Lẹ́yìn ìkọlù ikọ Houthi sí Saudi Arabia tó gbá ẹ̀mí èèyàn 13, tí èèyàn sì 308 farapa, ìkọlù míì tún wáyé, ẹ́mí kan bọ́, èèyàn mọ́kànlá farapa

Àkọlé fídíò, Fidio papakọ ofurufu Riyadh ree lẹyin ikọlu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn alasẹ ti kede pe eeyan kan ti ku nigba ti awọn mọkanla miran fara pa lasiko ti ikọlu keji waye ni papakọ ofurufu to wa nilu Riyadh lorilẹede Saudi Arabia.

Akọtun isẹlẹ keji yii lo waye lẹyin ọjọ kan ti ikọlu akọkọ waye ni papakọ ofurufu naa eyi to mu ẹmi mẹtala lọ, tawọn eeyan mẹjọlelọọdunrun si farapa.

Agbẹnusọ fun ikọ ologun nilẹ Saudi Arabia salaye pe ọjọ Aiku ana ni ikọlu naa waye ni papakọ ofurufu King Khalid, eyi to mu ki ina sọ ni gbagede tawọn ero maa n duro si.

Atẹjade kan ti ileesẹ to n se akoso eto irinna nilẹ Saudi Arabia fi sita loju opo ayelujara rẹ, X salaye pe ọmọ ilẹ Pakistan kan to n gbe nilẹ naa ni wọn sekupa ninu isẹlẹ naa.

Ina n jo ni Papakọ ofurufu Riyadh ri Houthi se ikọlu si

Ikọ Houthis ni oun n dojukọ ilẹ Saudi Arabia lori atilẹyin to se fun ikọ ologun ijọba lasiko ogun abẹle ni Yemen

Ikọ Houthi nilẹ Yemen salaye pe oun lo wa nidi ikọlu naa, to si sekilọ fawọn ero atawọn ileesẹ ọkọ ofurufu lati ta kete sawọn papakọ ofurufu ati oju ofurufu ilẹ Saudi Arabia.

Ikọ naa ni oun ti doju awọn eroja abugbamu kọ papakọ ofurufu naa, pẹlu ẹrọ diroonu laarin ọjọ kan pere.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun ileesẹ ologun ilẹ naa, Ọgagun Yahya Saree ti ni ikọ Houthi naa tun kọlu awọn ibudo epo orilẹede Saudi Arabia ati papakọ ofurufu Damman to wa lẹkun ariwa ilẹ naa.

Ikọ Houthis ti kede pe oun n dojukọ ilẹ Saudi Arabia lori atilẹyin to se fun ikọ Ologun ijọba lasiko ogun abẹle ni Yemen ati ikọlu si papakọ ofurufu to waye ni papakọ ofurufu Sanaa.

Ọmọ orilẹede Saudi Arabia mẹrin, eeyan meji lati ilẹ Bangladesh ati eeyan kọọkan lati ilẹ Amẹrika, Jordan, Palestine, Syria, Sudan ati Egypt lo ku ninu ikọlu naa

Lọjọ Aiku ana ni ọgagun Turki Al- Maliki tii se agbẹnusọ fun ikọ Ologun alajumọse ilẹ Saudi kede pe ẹka to n daabo bo oju ofurufu rẹ ti sẹburu awọn ado iku kan lẹba papakọ ofurufu Riyadh, tijọba si n wa ọna bi yoo se pa ina ti ado oloro da silẹ ni ibudo awọn er oni papakọ ofurufu ilẹ naa.

Ikọlu to waye lọjọ Satide lo tii buru julọ ti yoo waye nilẹ Saudi Arabia lati igba ti ogun ti n waye lagbegbe naa eyi ti ogun Israel ati Iran ti bẹrẹ losu keji ọdun yii.

Ikọ ogun alajumọse nilẹ Saudi ti wa seleri lati fesi si isẹlẹ naa eyi to pe ni iwa ọdaran loju ogun.

Ọmọ orilẹede Saudi Arabia mẹrin, eeyan meji lati ilẹ Bangladesh ati eeyan kọọkan lati ilẹ Amẹrika, Jordan, Palestine, Syria, Sudan ati Egypt naa ku.

Awọn orilẹede kilọ fawọn ọmọ ilẹ wọn lati mase rinrinajo lọ silẹ Saudi Arabia

Bakan naa ni ileesẹ asoju ijọba ilẹ India to wa nilẹ Saudi Arabia ni ọmọ ilẹ India kan to fara gbọgbẹ nibi isẹlẹ naa ti jade laye.

Akọwe ọrọ abẹle nilẹ Amẹrika, Marco Rubio wab u ẹnu atẹ lu ikọlu naa, to si fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọmọ ilẹ Amẹrika kan ku nibi ikọlu naa.

Bakan naa ni ileesẹ asoju ilẹ UK to w ani orilẹede Saudi Arabia ti wa sekilọ fun awọn ọmọ ilẹ naa lati mase rinrin ajo lọ silẹ Saudi lasiko yii to fi mọ ilẹ Yemen to mule ti i.