Mi ò kìí ṣe olè, àkóbá òṣèlú ni wọ́n ṣe fún mi - Surii Ilupeju

Oríṣun àwòrán, InsideOyo
Surajudeen Babatunde Adio ti ọpọ mọ si Surii Ilupeju ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fi ẹsun idigunjale kan ti jade sọrọ, to si sọ tirẹ nipa ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan an ọhun.
Surii Ilupeju ninu fidio kan to wa lori Facebook ni ọrọ oṣelu ni nnkan to ṣẹlẹ si oun ati pe wọn kan mọọmọ parọ mọ oun nitori gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun naa kii ṣe ootọ.
Ninu fidio naa ni Surii ti n sunkun to si n sọrọ nipa ohun to mọ nipa iṣẹlẹ naa.
Ẹ o ranti pe bii ọsẹ mẹta sẹyin ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe afurasi adigunjale ni Surii Ilupeju ati pe ọpọ awọn ohun ija oloro bii ibọn atawọn nnkan mii ni awọn ba ninu ile rẹ nigba ti awọn ṣabẹwo sibẹ.
Amọ Surii sọ pe gbogbo nnkan tawọn ọlọpaa sọ pe awọn ba ninu ile oun kii ṣe ti toun, pe wọn ko awọn nnkan naa wa sile oun ni.
O sọ pe ọrọ oṣelu pọnbele ni iṣẹlẹ naa to si ṣalaye bi gbogbo iṣẹlẹ naa ṣe lọ.
O ṣalaye pe lati ọdun 2015 ni awọn ti n tẹle Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti awọn si tẹle ṣe ipolongo ṣugbọn ti ko wọle ibo lasiko naa.
O ni awọn tun tẹle Makinde lati polongo ibo ni ọdun 2019 to si wọle ibo, to si jẹ pe bẹẹ lawọn tun ṣe lọdun 2023.
Surii tẹsiwaju pe lẹyin ti Gomina Makinde wọle saa keji lọdun 2023 lo pe ọga awọn to jẹ Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si Auxillary pe iṣẹ ti yatọ, pe awọn tikẹẹti wa to oun fẹ fi kun eyi ti awọn n ja tẹlẹ.
"Nitori ọga mi kọ lati maa ja alekun tikẹẹti ni wọn ṣe ṣakoba fun-un"
"Tikẹẹti ẹyọkan ni a n ja tẹlẹ fun ọkọ kan amọ wọn wa ko tikẹẹti yii de o n lọ bii mẹẹdogun. Ọga ni bawo ni awọn ṣe fẹ ta a fun awọn eeyan ti ko ni di isọlẹnu, ki wọn jẹ ki a maa ṣe e bi a ṣe n ṣe e tẹlẹ ti ara fi dẹ awon eeyan.
O fi kun pe lẹyin ti awọn kuro nibi ipade naa ni wọn sọ fun ọga oun pe ko lọ kọwe fipo rẹ silẹ ati pe ko faramọ oun ti oju rẹ ba ri ti ko ba ṣe bẹẹ.
O ni ọjọ ti wọn burawọle fun Makinde fun saa keji lo ko awọn ẹṣọ aabo lati lọ da hotẹẹli ọga awọn ru, ti wọn si gba akoso garaji lọwọ rẹ, gbe fun ẹni to jẹ akọwe rẹ tẹlẹ.
O woye pe gbogbo awọn to n tẹle Auxillary ni wọn ba ẹni tuntun naa lọ amọ oun kọ lati fi ọga oun silẹ, ti oun si duro ti ọga oun ati pe lati igba naa ni oun ko ti ba Makinde ṣiṣẹ mọ.
Surii ni lati igba ti Oriyomi Hamzat ti kede erongba rẹ lati dije dupo gomina ipinlẹ Oyo ni oun ti daran, ti wọn si ranṣẹ si oun pe ṣe Oriyomi lo yẹ ki oun maa tẹle.
"Wọn ranṣẹ wa pe ti mo ba kọ, ti mo ba ni ẹni ti maa tẹle niyẹn, oun ti oju mi ba ri ki n faramọ o, pe ṣe mi o ri bi wọn ṣe ṣe fun ọga ni.
"Mi o ka a si nigba ti wọn wa ni ẹlẹẹkeji pe wọn maa foju mi ri mabo. Mo bẹrẹ si ni gbọ oriṣiriṣi bii ki wọn ni ki DSS maa wa mi kiri, mo ṣa n baa lọ."
