Ọmọ ọdún méjìlélógún ṣàlàyé bó ṣe jí ara rẹ̀ gbé, tó sì ń bèèrè N25m owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Boko Haram
Ijinigbe gba owo ti di tọrọ fọnkale lorilẹede Naijiria bayii, to bẹẹ ti awọn eeyan kan n purọ rẹ mọra won lai jẹ pe ẹnikẹni ji wọn gbe, wọn n ṣe bẹẹ lati fi gbowo lọwọ awọn eeyan wọn ni.
Ọkunrin ọmọ ipinlẹ Edo kan to n gbe nipinlẹ Delta, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Micheal James, ẹni ọdun mejilelogun lo ti jẹwọ bayii lẹyin ti irọ ijinigbe to pa mọ ara rẹ tu.
James, ninu fidio kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Delta, Bright Edafe fi sita lọjọ Aiku, ṣalaye pe oun mọ-ọn-mọ wọgbo lọ, oun si pe iya oun lori aago pe wọn ti ji oun gbe.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ rẹ ninu fidio naa, James ṣalaye pe oun jẹ ẹgbọn oun ọkunrin ati eyi to jẹ obinrin lowo, oun ko si ri owo naa san fun wọn.
O ni ọna toun yoo gba ri owo naa ti ko si lo mu oun dọgbọn ijiraẹni gbe.
''Lọjọ kin-in-ni oṣu Keje, mo ji ara mi gbe. Wọn ran mi pe ki n lọ da idọti nu. Lẹyin ti mo da ilẹ naa nu tan, mo gbe kẹkẹ ọmọlanke mi sibi kan mo si wọgbo lọ.
"Lẹyin igba diẹ, mama mi bẹrẹ si i pe mi lori aago ṣugbọn mi o gbe ipe naa.
"Nigba to ya, mo pe iya mi pada, mo si sọ fun un pe wọn ti ji mi gbe, ati pe awọn ajinigbe naa n beere miliọnu mẹẹẹdọgbọn (N25m)."
James tẹsiwaju pe oun tun pe iya oun pada lẹyin igba naa, oun sọ fun un pe awọn ajinigbe ti n lu oun, oun si ti ṣe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira (N700,000) ranṣẹ sawọn toun wa lakata wọn naa.
Iya James gbọrọ naa o si sọ fun ọmọ rẹ pe oun ti fi ohun to ṣẹlẹ to ọlọpaa atawọn fijilante leti, wọn si ti bẹrẹ igbesẹ lati gba a silẹ.
Eyi lo mu idaamu ọkan ba ọkunrin to ji ara rẹ gbe naa, to si n ro o pe awo ti fẹ ya.
''Nigba ti ojo fẹ rọ ninu igbo ti mo wa ni mo sa jade lọ sibomi-in, mo tun parọ pe mo ti sa mọ ajinigbe lọwọ"
Gẹgẹ bi Micheal James ṣe tẹsiwaju ninu alaye ijiraẹni gbe naa, o ni :
"Nigba tojo fẹ rọ ninu igbo ti mo wa lọjọ yẹn ni mo kuro nibẹ.
"Mo gun ọkada lọ sibomi-in ki n to tun pe awọn ẹbi mi pe mo ti sa mawọn ajinigbe naa lọwọ o."
''Imọ ẹrọ ni ọlọpaa fi dọdẹ rẹ ti a si mu un"
Nipa bi James ṣe bọ sọwọ ọlọpaa ninu arinkiri rẹ, Bright Edafe to jẹ Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Delta, ṣalaye pe itọpinpin nipa imọ ẹrọ ni awọn fi mu un.
Edafe ṣalaye pe imọ ẹrọ naa ni awọn fi dọdẹ ibi ti James to ji ara rẹ gbe wa, ti ọwọ si ba a ṣinkun.
"A gba ipe pe wọn ji i gbe, ileeṣẹ ọlọpaa si lo imọ ẹrọ lati tọpinpin ibi to ni wọn ji oun gbe pamọ si.
"Afi bi afurasi naa ṣe sare jade to si ni wọn ji oun gbe ni. O pada jẹwọ pe oun loun ji ara oun gbe, koun le gba N25m lọwọ awọn ẹbi oun."
Bẹẹ ni Alukoro ọlọpaa Delta ṣalaye.
Iwadii ti n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii bi ọlọpaa ṣe wi, bẹẹ ni James, ẹni ọdun mejilelogun ko ni i ṣai foju ba kootu bi wọn ṣe sọ.
Ọlọpaa kilọ fun araalu lati ma ṣe fi ijinigbe tabi iwa ọdaran kankan ṣere, nitori iwa to lodi labẹ ofin ni.



























