Regina Daniels ṣàlàyé ìdí tó fi di ẹni tó ń jókòó sórí 'wheel chair'

Oríṣun àwòrán, Regina Daniels/Facebook
Gbajugbaja oṣere ilẹ Naijiria nni, Regina Daniels ti ṣalaye nipa idi to fi di ẹni ti ko le dide rin daadaa mọ, to si jẹ pe ori aga ijokoo 'wheel chair' lo n jokoo si bayii.
Regina Daniels sọ pe o ti to ọpọlọpọ oṣu toun ko ti le rin mọ bayii, to ni ipenija ailera to n ba oun finra lasiko yii ni aikole rin.
Oṣerebinrin naa lo sọrọ yii ninu fọnran to gbe soju opo ayelujara rẹ lọjọ Aje, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Fọnran naa lo tun fi n ṣajọyọ ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlọgbọn to n ṣe loke eepẹ.
Daniels wa lori aga ijokoo ti awọn ti ko ba le rin maa n lo.
Ninu fọnran naa, Daniels ṣapejuwe awọn irin ajo rẹ, to si loun n gbadura fun alaafia ati iwosan pipe.
"Mo ki gbogbo yin, ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlọgbọn mi ree. Eyi ni ipele miran nigbesi aye mi. Mo gbadura fun ifọkanbalẹ patapata. Mo ki ata mi ku ayẹyẹ ọjọ ib," o sọ bẹẹ ninu fọnran ọhun.
Oṣere ọlọmọ meji naa ṣalaye nipa bi irin ajo ailera rẹ ṣe bẹrẹ, to si loun lero pe nnkan kekere lasan ni, ṣugbọn to pada di nnkan toun ko lero.
"Fun ọpọlọpọ oṣu, mo padanu anfaani lati maa rin kaakiri bo ṣe wu mi. O bẹrẹ gẹgẹ bi nnkan kekere, ṣugbọn to pada di bayii," o ṣalaye bẹẹ.
Daniels sọ pe ailera naa bẹrẹ lẹyin ayẹyẹ awọn ọmọde toun gbe kalẹ laipẹ yii. O ni latigba naa loun ti lọ fun oniruuru ayẹwo lati mọ ohun to ṣẹlẹ.
"Ayẹwo ojoojumọ ti fẹẹ sọ mi di ekute yara ayẹwo"
O ni ayẹwo toun n lọ ṣe ni gbogbo igba ti fẹẹ sọ oun di ekute yara ayẹwo (Lab rat), to si ni irora toun n jẹ ni gbogbo igba n dagba sii, to si lewu foun.
"Bawo ni mo ṣe fẹẹ ṣalaye irora yii? Ilera naa le gidi, to si n dun mi. Nigba miran, mo maa n rin daadaa, nigba miran, nko le rin rara," o sọ bẹẹ.
O ni gbogbo iriri toun n la kọja lo n fi ojoojumọ gba omije loju oun, to si ni oju Ọlọrun nikan loun n wo lasiko yii fun iranlọwọ atokewa.
"Mo sunkun. Mo n woju Ọlọrun fun iwosan atokewa, nitori pe Oun nikan lo ni aṣẹ lori aye mi," Daniels fidi rẹ mulẹ.
Latigba to ti gbe fọnran yii sita, lawọn ololufẹ kaakiri agbaye ti n ba a kẹdun, ti wọn si n fi adura ran an lọwọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post



























