Kà nípa ọkùnrin tó ní ilé ọmọ bíi obìnrin

Dokita obinrin ati ọkunrin n ko irinṣẹ abẹ dani
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Labẹ ilana Iṣẹda eeyan, awọn abuda kan wa fun ọkunrin ti obinrin ki I ni. Bakan naa lo si jẹ pe awọn nnkan kan wa to wa lara obinrin ṣugbọn to jẹ eewọ lara ọkunrin.

Sugbọn sibẹ naa, nnkan maa n yipada lawọn igba mi-in, ti ohun ti ko ṣẹlẹ ri tabi ti ko wọpọ yoo deede waye.

Irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ni ti ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, ni Delhi, orilẹede India, ẹni to ni ile ọmọ (Uterus) bii obinrin).

Airọmọbi lẹyin ọdun meji to ti ṣegbeyawo lo mu ki ọkunrin naa lọọ ṣe ayẹwo, nibẹ ni wọn si ti sọ fun un pe bo tilẹ jẹ pe o ni nnkan ọmọkunrin labẹ, o si n ṣe bii ọkunrin ni yara pẹlu iyawo rẹ, sibẹ, ile ọmọ obinrin n bẹ ninu rẹ pẹlu.

Bawo leyi ṣe ṣẹlẹ?

Dokita Sushil Kharbanda, olori ẹka to n ri si itọju òpó ibi ti eeyan n gba tọ̀ (Urology), nileewosan aladani kan ni Delhi, ṣalaye pe ayẹwo lo fidi ohun to n ṣe ọkọ iyawo ti wọn ko darukọ rẹ naa mulẹ.

Dokita Kharbanda to tọju alaisan naa ṣalaye pe, lasiko ayẹwo ni awọn ri i pe ile ọmọ wa ninu ọkunrin naa, opo meji (Fallopian tubes) si wa nibẹ pẹlu.

" Ohun ti a n pe eyi kari aye ni "Persistent Müllerian Duct Syndrome" (PMDS), wọn maa n bi I mọ eeyan ni.

"O kere tan, o ti to eeyan ọọdunrun (300) ti akọsilẹ ti fi han pe wọn ni ai ṣe deede naa lara."

Bẹẹ ni Dokita Kharbanda wi.

Abajade iwadii kan ti wọn gbe jade ninu Journal Nature Reviews Urology, ṣalaye pe ọkunrin to ba ni Müllerian Duct Syndrome ni ohun ti a mọ si chromosomes 46XY niye, ara rẹ yoo maa dagba bii ọkunrin gidi.

Amọ awọn ohun to n dagba lara rẹ lati ibi Müllerian Duct yii, bii ile ọmọ obinrin ati opo rẹ yoo ṣi wa lara rẹ.

Dokita to tọju ọkunrin naa sọ pe irisi rẹ duro deede bii ti ọkunrin gidi, ko si si apẹẹrẹ kankan to fi han pe o ni ile ọmọ obinrin ninu ara.

Iru nnkan bayii ko wọpọ bi Dokita Kharbanda ṣe sọ.

Ṣe ọkunrin to ba n koju iṣoro yii yoo ni atọ ati ẹyin obinrin papọ ni?

Ile ọmọ obinrin

Idahun si eyi ni pe ni ẹgbẹ mejeeji ẹni naa, o ni opo to n gbe ẹyin lọ sile ọmọ, amọ ko ni apo to n pese ẹyin (ovary).

Nibi ti ẹyin yoo wa, atọ lo wa nibẹ fun ẹni to n koju iṣoro yii. Ọkunrin lo n pese atọ ti yoo di ọmọ, nigba ti obinrin n pesẹ ẹyin, wọn si yatọ sira wọn.

Ni ti ẹni yii, awọn eelo atibimọ mejeeji to ni jẹ atọ, ki i ṣe ẹyin.

Ki lo de ti wọn ko tete mọ pe nnkan naa n ṣẹlẹ?

Esi ti imọ ijinlẹ fun eyi ni pe awọn opo to n pese atọ lara alaisan naa ko si nibi to yẹ ki wọn wa.

Eyi ni wọn fi ṣe ṣayẹwo omoonu (hormone) ati atọ fun un.

Esi ti eyi mu wa ni oloyinbo n pe ni "Azoospermia", to tumọ si pe ko si awọn atọ to le di ọmọ ninu ohun to n jade lara ọkunrin naa.

