Ṣé òótọ́ ni pé ọ̀rọ̀ òṣèlú ló mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn máa pa ara wọn l'Osun? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan ko fararọ laipẹ yii niluu Osogbo, ipinlẹ Osun,laarin ọjọ Ẹti si ọjọ Aiku ọsẹ yii, pẹlu bi awọn eeyan kan ti wọn ni ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn ṣe gbinaya ti wọn si pa ara wọn.
Ohun ti ọpọ eeyan n sọ nipa iṣẹlẹ naa ni pe awọn to n fa rogbodiyan ko da iṣẹ ara wọn jẹ, wọn ni awọn oloṣelu lo ran wọn niṣẹ to fa iku ojiji fun wọn.
Bakan naa ni awọn kan n sọ pe ibo gomina ti wọn di loṣu Kẹjọ ọdun yii, to gbe Gomina Ademola Adeleke wọle fun saa keji, lo fa a tawọn kan fi n ran awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lati maa da ipinlẹ Osun laamu.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelade, fi atẹjade kan sita.
Ninu atẹjade naa lo ti ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa Osun ti ran ikọ ọlọpaa lọ si Osogbo lati kapa ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye lawọn agbegbe bii Owo-Eba ati Arowomole.
Atẹjade naa sọ pe lọjọ keji, oṣu Kẹwaa yii, ija awọn ẹgbẹ okunkun waye lagbegbe Owo-Eba, l'Osogbo.
Ninu ija naa ni eeyan meji ti ku iku ibọn, awọn si ni Adebayo Taoreed, tawọn eeyan mọ si "Small Rugged," ati Oluwaseyi Daniel, ti inagijẹ rẹ n jẹ "OSHA,"
Atẹjade naa fi kun un pe awọn eeyan kan naa tun farapa latari ibọn to ba wọn nibi ija naa.
"Nigba to tun di ọjọ kẹrin oṣu Kẹwaa kan naa, awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan tun ya bo agbegbe Arowomole, l'Osogbo, ninu ija naa ni wọn ti yinbọn fun ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Rasak Wahab, "Ojo Iku."
"Wọn sare gbe e lọ sile iwosan, o si n gba itọju lọwọ."
Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa naa ṣalaye.
"Loootọ ni awọn oloṣelu lo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lasiko idibo, amọ ko si ibo mọ bayii, oloṣelu kọ lo wa nidii ija ti wọn n ba ara wọn ja"- Alukoro ọlọpaa Osun
Lati tubọ tan imọlẹ si iṣẹlẹ yii, BBC Yoruba kan si DSP Ojelabi lowurọ ọjọ Aje, pe ko ṣalaye idi ija yii gan-an.
Ohun to sọ ni pe:
"Loootọ ni awọn oloṣelu lo awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lasiko idibo, amọ ko si ibo mọ bayii, oloṣelu kọ lo wa nidii ija ti wọn n ba ara wọn ja.
"Lọjọ keji oṣu Kẹwaa yii, ija ẹgbẹ okunkun lo waye, ẹmi meji si lọ si I, ọkan ti wọn n pe ni Small Rugged ati ikeji ẹ ti wọn n pe ni Ooṣa ni ẹmi bọ lara wọn lọjọ yẹn.
" A fidi ẹ mulẹ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni awọn mejeeji.
"Ohun to n ṣẹlẹ yii ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu ibo to waye lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ. Ohun to fa ija ko ju pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun maa n kọlu ara wọn bii iṣe wọn, iru ẹ naa lo si waye yẹn."
DSP Ojelade sọ pe bi ẹnikan ba ku ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, wọn maa n fẹ pa ẹlomi-in pada ninu ẹgbẹ alatako ni.
"Ohun ti a le sọ ni pe oloṣelu lọ wọn nigba ibo loootọ, amọ ibo ti tan bayii, ohun to n ṣẹlẹ yii ko kan ẹgbẹ oṣelu rara.
"Ko sẹni to n darukọ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan ni mi ninu wọn mọ bayii, oloṣelu ti lo wọn tan wọn si ti ju wọn silẹ, awọn ni wọn n ja ija agba laaarin ara wọn."
Bẹẹ ni Alukoro ọlọpaa Osun naa ṣalaye.
O fi kun un pe Kọmiṣanna ọlọpaa Osun, CP Ibrahim Zungura, ti dari awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ si agbegbe Oke-Baale , o si ti paṣẹ pe wọn ko gbọdọ kuro lawọn agbegbe ti rogbodiyan ti waye naa, afi ti alaafia ba jọba tan patapata.
"Awọn oloṣelu lo n da rogbodiyan yii silẹ, awọn agbofinro naa si ti gbabọde"- Alaga ẹgbẹ Ajafẹtọọ ọmọniyan nipinlẹ Osun
Ni itẹsiwaju ọrọ yii, BBC News Yoruba kan si Alaga ẹgbẹ Ajafẹtọọ ọmọniyan nipinlẹ Osun, Civil Society Coalition, iyẹn Kọmureedi Waheed Lawal, o ṣalaye pe:
"Yoruba ni o yẹ ka ṣe ohun to tọ lasiko to tọ, ka le baa ri esi to tọ. Àwọn oloṣelu lo n da ọpọlọpọ rogbodiyan silẹ.
