Ṣé lóòótọ́ ni pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ dá 'sọbsidi' padà ló ṣe mú ẹ̀dínwó bá owó epo bẹntiróòlù NNPCL fún oṣù kan? Àlàyé rèé

Bola Tinubu wọ agbada olomi buluu pẹlu fila
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ṣé lóòótọ́ ni pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ dá 'sọbsidi' padà ló ṣe mú ẹ̀dínwó bá owó epo bẹntiróòlù NNPCL fún ọgbọ̀n ọjọ́? Àlàyé rèé

Lanaa Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni ijọba apapọ kede ẹdinwo (Discount) owo iye epo ti ileeṣẹ NNPCL ba n ta fun ọgbọn ọjọ.

Minisita fun eto iṣuna ati abojuto ọrọ aje, Taiwo Oyedele, lo kede ẹdinwo owo epo naa nibi ipade awọn akọroyin kan l'Abuja.

Amọ latigba ti ikede naa ti waye ni ọpọ eeyan ti n beere pe ki ni ẹdinwo naa ba de gan-an?

Araalu n beere iye ẹdinwo naa, ati pe ṣe ijọba Tinubu fẹẹ da owo iranwọ (Fuel subsidy) to yọ kuro ni 2023 pada ni.

Alaye ijọba apapọ

Nigba to n yannana ẹdinwo ta a mọ si discount naa, Minisita fun iṣuna sọ pe awọn awakọ ero ni ẹdinwo naa wa fun ju kaakiri Naijiria.

Oyedele ṣalaye pe ẹdinwo yii ko tumọ si pe ijọba apapọ ti pada si aye sọbsidy, bi ko ṣe pe wọn kan fẹẹ ta epo naa niye ti wọn ra a lai jere kankan ni.

Eyi yoo wa bẹẹ laaarin ọgbọn ọjọ gẹgẹ bi Minisita ṣe sọ.

"A n ṣe ẹdinwo lori bẹntiroolu ti NNPCL ba ta ni asiko yii si ọgbọn ọjọ, pẹlu awọn awakọ igboro ti a ni lọkan ju kaakiri Naijiria.

"Fun idi eyi, ki i ṣe sọbsidi, ijọba kan n sọ pe ẹ jẹ ka ta a niye ti a ra a ni."

Idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii bi Oyedele ṣe ṣalaye, ni lati mu idẹrun ba araalu lori iye ti wọn n ra epo, paapaa fun awọn awakọ ero, ki ero to n wọkọ lẹ tun ri idẹrun si i.

Atẹ epo bẹntiroolu pẹlu awọn ẹrọ POS meji labẹ rẹ. Awọn aṣọ inuju meji wa nibẹ pẹlu, bẹẹ ni awọn ike epo kan wa loke atẹ naa.

Ṣe ₦1,350 ni jala epo kan yoo jẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju alaye naa, Oyedele sọ pe ki i ṣe pe jala epo kan yoo jẹ ₦1,350 kaakiri awọn ile epo, bi ko ṣe pe o jẹ afojusun ijọba apapọ lati ri i pe bi iye owo epo ba yi lọja agbaye, ko ni I maa nipa inira lori iye owo epo nibi.

Wọn fi kun un pe ₦1,350 yii jẹ afojusun iye ti awọn alagbata epo yoo le ta a fawọn ti yoo tun un ta a .

O wa fun lati jẹ ki iye jala duro ni iye kan ná, dipo ti yoo maa foni lọ soke, ja walẹ lọla.

"Ohun to wa nibẹ ree: Bi epo ba jẹ ₦1,400 fun jala kan lonii, to jẹ ₦1,400 lọla, o daa ju ko jẹ ₦1,500 lonii, ₦1,300 lọla lọ."

Oyedele lo ṣalaye bẹẹ.

O ni idi eyi ni pe lilọ bibọ owo epo ki i jẹ ki eeyan mọ bi yoo ṣe pada duro, bi epo ba si gbowo leri kia, ki i ṣe bẹẹ tete pada walẹ.

Ohun miran ni pe wọn yoo maa ṣe agbeyẹwo iye owo yii loṣoosu, ki i ṣe pe yoo taku si ₦1,350 ti ijọba n fojusun yii lai yi rara.

