Ọ̀pọ̀ èèyàn farapa, ilé dàwó, látàrí ìbúgbàmù méjì tó wáyé ní Rivers àti Edo

Eefi to n jade lati ara ibugbamu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko din ni eeyan marun-un to padanu ẹmi wọn nigba ti ọpọ awọn mii si farapa bi ibugbamu ṣe waye ni agbegbe ọtọọtọ ni ipinlẹ Edo ati Rivers.

Ni ipinlẹ Rivers, ọpa gaasi lo bu gbamu ni agbegbe Aleto, ijọba ibilẹ Eleme ni irọlẹ ọjọbọ, to si sokunfa ki eeyan to le ni ogun farapa, ba ọpọ ile ati ṣọọbu jẹ.

Ni ipinlẹ Edo tanka epo kan to ṣubu lulẹ ni Oluku, ijọba ibilẹ Ovia North-East gba ẹmi eeyan marun-un, tawọn marun-un mii, to fi mọ oloyun kan si farapa.

Iroyin ni awọn eeyan to farapa nibi ni ipinlẹ Edo ni wọn ti ko lọ sile iwosan University of Benin Teaching Hospital, ti wọn si ti n gba itọju.

Awọn ibugbamu yii mu ki ọpọ eeyan padanu okoowo wọn ti ọpọ si di alainile lori mọ.

Ni ipinlẹ Rivers, nnkan bii aago marun-un irọlẹ ni wọn ni ibugbamu naa waye ni Aleto, ti wọn si ni ọpa epo kan to je ti ileeṣe Nigeria Gas Company lo n jo, to si fa ibugbamu naa.

Awọn olugbe agbegbe naa fẹsun kan pe lati bii ọsẹ mẹta ni ọpa epo naa ti n jo ko to di pe o bugbamu, da ijamba ina silẹ lọjọbọ.

Wọn ni lati igba ti wọn ti ṣakiyesi pe ọpa epo naa n jo ni awọn eeyan ilu naa ti lọ fi to awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa leti lati bii ọsẹ mẹta, amọ wọn ko gbe igbesẹ kankan.

Iroyin ileeṣẹ The Punch sọ pe ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Stanley to n gbe ni agbegbe naa sọ pe awọn to n kọja, atawọn to ni ṣọọbu ni agbegbe naa ni ijamba ọhun ṣe lọṣẹ julọ.

O ni ọpọ eeyan ni wọn gbe lọ sile iwosan fun ara wọn to ṣeṣe, tawọn ọkọ atawọn ṣọọbu to wa ni agbegbe naa si dawo.

O fi kun pe ile to ni aadọta atawọn ọkọ ni ijamba naa ṣe lọṣẹ, to si fẹsun kan pe ko si aṣoju ileeṣẹ naa kankan to ti yọju si agbegbe naa lati gba ti ibugbamu naa ti waye, ti wọn n rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati tete bawọn mojuto.

Èèyàn mẹ́jọ farapa bí táńkà agbépo ṣe jóná ní ìpínlẹ̀ Edo

Ni ipinlẹ Edo ẹwẹ, tanka epo to ṣubu, gbina eyi to ṣokunfa bi ọpọ eeyan ṣe farapa.

Agbẹnusọ ẹṣọ oju popo, Federal Road Safety Corps State Commander, FRSC Preye Ezekiel Bedford, sọ pe awọn ko le sọ pe iye eeyan kan lo ba iṣẹlẹ lọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Edo, Eno Ikoedem ninu atẹjade to fi soju opo rẹ sọ pe ọkọ nla agbepo kan ṣoṣo lo waye ni opopona Benin si Eko ki ijamba naa to waye.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa tete ko awọn oṣiṣẹ rẹ de ibi ti ijamba naa ti waye, lojuna ati ri daju pe wọn da aabo ẹmi awọn eeyan.

O sọ pe ọlọpaa ṣe aridaju rẹ pe wọn gbọn epo naa lati inu ọkọ naa sinu ọkọ mii amọ to ni o ṣeni laaanu pe ọkọ naa gba ina eyi to ṣokunfa ki ọja to wa ni agbegbe naa jona, ti ọkọ meji mii naa si ba iṣẹlẹ naa lọ.

Bakan naa lo sọ pe eeyan mẹjọ lo tun farapa nibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si gbe wọn lọ sile iwosan University of Benin Teaching Hospital.