Kí ló mú Dele Farotimi fi ẹgbẹ́ Afenifere sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi/Facebook
Ilumọọka ajafẹtọọ ọmọniyan to tun jẹ agbẹjọro, Dele Farotimi, ti kede wi pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ Afenifere lẹyin ọdun mejidinlọgbọn to ti wa ninu ẹgbẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti Farotimi fi lede loju opo ayelujara rẹ eyi ti o pe akori rẹ ni ''Bi Mo Ṣe fi Afenifere Silẹ'' ni o ti sọ pe ẹgbẹ Afenifere ko ni duro fun erongba oun mọ.
Farotimi ṣapejuwe asiko to darapọ mọ Afenifere nigba to jẹ alaga akọkọ ẹgbẹ ''Binukonu'' lọdun 1998 gẹgẹ bii asiko to ṣe pataki ninu iṣẹ ilu toun ti ṣe.
O ni asiko toun wa ninu ẹgbẹ Afenifere yii naa loun lanfaani lati kopa ninu idagbasoke eto oṣelu orilẹede Naijiria.
Ajafẹtọọ naa ko ṣai dupẹ fun awọn iriri ati anfaani ti o ni lasiko to fi jẹ ọmọ ẹgbẹ Afenifere.
Amọ, Ọgbẹni Farotimi sọ pe oun ti pinnu bayii lati fopin si ibaṣepọ oun pẹlu ẹgbẹ Afenifere, ati wi pe ẹgbẹ naa ko ni duro fun erongba oun mọ.
Ọgbẹni Farotimi sọ pe igbesẹ lati fi Afenifere silẹ jẹ igbesẹ to nira foun ṣugbọn ti o ṣe pataki bakan naa.
Gbajugbaja amofin naa ko sọ idi to ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ ni pato ninu atẹjade to fi sita.
"Lati akoko yìí lọ, mi o ni sọrọ lorukọ Afenifere mọ, n ko si ni duro fun ẹgbẹ naa mọ níbi kibi.
Gbogbo nnkan ni akoko ati igba wa fún un labẹ oorun, asiko yii kii se akoko ti mo maa ṣàlàyé ìdí tí mo fi kuro ninu ẹgbẹ Afenifere.
Mo ti pinnu lati ma sọ ohunkohun lori igbesẹ mi lati fi ẹgbẹ Afenifere sílẹ̀, mo si rọ gbogbo eeyan lati ma bi mi ni ibeere kankan lori igbesẹ mi," Farotimi ṣalaye.
Ṣugbọn Farotimi ni oun ko ni kaarẹ lati maa pe fun orilẹede ti ipilẹ rẹ duro lori ilana eto ijọba awarawa ti ẹgbẹ Action Group ti Oloye Obafemi Awolowo and Afenifere gbagbọ ninu rẹ.


























