Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní kóòtù lónìí tí ìgbẹ́jọ́ òṣìṣẹ́ FRSC Ogun tí wọ́n pa òun àtọmọ rẹ̀ l'Osun bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @others
Gẹgẹ bi a ṣe fi to yin leti ṣaaju, oni ọjọ Aje, ọjọ kejila oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii lo yẹ ki igbẹjọ lori iku Oloogbe Oluwafunmilayo Lasisi ati ọmọ rẹ, Adesewa Lasisi, bẹrẹ nile ẹjọ giga ilu Osogbo, ipinlẹ Osun.
Tẹ o ba gbagbe, Oloogbe Lasisi ni oṣiṣẹ ajọ FRSC ipinlẹ Ogun, ẹni ti ọrẹkunrin rẹ, Fajemirokun Victor, tan lọ si ipinlẹ Osun lọjọ Keji Osu kọkanla ọdun 2025.
Lati Abeokuta, ipinlẹ Ogun ti Oloogbe n gbe pẹlu ọmọ rẹ ni wọn ti rin irinajo lọ si Osun, amọ irinajo naa pada di alọ iwale mọ.
Irin-ajo naa ni wọn rin ti wọn fi kagbako iku ojiji lọwọ ọrẹkunrin rẹ lọjọ kọkandinlogun oṣu Kọkanla, ọdun 2025.
Ọwọ pada ba Fajemirokun pẹlu awọn meji mi-in ti ijọba fẹsun ipaniyan kan, igbẹjọ naa lo si bẹrẹ lonii ọjọ Aje nile ẹjọ giga ipinlẹ Osun.
Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ
Lasiko to yẹ ki igbẹjọ naa bẹrẹ, ti awọn afurasi olujẹjọ ti wa nile ẹjọ ni òye foju han pe agbẹjọro wọn ko wa si kootu.
Bakan naa ni agbẹnusọ ijọba lori ẹsun naa, Muyiwa Ogunleye, sọ fun BBC News Yoruba pe iwe ẹjọ naa ṣẹṣẹ tẹ oun lọwọ ni.
O ni oun ni lati yẹ ẹ wo daadaa koun le mọ ibi ti ẹjọ naa de duro.
Nitori awọn idi meji yii ni igbẹjọ naa ko ṣe waye mọ lonii to yẹ ko bẹrẹ.
Agbẹjọro ijọba naa bẹ kootu lati sun igbẹjọ siwaju.
Ki ni Adajọ wi?
Nigba to n gbe ọrọ rẹ kalẹ, Adajọ Adeyinka Aderibigbe to n gbọ naa sọ, pe oun ko tun ni fi aaye gba wọn lati sun igbẹjọ naa siwaju mọ.
Adajọ sọ pe bi wọn ko ba ti mu agbẹjọro awọn olujẹjọ wa sile igbẹjọ mi-in toun yoo kede,oun ko sun un siwaju mọ.
Lẹyin eyi ni Adajọ Aderibigbe kede pe ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila ọdun 2026 yii ni igbẹjọ naa yoo bẹrẹ pada, ohunkohun ko ni i yi i pada mọ bo ṣe sọ.
Ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí Lasisi Funmilola, òṣìṣẹ́ FRSC tí wọ́n pa l'Osun

Oríṣun àwòrán, Others
Lonii, ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni igbẹjọ bẹrẹ lori oṣiṣẹbinrin ti ajọ ẹṣọ aabo oju popona tijọba apapọ, FRSC ti awọn amookunṣeka ṣeku pa nipinlẹ Osun.
Lasisi Funmilola Oluwamayokun, ẹni ogoji ọdun ati ọmọ rẹ, Adesewa, ọmọ ọdun mejila ni wọn tan kuro nile wọn niluu Abeokuta, lọ siluu Osogbo, ipinlẹ Osun, nibi ti wọn ti pa wọn.
Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Osun to wa niluu Osogbo, ni igbẹjọ ọhun yoo ti bẹrẹ, niwaju Onidajọ Aderibigbe ti ile-ẹjọ kẹrin.
Ẹsun to nii ṣe pẹlu igbimọpọ, ipaniyan ati ijinigbe la gbọ pe wọn fi kan awọn afurasi mẹta tọwọ tẹ, Gboyega Daramola, Sunday James, ati Fajemirokun Victor ninu ẹsun ti nọmba rẹ jẹ HOS/18c/2026.
Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Tẹ o ba gbagbe, ọdun to kọja ni iroyin gbode lori iku arabinrin naa ati ọmọ rẹ eyi ti wọn ni ko sẹyìn bi ọrẹ rẹ kan ṣe tan-an lọ si ipinlẹ Osun lati ipinlẹ Ogun to ti n ṣiṣẹ, to si tan an lọ si ọdọ babalawo lati fi ṣe etutu ọla rẹ.
Ni ọjọ Kẹta osu Kejila ọdun 2025 ni ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun fi oju awọn afurasi to ṣe iku pa Arabinrin Oluwafunlola ati ọmọ rẹ Adesewa lede.
Ọjọ Aje, ọjọ Kẹtadinlogun osu Kọkànlá ọdun 2025, ni afurasi Gboyega Daramola, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Aberefa" mu awọn agbofinro lọ si ilu Esa-Odo ni ipinlẹ Osun nibi ti wọn gbe oku arabinrin Funmilola Oluwamayokun, ẹni ọdun mejidinlogoji pamọ si.
Nigba ti wọn fi maa debẹ, ko si awọn ẹya ara bii ọyan, ọwọ mejeeji, oju ara atawon mii lara arabinrin naa.
Lẹyin iwadii ni Ile-iṣẹ ọlọpaa gbe oku arabinrin naa lọ si Ile igbokusi ti Ile iwosan Fasiti ipinlẹ Osun.
Lati igba naa ni oku Arabinrin Oluwafunlola ati ọmọ rẹ Adesewa ti wa nile igbokusi titi di asiko yii ti wọn fẹ sin-in.
Oluwafunlola jẹ ọga lẹnu iṣẹ ẹsọ ọkọ oju popo (FRSC) ti ijọba apapọ, ẹka ti ipinlẹ Ogun ko to jade laye.
