Lẹyin eyi ni wọn ṣe ayẹwo kan ti a mọ si MRI fun un, eyi to fi han pe o ni ile ọmọ, ti awọn opo to n gbe ẹyin si wa nibẹ pẹlu eyi to yẹ ko gbe atọ.

Wọn tun ṣe ayẹwo mi-in lorii chromosome, iyẹn si fi han pe awọn chromosome rẹ jẹ 46XY.

Ki I ṣe dandan pe ki ọkunrin ti dagba ki wọn too mọ ohun to n ṣelẹ lara rẹ yii, to ba jẹ wọn ti tete ṣe ayẹwo lasiko ni, wọn ko ba ti mọ ohun to n ṣẹlẹ naa kia.

Ko si irora kan ti aisan naa maa n koba ọkunrin to ba mu.

Ko si ara riro, eebi, iba atawọn to farapẹ ẹ, ju pe atọ re ko si nibi to yẹ ko wa.

Ṣe iṣẹ́ abẹ ni wọn fi n ṣẹgun aisan yii tabi oogun lilo?

Bi eeyan ba ba ara rẹ ninu iru ipo yii, iṣẹ abẹ lo ṣe koko fun un lati ṣe .

Ni ti ọkunrin yii naa, won yọ awọn opo faIlopian tube nni kuro, wọn ko si ti I raye dagba ju lara rẹ, wọn ko ṣiṣẹ pẹlu.

Lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ naa tan, ayẹwo kan fi han pe ọkan lara awọn ohun to n di atọ lara rẹ ti ni awọn ayipada to le mu arun jẹjẹrẹ wa lọjọ iwaju.

Fun idi eyi, o ṣe pataki lati yọ ẹya ara naa kuro, iṣẹ abẹ si ni wọn fi ṣe eyi.

Iwadii fi han pe bi ọkunrin naa ba fi ẹya ara obinrin ti ko nilo yii silẹ lai mu un kuro, o le pada di jẹjẹrẹ ti a mọ si Cancer.

Igbesi aye lẹyin iṣẹ abẹ

Nnkan bii ọjọ meje lẹyin iṣẹ abẹ naa ni ọkunrin yii pada si ẹnu iṣẹ rẹ, to si n gbe igbesi aye rẹ pẹlu alaafia.

Niwọn igba to ti jẹ pe ohun ti a mọ si testosterone ni wọn ti yọ ọ kuro lara rẹ, ko ni I le pese eroja yii mọ.

Fun idi eyi, yoo ni lati maa gba abẹrẹ testosterone ni ẹẹkan laaarin oṣu mẹta.

Ni afikun, ko si kinni kan ti yoo ṣe biba obinrin lo pọ lara rẹ, agbara ibalopọ rẹ yoo ṣi duro deede, yoo si gbe igbesi aye rẹ lai si iyọnu.

Bakan naa ni ko si iyatọ gboogi ti yoo foju han lara rẹ lẹyin iṣẹ abẹ ọhun, nitori ilana ti a mọ si 'Laparoscopy', ti wọn ti maa n lo irinṣẹ kekere ti yoo fi ibi ti aleebu naa wa han, ti wọn yoo si fi abẹ sín oju ibi ti wọn ti fẹ yọ aleebu naa ni wọn lo fun un.

Pẹlu eyi, ẹni ti wọn ṣe e fun le pada sẹnu iṣẹ rẹ laaarin asiko perete.

Ẹkọ to wa ninu iṣẹlẹ yii

Ẹkọ to wa ninu iṣẹlẹ yii bi dokita ṣe wi, ni pe ki eeyan ma ṣe foju pa ohunkohun to ba yingin lara rẹ, tabi ayipada to n ba ri ninu ara rẹ.

Ohun to ṣe pataki ni lati tete gbera lọ sile iwosan, ki eeyan ma si tiju lati beere iranlọwọ.

Koda ko jẹ ọmọ ọwọ ni eeyan ri apẹẹrẹ to yatọ lara rẹ, tabi ti ẹya ara rẹ kan ti n fi ayipada ti ko yẹ han, kawọn obi rẹ tete gba ọdọ dokita lọ.

Atete mojuto aleebu, pẹlu ayẹwo ti ko pẹ rara, le dena ohun to le pada di ogun sinu ara.