Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àdínkù owó epo bẹntiróòlù tí ìjọba Nàìjíríà kéde
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Lanaa Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni ijọba apapọ kede ẹdinwo (Discount) owo iye epo ti ileeṣẹ NNPCL ba n ta fun ọgbọn ọjọ.
Minisita fun eto iṣuna ati abojuto ọrọ aje, Taiwo Oyedele, lo kede ẹdinwo owo epo naa nibi ipade awọn akọroyin kan l'Abuja.
Amọ latigba ti ikede naa ti waye ni ọpọ eeyan ti n beere pe ki ni ẹdinwo naa ba de gan-an?
Araalu n beere iye ẹdinwo naa, ati pe ṣe ijọba Tinubu fẹẹ da owo iranwọ (Fuel subsidy) to yọ kuro ni 2023 pada ni.






















