Ajínigbé yìnbọn pa awakọ̀ wa, èèyàn mẹ́rin móríbọ́, méjìlá wà nìgbékùn-Àwọn tórí kó yọ níbi ìjínigbe ìpínlẹ̀ Niger ṣàlàyé
Lọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ti i ṣe ayajọ ọdun kẹrindinlaadọrin (66) ominira orilẹede Naijiria ni awọn eeyan kan ti wọn n bọ lati ipinlẹ Sokoto, ti wọn si n lọ si ipinlẹ Oyo, bọ sọwọ agbebọn.
Yatọ si awọn agunbanirọ ogun to n lọ si ipinlẹ Imo ti wọn ji gbe lọjọ yii kan naa, awọn ti wọn n bọ lati Sokoto yii naa ko si ajinigbe lọwọ lagbegbe kan ti a mọ si Pelegi, Mokwa, nipinle Niger.
Iroyin to kọkọ jade nigba naa ni pe ọmọ ilu Igboho, nipinlẹ Oyo ni gbogbo awon ti won ji gbe naa, ati pe akẹkọọ ni wọn.
Iroyin naa sọ pe eeyan mejidinlogun to wa ninu odidi ọkọ kan ni awọn agbebọn naa kọlu ti wọn si gbe wọgbo lọ.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an
Lati fidi otitọ iṣẹlẹ yii mulẹ, BBC News Yoruba kan si lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si, amọ ti wọn ri ọna sa lọ mọ awọn ajinigbe agbebọn naa lọwọ.
Yekini Suraju,toun naa jẹ awakọ, ṣalaye pe:
"Mọto wa n bọ lati Sokoto, igba ti a de apa kan Mokwa, nibi ti wọn n pe ni Pelegi, awọn bandiiti jade si wa.
"Awa tiẹ ro pe ọmọde ni awọn ta a n wo lọọkan nibi odo ti wọn wa ni, tori ẹ ni dẹrẹba ọkọ wa ṣe din bo ṣe n sare ku.
" Bi a se debi odo naa ni awọn kan jade si wa, won gbe ibọn AK 47 dani, awọn mi-in gbe ada dani, wọn bẹrẹ si I yinbọn si wa, ṣa wa ladaa."
Ọkunrin yii tẹsiwaju pe ibọn ba awakọ to n wa awọn, dẹrẹba naa si jade laye.
O ni awọn wa ọna lati sa mọ wọn lọwọ, nitori awọn ajinigbe naa bẹrẹ si I ba ara wọn ja nigba ti ibọn ba awakọ, wọn n binu si ẹni to yinbọn mọ ọn pe ko yẹ ko pa a.
O ni nibi ti won ti n ṣe eyi, oun pẹlu ti ibọn ti ba, wa ọna lati sa lọ.
Ẹlomiran ninu iṣẹlẹ naa ti ibọn tun ba, Ismaila Gazali , ṣalaye pe awọn meji ni wọn jẹ ọmọ ilu Igboho, awọn ọmọ ilu miran naa wa ninu ọkọ oun pẹlu.
O fi kun un pe awọn mẹrin lawọn rọna sa lọ, ẹnikan ku, nigba ti awon mejila wa nigbekun awọn ajinigbe naa.
"50m ni wọn n beere fun itusilẹ wọn"
Ni itẹsiwaju alaye yii, obi kan ti awọn ọmọ rẹ meji wa ninu ọkọ naa, Alagba Sunday Ademola, ṣalaye pe aadọta miliọnu naira ti i ṣe 50m ni awọn ajinigbe naa n beere fun, ki wọn too le fi ọmọ oun kan to wa lakata wọn silẹ.
O fi kun un pe foonu ọmọ naa ni wọn fi n pe oun, bẹẹ ni awọn to wa nigbekun ṣi to mejila. Awọn mẹrin lo ni wọn raye sa lọ.
Ọmọ kan ṣoṣo lo ri ọna sa mọ wọn lọwọ ninu awọn ọmọ rẹ meji to wa ninu ọkọ naa bo ṣe sọ.
Ninu ọrọ aṣoju Baale ilu Igbope ti ko jinna si Igboho, Odebunmi Saheed, o rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Oyo lati dide si ọrọ yii, kawọn to wa nigbekun le gba itusilẹ.
Bakan naa awọn eeyan ti ọmọ wọn wa nigbekun n bẹbẹ pẹlu, wọn rọ ijọba lati ji giri si eto aabo to mẹhẹ lorilẹede yii.

