Gẹgẹ bi Oyedele ṣe wi, ijọba yoo maa gbe ohun to ba yẹ lati mọ fun araalu jade nipa rẹ, ko le baa kun fun akoyawọ ati otitọ.

Ki lo de ti ijọba fi n gbe awọn igbesẹ yii?

Idahun Oyedele si eyi ni pe ijọba n gbe afikun igbesẹ ti yoo mu idẹkun ba araalu, nitori awọn eto to wa nilẹ ko ti i fi gbogbo ara yanju iṣoro ti idile kọọkan n koju latigba ti afikun ti ba owo epo ati owo ọkọ wiwọ

Awọn igbesẹ idẹrun mi-in to tun ni yoo wa ni:

Fifi opin si awọn owo ti ko tọ tawọn kan n gba lọwọ awọn awakọ, eyi to n mu owo mọto wiwọ wọn gogo.

O ni ijọba apapọ yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ijọba ipinlẹ kọọkan lati ri si eyi.

Bakan naa ni lo ijọba apapọ yoo fowo ranṣẹ sawọn idile ti ìṣẹ́ n ṣẹ́, bẹẹ ni wọn yoo ran awọn olokowo kereje lọwọ pẹlu.

Wọn yoo pese afẹfẹ gaasi fawọn ọkọ to n lo o (CNG), pẹlu ero pe araalu yoo jẹre ẹdinwo, owo ti wọn fi n wọ ọkọ yoo si dinku.

Awọn olokowo to ba kọ lati jẹ ki araalu jẹ anfaani ẹdinwo yii yoo foju wina ofin bi ijọba ṣe wi.

Owo ti wọn ba ri lati ara awọn to lufin yoo tun maa wa fun iranlọwọ igbokegbodo ọkọ ni alaye ti ijọba Naijiria sẹ.

Amọ ọpọ araalu ni igbesẹ yii n ru loju, ohun ti wọn si n sọ lori ayelujara ni pe ète oṣelu ni ijọba Aarẹ Bola Tinubu n pa.

Ero awọn mi-in lori ayelujara ni pe ọgbọn ati fa oju araalu mọra ṣaaju idibo 2027 ni eto yii jẹ.

Wọn ni ko sẹni ti ki mọ pe oore ti ijọba n ṣe yii ki i ṣe lasan, oore ti a ṣe fun adiẹ ko gbe ni, bo pẹ titi, a ṣe omitoro ata si ni lẹnu.

Amọ ijọba apapọ ti ni ko si kinni kan lẹyin anfaani toun gbe de yii, bi ko ṣe lati mu idẹrun ba awọn ọmọ Naijiria nikan.

Kókó tó yẹ kí o mọ̀ nípa àdínkù owó epo bẹntiróòlù fún oṣù kan tíjọba kéde

Ijọba apapọ ti sọ pe ikede adinku owo epo bẹntiroolu fun oṣu kan lawọn ile epo NNPCL ko tumọ si pe ijọba ti da owo iranwọ ori epo ti wọn n pe ni ''subsidy'' pada.

L'Ọjọbọ ọjọ kẹjọ oṣu Kẹwaa yii ni minisita eto inawo, Taiwo Oyedele, kede igbesẹ yii atawọn igbesẹ mii lati mu adinku ba inira araalu latari epo bẹntiroolu to gbowo lori.

Minisita eto inawo sọ pe igbesẹ ijọba yii yoo ṣe iranwọ fawọn ọmọ Naijiria pẹlu ipenija ti wọn n koju lasiko yii ti owo epo n lọ soke lọja agbaye.

Wọnyii ni koko to yẹ ki o mọ nipa adinku owo epo bẹntiroolu fun oṣu kan ti ijọba apapọ kede.

Adinku owo epo bẹntiroolu fun oṣu kan

Minisita eto inawo kede wi pe awọn ọmọ Naijiria yoo maa ri epo bẹntiroolu ra ni ẹdinwo lawọn ile epo ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPCL kaakiri orilẹede Naijiria.

Oyedele ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe eyi ko tumọ si pe ijọba ti da iranwọ owo ori epo ti wọn yọ kuro lọdun 2023 pada.

Minisita eto inawo sọ pe awọn awakọ ero ni ijọba fẹ ki wọn jẹ anfaani eto yii julọ.

