Èèkàn ìlú míì tún kọ̀wé fípò sílẹ̀ nínú ìṣèjọba Seyi Makinde lẹ́yìn Segun Ogunwuyi

Oríṣun àwòrán, Facebook
Lẹyin ọjọ kan ti olori oṣiṣẹ ile ijọba ipinlẹ Oyo, Segun Ogunwuyi kọwe fipo silẹ, alaga igbimọ to n ri si akoso ile ẹkọ College of Agriculture and Technology, Igboora, Dokita Damilare Gideon Amusan naa ti kọwe fipo rẹ silẹ.
Dokita Amusan ninu lẹta to kọ ranṣẹ si Gomina Seyi Makinde lati kede ikọwefiposilẹ rẹ ni ọjọ Kẹtala ni igbesẹ naa ti bẹrẹ lẹyẹ o sọka.
O sọ pe oun gbe igbesẹ fipo naa silẹ lẹyin ti oun ṣagbeyẹwo ọrọ naa daadaa, to si ni oun dupẹ lọwọ Seyi Makinde fun anfaani to fun oun lati kopa oun lori idagbasoke ile ẹkọ naa.
Amusan ni enikẹta to n kọwe fipo silẹ laaarin ọjọ kan ninu iṣejọba Seyi Makinde lẹyin Segun Ogunwuyi, Tara Adefope, ti oun naa fipo silẹ gẹgẹ bi adari ileeṣẹ Due Process.
Ta ni Segun Ogunwuyi to kọwe fipo silẹ gẹgẹ olori oṣiṣẹ ile ijọba Seyi Makinde?
Ni ọjọ Aje, ọjọ Kejila, oṣu Kẹwaa ni Segun Ogunwuyi kọwe fipo rẹ silẹ gẹgẹ bi olori ile ijọba ipinlẹ Oyo.
Ogunwuyi ninu lẹta to kọ ranṣẹ si Gomina Seyi Makinde ni ọjọ Aje ni iṣẹ oun pari pẹlu rẹ, to si dupẹ fun aaye ti wọn fi gba a lati sin ijọba.
Awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa Segun Ogunwuyi niyi:
- Onimọ nipa iṣiro owo ati aato ilu to ni iriri to ti le ni ọdun mẹẹdọgbọn lẹka ileeṣẹ adani ati ti ijọba.
- Ṣaaju ko to di olori oṣiṣẹ nile ijọba Oyo labẹ iṣejọba gomina Seyi Makinde, o ti jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo laaarin ọdun 2011 si 2015.
- Bakan naa lo tun ṣokun ẹkun Ogbomoso North/South/Oriire laaarin ọdun 2015 si 2019 ni ile igbimọ aṣojuṣofin niluu Abuja.
- O ṣe oluranlọwọ gomina lori idokoowo lọdun 2019, to si tun jẹ adari agba fun ajọ Oyo State Investment and Public, Private Partnership Agency, OYSIPPPA ni ọdun kan naa.
- Ile ẹkọ Obafemi Awolowo University, Ile Ife, ipinlẹ Osun lo ti kẹkọọ gboye onipo kiini ninu imọ iṣiro owo, ko to tẹsiwaju kẹkọọ gboye onipo keji MBA ni ile ẹkọ kan naa.
- Lẹyin naa lo tun kẹkọọ gboye onipo keji MSC ninu imọ iṣiro ni ile ẹkọ Nasarawa State University, to si gbowe Ọmọwe ni ile ẹkọ Ajayi Crowther University, ipinlẹ Oyo.
Wo igi lẹ́yin ọgbà fún gómìnà Seyi Makinde méje tó ti kúrò lẹ́yìn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Se ni ariwo n sọ lori ayelujara nipa bi awọn alabasisẹpọ ati eekan gboogi ninu ijọba gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo se n fi ipo wọn silẹ ni ẹyọ kọọkan.
Bi ẹ ko ba gbagbe, gomina Makinde lo kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP lọ si APM, to si n dije dupo fun ipo aarẹ orilẹede yii latinu ẹgbẹ oselu naa.
Amọ bawọn igi lẹyin ọgba rẹ yii se n fi ojoojumọ ya kuro lẹyin rẹ lo n mu kawọn eeyan maa beere pe ki lo de ti eyi se ri bẹẹ.
Ni ana ode yii ni Olori osisẹ ni ọọfisi gomina, Hon Segun Ogunwuyi naa kọwe fipo silẹ pe oun ko sisẹ olori osisẹ ni ọọfisi gomina mọ.
Eyi si lo mu kawọn ọmọ Naijiria maa figbe bọnu pe ki lo de tawọn eekanlu fi n kuro lẹyin Gomina Seyi Makinde?
Lara awọn oloṣelu ati alatilẹyin jankan-jankan to ti kuro lẹyin Seyi Makinde ni iwọnyi:
1. Alhaji Rasak Gbadegesin (Ọmọ igbimọ Advisory Council).
2. Babs Oduyoye (Ọmọ igbimọ Advisory Council).
3. Amb Taofik Arapaja, (Igbakeji Makinde tẹlẹ).
4. Abbas Oloko ( Igbakeji alaga ajọ to n ri si eto irinna lọ si irinajo mimọ lọ si Mecca fawọn musulumi).
5. Yomi Olajide (Ọre Gomina, Royal Umbrella).
6. Barrister Micheal Lana (Ọmọ igbimọ Advisory Council).
7. Fatai Owoseni (Former SA Security)


























