Àṣírí iléeṣẹ́ ayédèrú ọtí tú l'Ekoo, NAFDAC gbẹ́sẹ̀ lé ọtí tó lé ní N2bn níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjọ ijọba apapọ to n bojuto ounjẹ ati ogun lorilẹede Naijiria (NAFDAC), ti ṣawari ileeṣẹ kan ti wọn ti n pọn ayederu ọti niluu Eko, wọn si gbẹsẹ le ọti ti iye rẹ le ni biliọnu meji naira nibẹ.
Ninu ọgba ibudo itaja nla ta a mọ si Lagos International Trade Fair Complex ni NAFDAC ti ṣawari ibi ti wọn ni ayederu ọti ni wọn n pọn naa.
Bawo ni aṣiri ṣe tu?

Oríṣun àwòrán, Sreenshot/NAFDAC Video
Ninu atẹjade kan ti ajọ NAFDAC fi sita lọjọ Iṣẹgun, wọn ṣalaye pe itọpinpin ati olobo to ṣee tẹle lo mu awọn de ibudo naa.
NAFDAC kede pe awọn ile itaja ti wọn ko awọn ayederu ọti yii si ni gbagede itaja naa le ni ogun (20).
Gẹgẹ bi ajọ yii ṣe ṣalaye, awọn oṣiṣẹ rẹ ri awọn afurasi naa nibi ti wọn ti n po ayederu ọti pọ, awọn ọti wọnyi si jẹ ẹya awọn ọti tootọ to gbajumọ lawujọ.
Wọn fi kun un pe awọn afurasi naa n ṣe atunṣe si ọjọ to yẹ ki awọn ọti naa ma jẹ mimu mọ.
Wọn n kọ ọjọ mi-in ti yoo pẹ si I lara, wọn si tun n ko awọn ọti ti wọn ti fofin de nilẹ okeere wọle si Naijiria.
NAFDAC sọ pe eeyan meji lọwọ ba lasiko tawọn de ibudo yii, wọn si ko awọn ọti ti wọn gbẹsẹ le naa jade.
Bakan naa, ninu fidio kan to fi sita, NAFDAC ṣafihan awọn ọti amarayagaga alawọ aro kan ti wọn to jọ.
Bakan naa ni awọn kan tun wa lapa kan ninu agolo ati paali.
Fidio naa tun ṣafihan àgbá nla alawọ aro kan ti wọn ko awọn nnkan ti wọn ko lo mọ si, bẹẹ ni awọn ọkunrin meji kan jokoo silẹẹlẹ, wọn fi ẹyin ti ogiri.
Awọn nnkan miran to tun wa nibẹ ni igo ọti ofifo pupọ, idẹri ọti, ohun ti wọn fi n de ọti naa pa, awọn iwe orukọ ti wọn n le mọ awọn ọti naa lara ati bẹẹ bẹẹ lọ.
NAFDAC kilọ ewu to wa ninu ayederu ọti tita
Nigba to n kilọ nipa ki iru ọti bayii jade sita fun tita, ajọ NAFDAC sọ pe ewu gidi lo jẹ fun ilera araalu.
Ajọ naa sọ pe awọn ọti ti ọjọ ti lọ lorii wọn tawọn eeyan yii n po pọ, le di ohun ti wọn n ko sori igba fawọn eeyan lati maa ra a lai mọ.
Wọn kilọ fun araalu lati ṣọra, ki wọn si maa fi ileeṣẹ to maa n ṣe ayederu nnkan to ijọba leti.
Bi ẹnikẹni ba ni ifisun lori nnkan bayii, nọmba ti NAFDAC fi sita pe ki wọn pe ni: 0800-1-NAFDAC (0800-1-623322).
























