Wo ìlú márùn-ún tí ètò ìsìnkú Ayatollah Khamenei, olórí Iran tí US pa yóò ti wáyé fún ọjọ́ mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ orilẹede Iran ti bẹrẹ ipalẹmọ eto isinku olori ẹsin tẹlẹ niluu naa, Ayatollah Ali Khamenei, ẹni to ku latari ikọlu orilẹede America ati Israel loṣu Keji ọdun 2026 yii.
Gẹgẹ bi wọn ṣe kede, o kere tan, isinku naa yoo gba wọn to ọjọ mẹfa.
Wọn fi kun un pe aabo to nipọn lawọn ti pese kalẹ .
Tẹ o ba gbagbe, ikọlu ti America ati orilẹede Israel ṣe si ile Oloogbe Ayatollah Khamenei ati ẹbi rẹ lo pa olori ẹsin naa loṣu Keji ọdun yii.
Ki lo de ti wọn ko sinku Ayatollah Khamenei lati oṣu Keji to ti ku?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ eeyan lo n jọ loju, pe bi Ayatollah Khamenei ṣe jẹ Musulumi ati aṣaaju ẹsin Islam ni Iran to, wọn ko sinku rẹ lati igba to ti ku lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji ọdun 2026.
Amọ awọn alaṣẹ to yẹ ko ri si eto isinku naa ko le ṣe bẹẹ latari ogun to n lọ lọwọ laaarin Iran, America ati Israel.
Eyi lo fa a ti wọn fi sun isinku naa siwaju titi di asiko yii.
Ṣugbọn ni bayii ti wọn ti fẹnuko lati jẹ ki ogun o sinmi, eyi ti ko ti i fi gbogbo ara han boya ogun ọhun yoo pari loootọ, awọn alaṣẹ Iran ti ṣeto bi wọn yoo ṣe sin olori wọn naa lọna manigbagbe.
Ọjọ kerin oṣu Keje ni eto isinku naa yoo bẹrẹ ni Tehran, wọn yoo si pari rẹ lọjọ kẹsan-an ni Mashhad.
Nibo ni wọn yoo ti ṣeto isinku naa?
Awọn alaṣẹ orilẹede Iran ti ṣeto pe isinku Ayatollah yoo bẹrẹ lọjọ Satide kaakiri ilu marun-un ni Iran ati Iraq.
Awọn ilu ti wọn kede pe eto isinku naa yoo ti waye ni.
- Tehran:
Olu ilu Iran ti i ṣe Tehran, to tun jẹ ibudo agbara ijọba ilu naa ni eto isinku Ayatollah yoo ti gbera sọ.
Iroyin sọ pe moṣalaṣi Jimọ ilu naa ni wọn yoo ti bẹrẹ, nibi ti awọn eeyan yoo ti waa dagbere fun oku Ayatollah.
- Qom:
Lẹyin ayẹyẹ idagbere ni Tehran, wọn yoo gbe oku lọ si ilu Qom, nibi to jẹ ibudo akojọpọ agbaye fawọn ijọ Shiite.
Ilu Qom yii ni iboji ti wọn maa n sin awọn Shiite si ju lagbaaye.
Lara awọn ibi ti wọn yoo ti ṣeto naa ni mọṣalaṣi Jamkaran to wa ni ẹyin ilu, to si jẹ ọkan pataki lara ibi tawọn ọmọ ijọ Shiite ki i fi ṣere.
- Mashhad:
Ilu Mashhad ni wọn yoo ti pari eto, nibi ti wọn yoo sin oku Ayatollah Ali Khamenie si gan-an.
Ilu Mashhad yii ni wọn ti bi Ayatollah Khamenei.
- Najaf ati Karbala ni Iraq:
Awọn ilu meji ti a mọ si Najaf ati Karbala lorilẹede Iraq wa lara ilu ti wọn yoo gbe eto de fun Oloobe Ayotallah.
Lara eto ti wọn yoo ṣe nibẹ ni ikojọpọ awon Shia lati daro ẹni wọn to lọ.
Wọn yoo tun gbe oku naa lọ sawọn ilu yii kawọn Shia to wa nibẹ le ki I pe o digba kan na.
Ijọba ṣabẹwo sawọn agbegbe yii ṣaaju
Gbogbo awon aaye ti eto isinku naa yoo ti waye ni ijọba Iran ti kọkọ ṣabewo si, lati ri I pe ohun gbogbo wa leto.
Ikọ kan ni won ran lọ sawọn aaye naa lati moju to eyi.
Bakan naa ni Igbakeji Aarẹ, Mohammad Reza Aref, to jẹ alakooso igbimọ isinku, ti fi ọpọlọpọ oṣu ri si bi isinku naa yoo ṣe kẹsẹjari.
Minisita to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Iran, Abbas Araghchi, toun naa jẹ ọkan lara awọn igbimọ yii, ṣabẹwo sawọn ilu naa, nibi to ti ba awọn gomina ibẹ sọrọ.
Bi awọn alaṣẹ Iran ṣe wi, eeyan to to miliọnu mẹjọ ni wọn n reti nibi isinku naa lati ilu marun-un.
Bẹẹ si ni won ni awọn eeyan yoo wa lati ẹkun mọkanlelọgbọn (31) ti Iran pin si, lati ki olori ẹsin tẹlẹ naa pe o digba, o ṣe.
Wọn yoo sọ awọn títì gboogi ni Iran di aaye igbọkọsi, awọn mọṣalaṣi, ile ẹkọ, papa iṣere atawọn ọgba yunifasiti yoo di ibi tawọn eeyan yoo maa sun si lasiko isinku naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ alaabo Basij to n lewaju isinku naa, ṣalaye pe awọn atunto kan yoo waye lawọn ilu ti isinku ti fẹ waye.
Ikọ naa sọ pe awọn yoo sọ awọn títì gboogi ni Iran di aaye igbọkọsi, nigba ti awọn mọṣalaṣi, ile ẹkọ, papa iṣere atawọn ọgba yunifasiti yoo di ibi tawọn eeyan yoo maa sun si lasiko isinku naa.
Ko ni I si lilọ bibọ ọkọ ofurufu, bẹẹ ni iwọle ati ijade sawọn ilu naa yoo ni abojuto.
Ikọ Revolutionary Guard Corps, IRGC, ni yoo bojuto aabo lasiko isinku naa bi wọn ṣe sọ.
Awọn eeyan nla wo ni yoo wa nibi eto isinku naa?
Ko ti I foju han boya olori ẹsin tuntun ni Iran, Mojtaba Khamenei; ẹni ti ko ti I yọju sigboro aye latigba ti won ti yan an sipo yoo wa sibi isinku naa.
Awọn ẹka iroyin America kan sọ pe Mojtaba Khamenei farapa gan-an nibi ikọlu to pa baba rẹ, Ayatollah.
Wọn ni ọṣẹ́ naa pọ to bẹẹ to jẹ o nilo awọn iṣẹ abẹ kan.
Amọ awọn alaṣẹ Iran ko fidi eyi mulẹ.
Aarẹ ilẹ Pakistan; Asif Ali Zardari ati Olootu rẹ; Shehbaz Sharif, sọ pe awọn yoo ran aṣoju lọ sibi isinku Ayatollah.
Awọn aṣoju lati ọdọ ijọba Taliban ti bẹrẹ si I kora jọ ni Tehran ni tiwọn fun isinku yii.
Bakan naa ni òye ko ti I foju han boya awọn olori lati Russia ati China, ti wọn jẹ alabaaṣẹ Iran yoo wa.



























