Tinubu gbọdọ̀ ṣàlàyé ìdí tó fi yan Yorùbá láti darí ẹ̀ka méjì gbóògì ní àjọ elétò ìdìbò INEC - Atiku

Aarẹ Bola Tinubu wọ buba olomi buluu, Joash Amupitan wọ kootu, Atiku Abubakar wọ buba ankara
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olùdíje sípò aarẹ f'ẹgbẹ òṣèlú ADC, Atiku Abubakar, ti bu ẹnu ẹtẹ lu iyansipo ọmọ Yoruba meji lati dari ẹka àjọ eleto idibo INEC gboogi meji.

Atiku sọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Phrank Shuaibu, fi sita.

Atiku sọ ninu atẹjade náà wí pé ọmọ Naijiria nilo alaye lori iyansipo Arabinrin Oluyemi Titilayo Adeyemi-Showunmi ati Ọmọwe Lawrence Bayode gẹgẹ bíi adari eto idibo ati iforukọsilẹ oludibo ati ẹka ibaraẹnisọrọ.

Igbákejì ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀ rí sọrọ yii leyin ti Adeyemi-Showunmi rọpo Magaji Gum nigba ti Ogbeni Bayode bọ sípò adari ẹka ibaraẹnisọrọ, eyi ti ọpọ gbagbọ pe ẹka to ṣe pataki ni ẹka mejeeji yìí.

Amọ, Atiku sọ pe Ààrẹ Bola Tinubu ní lati jẹ ki eto idibo 2027 wáyé láìsí eeru.

Olùdíje sípò ààrẹ fún ẹgbẹ ADC ke pe Tinubu lati kede ọna tó gbà yan an Adeyemi-Showunmi sípò.

Atiku ni ọmọ Naijiria ko ni gba ki ẹnikẹni ja eto idibo ọjọ kẹrindilogun oṣù kínní ọdún 2027 gba.

"Awọn ẹka méjì yíì jẹ gbòógì ninu ajo eleto idibo INEC, nitori naa INEC gbọdọ kéde ọna to gba to fi yan awọn mejeeji yìí sipo ko sí sọ amuyẹ wọn fún ipo ti wọn wa," Atiku lo sọ bẹẹ.

Atiku tun beere alaye lọwọ INEC nipa ileeṣẹ to n ṣe ohun elo idibo ati eto aabo ti wọn pese fawọn ohun elo idibo naa.

O ni awọn Naijiria ni lati mọ ileeṣẹ to n ṣe ohun elo idibo ti won fẹ lo nínú ètò ìdìbò odun 2027.

Atiku ni ọmọ Naijiria ko ni gba ki ẹnikẹni yi ibo lodun 2027.