Gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí Toluwanisings jáde láyé

Toluwanisings mu gbohun gbohun lọwọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹbi gbajumọ akọrin ẹmi, Olayemi Bayonile Bolaji, tawọn eeyan mọ si Toluwanisings ti kede pe olorin naa ti jade laye.

Ẹbi Toluwani kede loju opo Instagram oloogbe naa wi pe laaarọ Ọjọru ọjọ kẹrinla oṣu Kẹwaa yii ni akọrin ẹmi ọhun ki aye wi pe o digba o ṣe.

Wọn wa rọ gbogbo ololufẹ Toluwani wi pe ki wọn maa ranti iyawo, ọmọ ati ẹbi rẹ ninu adura lasiko ti wọn n ṣọfọ yii.

Ẹbi akọrin naa tun sọ pe awọn yoo maa kede eto isinku rẹ laipẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Iku awọn ọdọ ba ni lọkan jẹ, eyi ki i ṣe eto Ọlọrun fun wa- Olajengbesi

Lojiji ni ori ayelujara bẹrẹ si i gbe e l'Ọjọru, ọjọ kẹrinla oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii, pe gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Olayemi Bayonile Bolaji tawọn eeyan mọ si Toluwanisings' ti jade laye.

Irqoyin to gbode naa sọ pe Toluwanisings deede ṣubu lulẹ ni, o si ku.

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ, ti ọpọ eeyan to mọ akọrin naa si n gbadura pe ko gbọdọ ri bẹẹ, ni Pelumi Olajengbesi, gbajumọ agbẹjọro tun gbe ikede jade lori iku ọhun.

Bakan naa si ni awọn ẹka iroyin ọlọkan-o-jọkan tun n gbe e pe Toluwanisings ti ku.

Loju opo Facebook rẹ lọsan-an ọjọ naa, Amofin Pelumi Olajengbesi fi iyalẹnu han lori iroyin naa, bakan naa lo beere fun aanu atoke wa.

Olajengbesi kọ pe:

"Iku awọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin maa n ba mi lọkan jẹ gan-an. Eyi ki i ṣe eto Ọlọrun fun wa. A ko fẹ iku aitọjọ.!"

Bakan naa ni Olajengbesi tun sọ pe o yẹ ka ri ohun to fa iku yii.

O ni: "Toluwanisings, a gbọdọ mọ ohun to fa eyi.!"

Nigba to n da si ọrọ yii ni tirẹ, Wolii Agba ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Ayo Ajewole, rọ awọn eeyan lati ma ṣe sare gba pe Toluwanisings ti ku.

Wolii agba kọ tiẹ pe:

" Ẹ jọọ nao. Ẹ jọọ, ẹ ni suuru, ẹ ma ti I gba pe bẹẹ ni, a n gba Ọlọrun gbọ, ẹ jọọ."

Amọ nipari ọrọ rẹ naa, o fi ami omije ẹkun sibẹ, ati ami ifẹ ọkan to tuka.

Ikede wolii agba loju opo Facebook rẹ

Akọrin miran, Boye Best naa sọ pe, "Bẹẹ ni, mo nigbagbọ ninu Ọlọrun. Ọlọrun, wa a ṣe eyi."

Bẹẹ ni awọn ọrọ wọnyi n lọ lori ayelujara, amọ ko sẹni to sọ pato bi iku ọhun ṣe jẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii.

Bakan naa ni adẹrinpoṣonu ori ayelujara, Lady Comfo, naa gbe e soju opo rẹ, pe to ba jẹ ẹṣẹ ni, k'Oluwa dakun dariji. O ni ki Toluwanisings sun ire.

Titi digba ti a pari akojọpọ iroyin yii, bi nnkan ṣe wa ni pe ori ayelujara n kede iku naa.

BBC News Yoruba yoo maa fi to yin leti bo ba ṣe pada jẹ.

If it's our sin

Ta ni Toluwanisings?

Toluwanisings ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Olayemi Bayonile Bolaji jẹ ọmọ ilu Ikirun, nipinlẹ Osun.

Akọrin ẹmi ati adari isin ni awọn eeyan mọ ọn si.

O tun n ṣiṣẹ ile ta a mọ si Estate Valuer lede oyinbo.

Toluwanisings maa n kọ orin fawọn eeyan lati ọwọ ara rẹ (Song writer).

Ọpọlọpọ orin rẹ wa loju opo ayelujara bii Instagram ati Tiktok, awọn eeyan si mọ ọn bii ẹni mowo lawọn oju opo naa pẹlu bi wọn ṣe maa n lo awọn orin rẹ fun adura loju opo adani wọn.

Ọjọ kẹjọ oṣu Keje ni wọn bi i (A ko ri akọsilẹ ọdun).

O ti le ni ọdun mọkanla ti Toluwanisings ti n kọrin bi akọsilẹ ṣe wi.

Lara awọn orin to ti ṣe ni "Unreserved Praise, A Very Big God, Onibuore, E Lagbara, ati Owo Re Meji Meji.