Wo bí èèyàn kan ṣoṣo ṣe pín Ebola káàriri orílẹ́-èdè mẹ́ta

Awọn oniṣegun oyinbo ti wọn n tọju ajakalẹ arun Ebola
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Oṣiṣẹ banki orileede Kenya kan lo lọ si agbegbe ti ajakalẹ arun Ebola to n ṣeku pani wa, lati ibẹ lo si ti rin irin lọ si orileede mẹta ọtọọtọ lagbaye.

Lẹyin to de orileede to kẹyin, ni aisan naa bẹrẹ sii jẹyọ lara rẹ, ko to di pe o mọ pe oun ti lugbadi arun aṣekupani, Ebola.

Nigba to wa niluu Nairobi lo ṣakiyesi pe oun n ṣaisan, to si gba ile-iwosan lọ lati tọju ara rẹ, ile iwosan ni ayẹwo ti sọ pe wọn kofiri arun Ebola lara rẹ.

Alẹ ọjọ kẹta lẹyin ayẹwo naa lo gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, iyẹn lọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.

Ọkunrin, ẹni ogoji naa ni ẹni akọkọ ti yoo lugbadi arun Ebola lorileede Kenya.

Oniruuru ibeere ati ọrọ ariyanjiyan lo ti n jẹyọ bayii lorileede Kenya pẹlu bi wọn ko ṣe ri awọn aisan naa lawọn ile iwosan lorileede DR Congo ati lawọn papakọ ofurufu orileede Uganda.

Awọn araalu ti bẹrẹ sii sọr lori ipo ti eto ilera wọn wa, to fi mọ awọn ọna lati dẹkun ṣiṣe agbako arun Ebola.

Awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹrin ni arun Ebola ti ran lọ sajule ọrun lorileede DR Congo lọdun, eyi si jẹ ki wọn wa ni ipo keji ninu ikọlu Ebola to ti jẹyọ.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ní DR Congo?

Alakoso lori iṣẹlẹ pajawiri lorileede naa, Dokita Wessam Mankoula, ṣalaye nipa bi ọkunrin naa ṣe rin irin-ajo ẹgbẹẹgbẹrun kilomita lati tan arun naa kaakiri.

Ọkunrin naa ti wọn ko tii sọ idanimọ rẹ lo ti gbe lorileede DR Congo fun ọdun meje gbako, to si ti rin irin-ajo to nii ṣe pẹlu okoowo laaarin orileede mẹtẹẹta yii.

Ẹri nipa ibi to ti lugbadi arun Ebola ni ko tii foju han - ṣugbọn o wa ni awọn orileede mẹtẹẹta to lọ ni ibẹrẹ oṣu Kẹwaa, gẹgẹ bi ajọ eleto ilera agbaye, WHO ṣe sọ.

Ọkunrin naa ti lo ọpọ igba ati asiko ni agbegbe DR Congo bii Bas-Uélé, Buta, Aketi ati Likati, iyẹn ninu oṣu Kẹjọ si oṣu Kẹsan.

Ajọ WHO sọ pe iṣẹlẹ ajakalẹ arun Ebola jẹyọ ninu oṣu Kẹjọ, ọdun yii lẹkun BUta, iyẹn ko to di pe o rin irin ajo lọ sibẹ, bo tilẹ jẹ pe ko ẹri wi pe ibẹ lo ti ko aisan naa.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹsan ni aisan ọhun, wọn fun loogun lati lo ko to di pe wọn ni ko maa lọ sile.

awọn oṣiṣẹ ilera kan n gbaradi

Alẹ ọjọ kẹta, ni wọn daa duro si ile iwosan alabọọde Tongo Etandi to wa niluu Bondo, ibẹ lo si wa titi di ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan.

Pẹlu gbogbo ooru ati iyunra to n mu, ileeṣẹ to n ba ṣiṣẹ sọ pe ara yiyun lo n jẹ ko maa daku.

Wọn ko ṣawari Ebola lara rẹ, idi ree to fi ṣoro lati sọ pato ibi to ti lugbadi arun naa lasiko to rin irin ajo.

Awọn apẹẹrẹ ti wọn lo jẹyọ lara rẹ ni ti ẹni to ṣẹṣẹ lugbadi arun Ebola, ṣugbọn awọn aisan miran tun n jẹyọ ninu ayẹwo bii iba.

Ogunjọ oṣu Kẹsan, lo tun lọ si ilu Kisangani, ilu ti awọn eeyan rẹ to miliọnu kan ataabọ, ibẹ lo wa to ti gba itọju ọjọ mẹwaa.