"Mi o kii n ṣe ole, wọn fẹ ṣakoba oṣelu fun mi ni"
O ni ọjọ Kọkanla, oṣu Kẹfa ni ọrọ naa gba ibomiran yọ bi wọn ṣe pe oun lati ile pe awọn ọlọpaa ti wa nile oun, pe wọn n wa gbogbo inu ile.
"Awọn ọmọ to n bami ṣiṣẹ sọ pe nigba ti wọn wa gbogbo inu ile ti wọn ko ri nnkankan wọn ko gbogbo awọn jade, wọn ni kawọn doju bolẹ.
"Lẹyin bii ọgbọn iṣẹju, wọn ni kawọn gboju soke, kawọn wo ohun tan ba nile awọn, emi o ni nnkankan ninu ile, gbogbo aye lo mọ pe iṣẹ mọto ni mo n ṣe lati ilẹ.
"Awọn ọmọ yẹn sọ pe inu ile awọn kọ ni ẹ ti ri awọn eleyii o, awọn kọ ni awọn ni gbogbo ohun tẹ ko kalẹ yii o.
"Wọn ko gbogbo awọn ọmọ yẹn, awọn ọmọṣẹ mi mẹrin, akọbi ọmọ wa lara awọn ti wọn ko lọ."
Surii tẹsiwaju pe wọn pada wa sile oun ni owurọ ọjọ keji ti wọn si bẹrẹ si ni ko gbogbo nnkan ti oun ni ninu ile.
"Gbogbo awọn mọto ti mo fi n ṣiṣẹ, wọn ko gbogbo rẹ lọ, to fi mọ gbogbo aga, ibusun, wọn o ṣẹ ohunkohun ku fun mi, gbogbo ohun ti mo ni patapata ni wọn ko lọ."
O ni iyalẹnu lo jẹ fun oun pe nigba to maa fi di ọjọ kẹta si mẹrin ni wọn mu ọkọ katakata ti wọn fi wo ile oun.
O fi ẹdun ọkan sọrọ pe oun kii ṣe ole, pe gbogbo ohun ti wọn ni wọn ba nile oun kii ṣe toun, pe wọn ko gbogbo rẹ wa sile oun ni.
"Wọn fi ṣe akoba oṣelu fun mi ni, ẹyin ọmọ Naijiria ẹ dakun ẹ gbami, ẹ ṣaanu mi, mi o ṣe nnkankan, mi o daran o, mi o mọ nnkan nipa rẹ."
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo kede pe oniruru ohun ija oloro, alupupu, ọkọ akero ati aṣọ ẹgbẹ oṣelu Accord loun ba lakata afurasi adigunjale, Surajudeen Babatunde Adio, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Surii Ilupeju".
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Ayanlade Olayinka lo fidi ọrọ ọhun mulẹ ninu atẹjade kan.
Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii ni ọlọpaa sọ pe oun mu Surii Ilupeju pẹlu afurasi mẹrin mii lori ẹsun idigunjale ati nini ohun ija oloro ni ikawọ wọn.
Ayanlade sọ pe asiko iwadii awọn lawọn ṣawari oniruuru ohun ija oloro ni akata afurasi ọhun.
Lara awon ohun ti wọn ni awọn ba nile rẹ niiIbọn Pump-Action kan, ibọn Single-Barrel kan, ibọn Single-Barrel Cut-to-Size kan, ibọn ilewọ ti wọn gbelẹrọ meji, ibọn ilewọ Double-Barrel ti wọn gbelẹrọ kan, Ọta ibọn mẹtalelogun, Ọta ibọn AK-47 mẹjọ.
Yatọ si awọn ibọn yii, ọlọpaa ni awọn tun ri awọn ọkọ atawọn alupupu nibẹ bii alupupu Suzuki Inazuma Power Bike kan, to fi mọ awọn alupupu Honda ti ko ṣiṣẹ.
Awọn nnkan mii ti wọn tun ri lakata rẹ gẹgẹ bii ọrọ ọlọpaa ni ọpọlọpọ aṣọ ati fila ipolongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu Accord.
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu ẹgbẹ oṣelu Accord yii ni Oriyomi Hamzat ti fẹ dije du ipo gomina ipinlẹ Oyo.
Amọ ṣa, Oriyomi ti sọ ni gbangba pe oun ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu afurasi adigunle naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ awọn to ni awọn dukia naa ati ibaṣẹpọ wọn pẹlu awọn adigunjale to wọn mu.

























