Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ egbòogi olóró n'Ibadan, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Afurasi naa ree pẹlu obitibiti egboogi oloro ti wọn gba lọwọ rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi kan ti ko niṣẹ meji ju tita egboogi oloro lọ fawọn eeyan.

Atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ayanlade Olayinka fi sita laipẹ yii lo fidi rẹ mulẹ.

Olayinka jẹ ko di mimọ pe agbegbe Apata to wa niluu Ibadan ni ọwọ ti tẹ afurasi ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa ni nnkan bi agogo mẹjọ aarọ ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan, ọdun 2026.

Báwo ni ọwọ́ ṣe tẹ afurasí ọ̀hún?

Nigba to n ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa bi ọwọ ṣe tẹ afurasi naa to pe orukọ rẹ ni Ridwan, agbẹnusọ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe awọ kan lo ta ileeṣẹ wọn lolobo, ko to di pe wọn sare lọ koju rẹ.

O ni bọwọ ṣe tẹ Ridwan ko ṣẹyin igbiyanju igbesẹ lati gbogun ti gbogbo oniruuru iwa ọdaran

Olayinka ṣalaye pe ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Iyaganku lo sare lọ sibẹ lati rọwọ to Rilwan.

Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe gbara tọwọ ti tẹ afurasi naa, lo ti n jẹwọ, to si n bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni.

O ni awọn nnkan bii ewe gbigbe ti igbagbọ wa wi pe o jẹ egboogi oloro 'Indian Hemp', ati eyi to funfun to pe ni 'methamphetamine', to fi mọ awọn egboogi oloro miran ni wọn gba lọwọ rẹ loju ẹsẹ.

Ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe afurasi naa ti wa ni ahaamọ awọn, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo fun iṣẹ iwadii to n tẹ siwaju lori rẹ, nipa oniruuru iwa ọdaran to ti tọwọ rẹ waye.

Iyẹn nikan tun kọ, Olayinka jẹ ko di mimọ pe awọn yoo tun tọpinpin nipa gbogbo awọn ti wọn jọ n lọwọ ninu iwa ọdaran kaakiri ipinlẹ Oyo ati agbegbe rẹ.

Bẹẹ lo sọ pe ọga awọn, Abimbola Ayodeji Olugbenga, ti fidi rẹ mulẹ afurasi naa yoo foju bai le-ẹjọ lati gba idajọ to tọ si i, nigba ti iṣẹ iwadii ba tubọ pari.

Olugbenga wa fi ọkan awọn araalu balẹ wi pe awọn ko nii kawọ gbera lati maa gbogun ti oniruuru iwa ọdaran kaakiri ipinlẹ naa, nitori pe eto aabo ẹmi ati dukia araalu lo jẹ wọn logun.

Bẹẹ lo ni awọn ko ni faaye gba gbigbe, tita ati rira egboogi oloro kaakiri ipinlẹ Oyo ati agbegbe rẹ.