Mi ò ní juwọ́ sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni kódà bí ẹgbẹ́ alátakò bá parọpọ̀ di ọ̀kan - Adegoke, olùdíje ADC ní ìpínlẹ̀ Oyo

Taofeek Adegoke wọ aṣọ alawọdudu, de igo oju, o n wo ọọkan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo lẹgbẹ oṣelu Africa Democratic Party, ADC, Taofeek Adegboyega Adegoke ti sọ pe oun ko ni juwọ silẹ fun ẹnikẹni bi gbogbo ẹgbẹ oṣelu alatako ba parapọ di ẹyọkan.

Adegoke sọ eyi lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Oyo nibi eto idibo ọdun to n bọ.

O ni ọrọ oṣelu gba kiko ọpọ eeyan mọra, ti oun yoo si gba ọpọ eeyan to ba fẹ darapọ mọ oun laaye ṣugbọn oun ṣi ni oun maa durro gẹgẹ bi oludije.

"Kii ṣe ipinlẹ Oyo nikan lo maa nawo ọna oju irin ti mo fẹ ṣe lati Ibadan de Saki, awọn ileeṣẹ ilẹ okeere maa ran wa lọwọ"

Nigba to n sọrọ lori erongba rẹ lati ṣe ọna oju irin lati ilu Ibada n lọ si ilu Saki, Adegoke sọ pe igbesẹ naa maa ṣe iranwọ fawọn agbẹ to wa lawọn ilu yii lati le tete ko ere oko wọn lọ sawọn ilu to sunmọ wọn, ti ko si ni jẹ ki ero oko tete maa bajẹ laipẹ ọjọ.

O sọ pe ipele mẹta ni eto ṣiṣe oju ọna irin naa fi maa waye, ti oun si maa ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ileeṣẹ aladani lati le ri owo ti wọn fi maa ṣe ọna naa.

"Ọna mẹta la maa pin ọna yẹn si, a a kọkọ ṣe de Iseyin, to ba tun ya a ma ṣe de Okeho, ẹlẹkẹta a ma ṣe de Saki.

"Kilomita kan maa na wa bii miliọnu mẹta dọla, kii ṣe ipinlẹ Oyo nikan lo maa nawo yẹn ni mon n sọ yẹn, awọn ileeṣẹ kan wa ni okun ti wọn maa n ba eeyan ṣe iṣẹ yẹn."

Lori ọrọ ijọba ibilẹ, Adegoke ni ọgọrun-un ọjọ ti oun ba kọkọ de ipo ni oun maa fun awọn ijọba ibilẹ ni aaye lati di ominira ara wọn.

"Kii ṣe igun meji ni ẹgbẹ oṣelu ADC ni ipinlẹ Oyo, awọn kan lo lọ kora wọn jọ lati ṣeto idibo abẹnu nibi ti ko yẹ"

Adegoke tun sọ afọmọ ọrọ pe kii ṣe igun meji lo n gbe oludije sita ni ipinlẹ Oyo gẹgẹ bi ọpọ eeyan ṣe ro, o ni awọn kan ti wọn ti ẹru n ba ni wọn lọ ṣeto idibo abẹnu di ibi ti awọn adari ẹgbe ko faramọ.

"Ẹgbẹ mọ awọn ti wọn fọwọ si lati ṣeyo idibo abẹnu, oun lo fa a to fi jẹ pe orukọ mi lo jade lọdọ INEC."

Lori ọrọ wi pe o n darapọ ẹgbẹ oṣelu kaakiri, o ni nitori Olubadan toni, Oba Lamidi Ladoja ni oun ṣe darapọ ẹgbẹ oṣelu Accord, to si jẹ pe nitori Olubadan naa ni oun fi lọ si APC.

O fi kun pe kii ṣe pe awọn ọmọ oṣelu lo n gbe awọn oludije wọle sipo bikoṣe awọn araalu, o ni eyi lo fi jẹ pe ẹgbẹ oṣelu ti oun wa ko nipa kankan bikoṣe awọn araalu to maa fi ibo gbe oun wọle.