Tiger gbẹ̀mí lọ́rùn ọkùnrin kan níbi tí wọ́n ti lọ gbafẹ́

Aworan tiger ni Yorkshire Wildlife Park to ṣokunfa iku ọkunrin kan
Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ya aworan tiger yii ṣaaju ki iṣẹlẹ naa to waye
    • Author, Fiona Callow
    • Author, Julia Bryson
    • Role, Yorkshire
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹ ede England ni ọkunrin kan ti padanu ẹmi rẹ nigba ti ẹranko "tiger" ṣe ikọlu sii ni ọgba awọn ẹranko iju Yorkshire Wildlife Park.

Wọn ṣalaye pe wọn ri ọkunrin naa bo ṣe n lọ sinu ibi ti wọn pese fun tiger naa ni ẹba Doncaster ki wọn to ranṣẹ pe awọn ọlọpaa ni nnkan bii aago meji ọsan n lọ lu ni ọjọ Abamẹta.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Guusu Yorkshire sọ pe ni ile tiger naa lo ti ṣekọlu si ọkunrin naa to si padanu ẹmi rẹ loju ẹsẹ.

Ọlọpaa ni ko si ohunkohun to ṣe tiger ọhun to si ni ibugbe rẹ amọ wọn ti ti ọgba awọn ẹranko naa fun igba kan na.

Akọwe ijọba fọrọ ilẹ okeere ati aṣofin to n ṣoju ariwa Doncaster, Edward Miliband sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to banilọkan jẹ to si ba awọn ẹbi ọkunrin to padanu ẹmi wọn naa kẹdun lori adanu naa.

Ileeṣẹ inaju Yorkshire Wildlife Park ninu atẹjade ti wọn fi lede sọ pe awọn eeyan ẹni padanu ẹmi rẹ kẹdun ti ileeṣẹ ọlọpaa si sọ pe awọn n ṣeranwọ pẹlu awọn oṣiṣẹ wọn.

Bakan naa ni wọn rọ awọn eeyan lati ye pin fidio naa kiri.

Orukọ paaki naa ti wọn sara aṣọ ti wọn kan mọ igi nla. Ododo meji wa lẹgbẹẹ rẹ

Ella Ford, ẹni ọdun mẹrinlelogun, lati Moreton, Wirral, to wa ninu ọgba naa pẹlu ọrẹkunrin rẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa waye ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

O ni oun ri ọkunrin naa to n rinlọ rinbọ ni ibi ti tiger naa maa n wa pẹlu gbohungbohun to gbe sori.

O ni ko pẹ pupọ si asiko naa ni oun ri ọkunrin to gun odi ti wọn fi pin ibi tawọn tiger naa ati eeyan maa n duro si meji.

O sọ pe oun ri obinrin kan to duro n ba ọkunrin naa sọrọ ko to di pe o bẹ sinu ọdọ awọn tiger naa, ti tiger ọhun si lugọ si aaye to wa.

Ford ni ko pe ni tiger han ọkunrin naa, to n si pariwo pe ki awọn eeyan ran oun lọwọ.

O fi kun pe o to eeyan mẹẹdogun si ogun to wa nibi isẹlẹ naa kawọn oṣiṣẹ ibẹ to ni ki gbogbo eeyan kuro.

O ṣalaye pe niṣe ni gbogbo awọn to wa nibẹ kan n ro o pe ki lo ṣẹlẹ ati pe oun gbagbọ pe ọkunrin naa fẹ dẹruba tiger ọhun ṣugbọn to yiwọ mọ ọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Ohun ti a mọ nipa tiger to pa ọkunrin kan ni Yorkshire Wildlife Park
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Karmelle Pelham, ẹni ọdun mọkandinlogoji, lati Worksop ṣe inaju isinmi opin ọsẹ jade pẹlu awọn ẹbi rẹ ni ọgba awọn ẹranko naa kawọn oṣiṣẹ paaki naa to sọ fun wọn pe wọn n ko gbogbo awọn eeyan to wa nibẹ jade.

O sọ pe oun gbọ ohun to jọ iro ibọn tawọn oṣiṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri si wa kaakiri gbogbo inu ọgba naa.

Pelham fi kun pe wọn da apo nla bo ibi ti tiger naa n gbe, to si kan saara sawọn oṣiṣẹ ọgba naa fun bi wọn ṣe ṣamojuto iṣẹlẹ ọhun.

Lee Pitcher, aṣofin to n ṣoju ila oorun Doncaster ati Isle of Axholme dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri fun bi wọn ṣe tete mojuto iṣẹlẹ naa.

O ni gbogbo awọn ti iṣẹlẹ ni ipa lori wọn ni awọn ba kẹdun.

Ni ọdun 2009 ni wọn ṣi Yorkshire Wildlife Park, ti wọn si ṣi ibi ti tiger naa w ani ọdun 2011.

Ilẹ eeka meji ti wọn si fun awọn tiger naa ni awọn tiger ti Amur, ẹya tiger to buru, ti iye to ku ninu aginju naa si to ẹẹdẹgbẹta.

Awọn aworan to wa lori ayelujara paaki naa ṣafihan ibi ti awọn alejo to ba ṣabẹwo sibẹ le ti maa rin, eyi ti wọn fi mọ odi yika lati fi pa aala si ibi tawọn tiger naa ti n rin kaakiri.

Afikun iroyin latọwọ James Kelly

Get in touch

Did you witness the incident or do you have information that could help our reporting?