Wo orúkọ ọmọ Naijiria 24 tí àjọ DHS fọwọ́ òfin mú lórí onírúurú ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn lórílẹ́èdè Amẹrika

Awọn ọlọpaa mu ọdọkunrin kan to di irun rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ United States Department of Homeland Security (DHS) to n ri si ọrọ aabo lori wiwọle si orilẹede Amẹrika lati ilẹ okeere ti gbe oruko ọmọ Naijiria mẹrinlelogun ti wọn ti fọwọ ṣinkun ofin mu lori oniruuru ẹsun iwa ọdaran to ni i ṣe pẹlu wiwọle si Amẹrika jade.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe ajọ to n ri si wiwọle si Amẹrika ati ọrọ ibode lo fọwọ ofin mawọn mẹrinlelogun ọhun.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ni fifi owo ranṣẹ soke okun lọna aitọ, ẹsun iwa ọdaran lori gbigbe egboogi oloro, iwe yiyi, lilo ohun ija oloro lọna ti ko ba ofin mu ati ihuwa ipa sọmọde.

Ajọ to n ri si eto aabo lori wiwọle si orilẹede Amẹrika lati ilẹ okeere sọ pe awọn ọdaran gidi lawọn ti fọwọ ofin mu bayii.

Ajọ naa so pe ileri Aarẹ Donald Trump lati le gbogbo awọn to wọ orilẹede Amẹrika lọna aitọ ni ajọ naa n tẹle.

Orukọ awọn ọmọ Naijiria naa ni ajọ ọhun gbe jade pẹlu ẹsun ti wọn fi kan wọn ati ibi ti wọn ti fọwọ ofin mu wọn.

Wọnyii ni orukọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti fọwọ ṣinku ofin mu l'Amẹrika lori oniruuru ẹsun iwa ọdaran.

Emmanuel Omowaiye ni wọn mu ni Richmond ni Texas lori jibiti fifi ọrọ ranṣẹ lori itakun agbọrọkaye ti wọn n pe ni emeeli.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

1. Emmanuel Omowaiye — Fun ẹsun jibiti fifi ọrọ ranṣẹ lori itakun agbọrọkaye

2. Laurene Onwuka — Fun lilo orukọ ẹlomiran lati lu jibiti

3. Olusegun Shonekan — JIbiti ori ayelujara

4. Olusegun Olaseni — Fun ẹsun tita oogun oloro

5. Peter Ude — Jibiti ori ayelujara

6. Newton Jemide — Igbimọpọ lati lu jibiti lori itakun agbọrọkaye

7. Shedrack Umukoro — Fifi owo ranṣẹ silẹ okeere lọna to lodi sofin.

8. Olasoji Akinbode — Lilo orukọ ẹlomiran lati lu jibiti.

9. Oluwatosin Afolabi — Fun lilu jibiti

10. Alameen Adetunji Tokosi — Gbigbe oogun oloro

11. Joshua Ipoade — Jibiti ori ayelujara

12. Michael Orji — Lilo ohun ija oloro lọna ti ko tọ, lilo ayederu iwe igbeluu ati kiko owo ranṣẹ silẹ okeere lọna to lodi sofin.

13. Ahmadu Apooyin — Gbigbe oogun oloro.

14. Teslim Kiriji — Kiko owo lọ silẹ okeere lọna ti ko ba ofin mu

15. Onomen Uduebor — Piparọ pẹlu iwe igbeluu

16. Charles Ochi — Kiko owo lọ silẹ okeere lọna aitọ

17. Daniel Eta — Jibiti ori ayelujara

18. Ifeanyi Ibennah — Iwa ipa si ọmọde

19. Kazeem Runsewe — Jibiti ori ayelujara

20. Fatiu Lawal — — Jibiti ori ayelujara

21. Justin Akubueze — Kiko owo lọ silẹ okeere lọna aitọ

22. Moyinoluwaseun Okeowo — ole jija

23. Babajide Oluwaseun Faseyi — Ikọlu si eeyan

24. Bright Eigbedion — Kiko owo lọ silẹ okeere lọna aitọ

Ajọ DHS ni ikede orukọ awọn afurasi ọdaran naa wa ni ibamu pẹlu ipinnu ijọba Aarẹ Trump lati ṣe afọmọ eto wiwọle si orilẹede Amẹrika.