Ijọba fẹ gbe owo epo bẹntiroolu si N1,350

Minisita eto inawo tun ṣalaye wi pe ijọba n jiroro lọwọ pẹlu awọn tọrọ kan lati gbe owo bẹntiroolu si N1,350, ti ko si gbọdọ ju iye yii lọ lai fi nnkan to n ṣẹlẹ lọja epo agbaye ṣe.

Eyi ko tumọ si pe N1,350 lawọn ọmọ Naijiria yoo maa ra lita kan bẹntiroolu lawọn ile epo ni Naijiria.

Ohun ti ijọba fẹ ṣe ni pe ohun epo bẹntiroolu ko ni lọ soke ju N1,350 lọ ti owo ep oba tiẹ lọ sọke lọja epo lagbaaye.

Oyedele sọ pe ''kii ṣe gbogbo igba ti owo epo ba ti lọ soke lọja agbaye lo yẹ ki epo bẹntiroolu maa gbowo lori ni Naijiria.''

Ijọba yoo maa ṣagbeyẹwo owo epo losooṣu

Ọgbẹni Oyedele sọ pe loṣooṣu ni ijọba apapọ yoo maa ṣagbeyẹwo owo epo bẹntiroolu, ijọba yoo si maa kede igbesẹ rẹ fun araalu.

Eyi to tun dabi rẹ ni pe awọn alagbata epo yoo maa faragba a ti owo epo ba lọ soke, amọ, Oyedele ni wọn yoo ri owo wọn pada ti owo epo ba tun ti lọọlẹ lọja agbaye.

Minisita ni igbesẹ yii ko ni ma jẹ ki owo epo bẹntiroolu kan maa ja lọ soke lojiji bi o ti n ṣẹlẹ bayii.

Ijọba fẹ mu adinku ba bowo epo bẹntiroolu ṣe n lọ soke loorekoore

Oyedele sọ pe ijọba n kọminu lori bi owo epo bẹntiroolu ṣe n lọ soke loorekoore, o fidi rẹ mulẹ pe kii ṣe wi pe ijọba fẹ gbe owo epo bẹntiroolu si iye kan fawọn eeyan lati maa ra.

Minisita ni nnkan ti ijọba fẹ ṣe ni pe awọn araalu yoo lanfaani lati maa wọ ọkọ pẹlu ẹdinwo.

''Nnkan ti ijọba fẹ ṣe ni pe fun apẹẹrẹ, o san ki awọn eeyan ra lita epo bẹntiroolu kan ni N1,400 loni ati lọjọ keji ju ki wọn ra a ni N1,500 lonii ko wa di N1,300 lọla.

Eleyii lo n ṣakoba fawọn araalu tori bi owo epo ṣe n lọ soke loorekoore, kii si i tete walẹ to ba ti lọ soke,'' Oyedele ṣalaye.

Ẹdinwo epo rọbi fawọn ileeṣẹ ifọpo ni Naijiria

Ijọba apapọ tun n gbero lati maa ta epo rọbi fawọn ileeṣẹ ifọpo ni Naijiria pẹlu ẹdinwo.

Eyi ko ni jẹ ki bi owo epo ṣe n lọ soke loorekoore lọja agbaye ni ipa to buru lori awọn ileeṣẹ ifọpo to wa ni Naijiria.

Ijọba gbagbọ wi pe eyi yoo ṣeranwọ fawọn ileeṣẹ ifọpo rọbi ni Naijiria pẹlu okowo wọn.

Adinku owo ọkọ

Yatọ si adinku owo epo bẹntiroolu, ijọba tun kede pe oun yoo ba lẹgbẹlẹgbẹ ati lajọlajọ sọrọ lati dẹkun oniruuru owo ti wọn maa n gba lọwọ awọn awakọ ero ki owo ọkọ le walẹ.

Ijọba tun sọ pe oun yoo mu adinku ba iye tawọn awakọ to n lo gaasi CNG n ra gaasi kawọn naa le mu adinku ba iye owo ọkọ.

Oyedele sọ pe ijọba yoo fiya jẹ awọn alagbata gaasi ti wọn ba ta a ju iye to yẹ ki wọn maa ta a lọ.

Bakan naa tun ni ijọba yoo tun mu alekun ba owo iranwọ ti o n fawọn idile ti ko rọwọ họri ni Naijiria.

Ijọba tun maa mu adinku ba owo ori tawọn ọmọ Naijiria ti ko rọwọ họri n san.