Agbegbe yii ni wọn ti ni akọsilẹ eeyan mọkanelaadọta to ti lugbadi Ebola.

Nígbà tó dé Uganda

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alẹ ọjọ akọkọ ninu oṣu October, lẹyin to ti ṣaisan ọsẹ meji, ọkunrin gbe baalu miran to n lọ si ilu miran ti wọn pe ni Beni lorileede DR Congo.

Ibẹ lo ti gba lọ si Kasindi, ilu ti wọn ti n sọ ede Kikuyu, eyi to wa lẹnubode aala DR Congo ati Uganda.

Ilu Beni yii, ati ilu miran ti wọn n pe ni Kasindi ni Mount Kivu ni wọn sọ pe arun Ebola ti wọ ibẹ, ti wọn si ti ni akọsilẹ ẹgbẹrun kan aabọ le diẹ (1,755) awọn to ni Ebola.

Ninu awọn eeyan to lugbadi yii, awọn to le ni ẹgbẹrun kan ni arun naa ti pa, eyi lo jẹ ki agbegbe naa jẹ ibi ti arun Ebola ti ṣọṣẹ julọ ni DR Congo.

Ṣugbọn ko duro pẹ rara, ko to di pe o gbera lọ si Uganda.

Uganda ti fofinde lilọ kaakiri ninu oṣu Karn-un, nigba ti ajakalẹ arun naa kọlu wọn.

Awọn alakoso gbiyanju lati dena itankalẹ arun naa, nipa ṣiṣe ayẹwo, titọpinpin ibi to ti n bọ, ati lati maa ya awọn eeyan sọtọ.

Lọdun yii, wọn ti ni akọsilẹ arun naa, ti pupọ rẹ jẹ lati DR Congo - ṣugbọn ninu oṣu Kẹjọ, wọn jẹ ko di mimọ pe ko si arun naa mọ lorileede ọhun.

Lẹyin to de Uganda, o rin irin ajo ori ilẹ lọ si olu ilu orileede naa, Kampala, to si lọ si papakọ ofurufu Entebbe, nibi to ti wọ baalu lọ si Nairobi lorileede Kenya, lọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa.

Awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni Uganda sọ pe irisi rẹ jọ ti ẹni ti wọn n wa fun arun Ebola, bo tilẹ jẹ pe arun naa ko jẹyọ lara rẹ ni papakọ ofurufu ọhun.

Awọn akọṣẹmọṣẹ eleto ilera sọ pe aisan iba lo jẹyọ lara rẹ, ati pe lati maa sọ pe eeyan n ṣaisan, ko to lati sọ pe wọn n dena itankalẹ.

Mankoula sọ pe awọn ṣi n ṣe iwadii lọwọ lati mọ boya oogun ti wọn fun ọkunrin jẹ eyi to le mu ara rẹ ya kuro ninu aisan iba.

O sọ pe o ṣee ṣe ki aisan naa lọ silẹ lasiko to n gba papakọ ofurufu kọja, nibi ti wọn ti yẹ ẹ wo.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Kenya

Aworan eeyan kan ninu aṣọ idaabobo lọwọ arun

Bakan naa nigba to n de Kenya, ayẹwo ti wọn ṣe fun un ni papakọ ofurufu Jomo Kenyatta to wa niluu Nairobi, ko fi han pe ọkunrin naa ni aisan Ebola.

Papakọ ofurufu naa ni aburo rẹ ti wa gbe e, to si gbe e lọ si ile iwosan aladani kan.

NIgba naa, aisan Iba ti wọ ọ lara, to si jẹ ko maa gbọn gidi, ara tun n yun un, bẹẹ lo n pọ ẹjẹ lẹnu.

Igba yii ni ayẹwo ṣẹṣẹ sọ pe o ti lugbadi Ebola, eyi to n kọlu wọn lọwọ ni DR Congo.

Wọn lọ fi si inu yara itọju kan, nibi to da wa fun itọju. Ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa lo dakẹ, ti wọn si sinku rẹ lọjọ keji lati dena itankalẹ arun naa.

Ijọba ilẹ Kenya ti wa sọ pe awọn ti tọpinpin awọn mẹrindinlaadọrin ti ọkunrin naa ni ibaṣepọ tabi fi ara kinra pẹlu latigba to ti wọ Kenya.

Bẹẹ ni WHO sọ pe o ṣee ṣe ki awọn to fi ara kan le ni iye naa bo ṣe n rin irin ajo lati Uganda ati DR Congo, ti iwadii si n lọ lọwọ.