"Lọjọ taye ti daye, a maa n da ọmọ ẹgbẹ okunkun mọ lọtọ , iṣe wọn, irisi wọn ati iwa wọn yatọ, ṣugbọn nigba tawọn oloṣelu ti tọwọ bọ ọ, to ti jẹ pe ati ọmọ ẹgbẹ okunkun, atọmọ ganfe gbogbo wọn ni wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu, eyi lo fa a ta a o fi mọ iyatọ ninu wọn mọ .
"Gbogbo wọn ti darapọ mọ oṣelu, to ba ṣe pe ibo kan wa lasiko yii ni, ẹ o le mọ pe ki I ṣe oloṣelu lo n pa ara wọn, ṣugbọn tori pe ko si ibo lasiko yii titi di ipari ọdun lo fi tete han pe awọn ọmọ ganfe ni.
Awọn agbofinro ti gbabọde
Lawal fi kun ọrọ rẹ pe awọn agbofinro ipinlẹ Osun paapaa ti gbabọde.
O ni nigba ti wọn ba ri awọn to n da omi alaafia ilu ru ti wọn ko si mu wọn, itumọ rẹ ni pe wọn ti gbabọde.
" Agbofinro n ṣegbe lẹyin awọn kan, wọn n gbogun ti awọn kan, awọn nnkan wọnyi ni ko le jẹ ka tete ri ojutuu si ọrọ yii."
Kọmureedi Lawal sọ pe bi ojutuu yoo ba lori ọrọ yii, afi kawọn agbofinro ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ. Ki wọn ma wo pe ọmọ ẹgbẹ kan ni ẹnikan.
Alaga ẹgbẹ Ajafẹtọọ ọmọniyan l'Osun naa sọ pe loootọ ni wọn ti fawọn ni kọmiṣanna ọlọpaa tuntun nipinlẹ Osun, amọ ọwọ oloṣelu ko ti i kuro ninu ọrọ yii bo ṣe sọ.
Awọn rogbodiyan to ti waye l'Osun lẹnu lọọlọ yii
- Bi idibo si ipo gomina ipinlẹ Osun ti wọn di loṣu Kẹjọ ọdun ṣe n sunmọle nigba naa, bẹẹ naa ni rogbodiyan ọlọkan o-jọkan bẹrẹ si i ṣẹlẹ nipinlẹ naa.
Awọn agbegbe kan l'Osogbo ati Ile Ife koju rogbodiyan naa to bẹẹ ti ẹmi awọn eeyan kan ba a lọ.
Eyi ni diẹ lara awọn ikọlu naa to waye titi ti idibo fi waye, ko too kan awọn to n ṣẹlẹ lẹyin idibo yii:
Oṣu Karun-un si Ikẹjọ 2026 (Eeyan mejidinlogun ku)
Ẹka CJID Conflict Tracker to maa n tọpinpin rogbodiyan ṣe akọsilẹ pe o kere tan, rogbodiyan mẹrinlelọgbọn (34) to ni i ṣe pẹlu ibo to waye kọja naa.
Eeyan mejidinlogun (18) ni wọn si ri pe wọn ba awọn iṣẹlẹ naa lọ.
- Oṣu Keje/ Ikẹjọ, iwọde Ilesa ati Osogbo: Ibọn yinyin bẹrẹ si I tọ ipolongo ibo lẹyin.
- Ọpọ alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu ku, ọpọ farapa. Awọn ẹgbẹ oṣelu APC ati Accord si bẹrẹ si i fẹsun kan ara wọn bii ẹni to n ro awọn janduku lagbara.
- Kikoju INEC, jiji kaadi idibo awọn eeyan lọ (Oṣu Keje 2026).
- Awọn janduku oloṣelu kọlu awọn oṣiṣẹ INEC, wọn ba awọn nnkan elo idibo jẹ.
Awọn janduku to dihamọra ogun yabo ile ẹkọ alakọọbẹrẹ Oyinlola DC Primary School, nijọba ibilẹ Odo-Otin.
Wọn kọlu awọn oṣiṣẹ INEC, wọn si ji awọn kaadi idibo alalopẹ awọn eeyan lọ.
- Rogbodiyan waye niluu Iree.
Kete lẹyin idibo, awọn janduku oloṣelu yabo ile ọba Iree, ọba pada pe fun aabo pajawiri ni.
- Ikọlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun n lọ lọwọ (Oṣu Kẹwaa, 2026)
Yatọ si oṣelu, ikọlu to lagbara ti waye laarin awọn ẹgbẹ okunkun, nibi ti wọn ti n ja ija agba.
Ipaniyan Osogbo (Ipari 2025):Awọn ẹgbẹ okunkun alatako koju ara wọn lawọn agbegbe bii Orita Elelede l'Osogbo, ọpọ eeyan lo fara kaaṣa iṣẹlẹ yii, ti awọn ọlọja ko si le ṣilẹkun mọ nitotri ibẹrubojo.
Lara rogbodiyan to waye l'Osun naa ni ti awọn onimọto akero .
Lori rẹ ni Gomina Ademola Adeleke paṣẹ, pe ki igun NURTW sọra ṣe.
Iku Emir Ajagungbade, ọlọkọ ero ti wọn lo ṣiṣẹ fun Gominaa naa wa nibẹ pẹlu, ti baale ile ṣe bẹẹ dero ọrun aremabọ loṣu Kẹsan-an ọdun yii.

























