọn.

Gẹgẹ bo ṣe, baalu naa to ja tun ba awọn igi ati ẹja inu odo naa jẹ, eyii to jẹ orisun ounjẹ ati ọrọ aje fun awọn eeyan oun.

Lẹyin naa lo ke si ijọba ipinlẹ Ondo, ijoba apapọ ati ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ki wọn wa nnkan ṣe si ọrọ naa ni kankan ko to yọri si aisan fun awọn araalu.

Gomina Aiyedatiwa pasẹ ki wọn fi oogun apakororo sinu odo naa

Ẹwẹ, lẹyin ẹbẹ Kabiesi ni gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa paṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika ki wọn bẹrẹ si n fi oogun apa kokoro sinu odo naa.

Aṣẹ yii lo waye lọna ati dena ajakalẹ arun to le waye lẹyin ijamba baalu naa to waye nibẹ nitori odo ọhun ni ọpọ araalu n mu ti wọn si fi n se ounjẹ atawọn nnnkan mii.

Aiyedaiwa tun paṣẹ pe ki wọn maa gbe agba omi lọ fun awọn olugbe igbokoda ti iwadii ba fi han pe omi naa ti bajẹ kọja mimu.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade ti kọmiṣọna fun ọrọ iroyin ati itaniji, Idowu Ajanaku fi lede.

Ajanaku so ninu atẹjade naa pe afojusun ijọba ipinlẹ Ondo ni lati yanju ọrọ naa lai ṣakoba kankan fun awọn eeyan Igbokoda.

O ni Aiyedatiwa tun pasẹ ki wọn pese ibomu atawọn ohun idaabo bo ara ẹni mii fun awọn eeyan naa latari awọn oorun to n jade lati ibẹ.

Iṣe ṣi n lọ lọwọ ninu odo naa – NAF

Wayi o, ileeṣẹ ọmọ ogun ti sọ pe iṣẹ si n lọ lọwọ ninu odo naa lati ṣawari awọn ẹya ara baalu to ja sinu rẹ fun iwadii.

NAF sọ pe ti iṣẹ naa ba ti pari loun yoo jiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan lori ọrọ ayika lati mọ bi wọn yoo ṣe gbọ ti akoba ti iṣẹlẹ naa le ṣe farralu.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, ọgagun Ehimen Ejodame lo sọrọ yii ninu atẹjade kan niluu Abuja.

Atẹjade naa sọ pe ipo ti awọn eeyan Igbokoda wa n kọ oun lominu amọ awọn ko ni fi awọn eeyan na silẹ lai gbe igbesẹ to yẹ fun aabo ati alaafia wọn.

Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karun un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ti a wa yii ni baalu naa ja lulẹ lasiko to n rinrinajo lati ilu Benin lọ si Eko, ti gbogbo eeyan marundinlọgbọn to wa ninu rẹ si jade laye.