'Igbó, Kolorádò wà lára èròjà tí wọ́n fi po ọtí tó gbẹ̀mí, fọ́ ọ̀pọ̀ lójú ní ìpínlẹ̀ Ondo'

Àkọlé fídíò, ‘Igbó, ‘Colorado’ wà lára èròjà tí wọ́n fi po ọtí tó pa ọ̀gọ̀rọ̀ èèyàn, fọ́ ọ̀pọ̀ lójú ní ìpínlẹ̀ Ondo’
'Igbó, Kolorádò wà lára èròjà tí wọ́n fi po ọtí tó gbẹ̀mí, fọ́ ọ̀pọ̀ lójú ní ìpínlẹ̀ Ondo'
Published

Eeyan mọkandinlaadọta lo padanu ẹmi wọn ti awọn marun miran si fọju tan patapata lẹyin ti wọn mu agbo ti wọn fi oriṣiriṣi adalu popọ ni ipinlẹ Ondo. Iṣẹlẹ yii jẹ eyi to ko ọpọ lọkan soke pe ki lo tun n fa iku ọwọọwọ lori ọti mimu.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Dokita Ayọdeji Anthony to ṣe itọju awọn to fara kaasa ọti gbẹmigbẹmi naa ṣalaye pe ariwo 'awọn ko riran mọ' ni gbogbo awọn ti wọn gbe wa si ileewosan oun lori mimu ọti gbẹmigbẹmi naa n pa ti wọn ba ti gbe wọn de.

Bakan naa ni oṣiṣẹ ajọ to n ṣe akoso ohun jijẹ, ati mimu lorilẹede Naijiria, Nafdac ni ipinlẹ Ondo ṣalaye pe awọn eroja to lewu fun ara ni wọn po pọ pẹlu ọti ti awọn to ku tabi fọ loju naa mu.

Ọkan lara awọn ti ori koyọ lọwọ ọṣẹ ọti gbẹmigbẹmi naa, Akinbami Ọlalekan ṣalaye pe 'Nigba ti mo ṣaa taji saye, mo rii pe gbogbo ẹya ara mi ti da ṣẹ silẹ.'

Eeyan mejidinlọgọsan lo ti jade pe awọn mu ninu ọti gbẹmigbẹmi yii gẹgẹbi ajọ Nafdac ṣe sọ.

Ẹkunrẹrẹ alaye nbẹ ninu fidio yii.