Àádọ́ta mílíọ̀nù náírà ni wọ́n sọ pé kí n mú wá láti gba ìtúsílẹ̀ ọmọ mi - Bàbá àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé

Awọn obi ti wọn ji awọn ọmọ wọn gbe nibi ijinigbe to waye ni ipinlẹ Imo ti sọ pe awọn ajinigbe naa ti kan si awọn, ti wọn si ti n beere fun owo itusilẹ lati fi gba itusilẹ awọn eeyan naa.
Ọkan lara awọn obi agbubanirọ naa sọ fun BBC News Yoruba pe awọn ajinigbe naa ti kan si awọn ni owurọ ọjọ Ẹti pe ki awọn lọ wa aadọta miliọnu naira wa fun ọmọ kọọkan ti wọn ba ni ẹmi ọmọ wọn lọ.
Omotosho Adewale, ọkan lara awọn obi ọmọ naa sọ pe funra oun ni oun mu ọmọ oun lọ si ibudokọ to wa ni Samọda ni agbegbe UI niluu Ibadan lati w'ọkọ to n lọ si ipinlẹ Abia ti ọkọ naa si gbera loju oun ni irọlẹ ọjọru.
O ṣalaye pe ọmọ oun ati iya rẹ n sọrọ titi di alẹ ti wọn fi de ilu Onitsha ni ipinlẹ Abia nibi ti wọn sun si mọjumọ ki wọn to tẹsiwaju ninu irinajo wọn ni aago mẹrin owurọ ọjọ keji, ki iroyin to tẹ awọn lọwọ pe awọn ajinigbe ti ji wọn gbe.
O ni lati igba naa ni awọn ti npe ẹro ibaniṣọrọ ọmọ naa titi di owurọ ọjọ Eti kawọn ajinigbe naa to kan si awọn pe ki awọn lọ maa wa aadọta miliọnu naira gẹgẹ bi owo itusilẹ.
Omotosho wa rọ ijoba ipinle Oyo ati ijọba apapọ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to wa l'orile ede Naijiria lati gba awọn ọmọ wọn silẹ lọwọ awọn ajinigbe layọ ati alaafia nitori awọn ko ni owo ti wọn n beere fun naa.
Nigba ti a kan si ile-iṣẹ Awọn agunbaniro to wa ni agbegbe Agodi gate niluu Ibadan ṣugbọn awọn ti a ba ni bẹ sọpe awọn ọga ti wọn le bawa sọrọ wani ilu isẹyin ni ibi ti awọn agunbaniro ti wọn ṣẹṣẹ fi ranṣẹ si ipinlẹ Ọyọ wa.
Ibudokọ ti awọn eeyan naa ti wọ ọkọ ti gbe orukọ awọn eeyan tawọn ajinigbe ji gbe naa siita, ti aworan naa si fi han pe eeyan mẹẹdogun ni wọn ji gbe, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ni awọn ti gba itusilẹ eeyan mẹwaa ninu wọn
A ti ń ṣiṣẹ́ láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé ní ìpínlẹ̀ Imo - Ìjọba Oyo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Oyo ti kọminu lori awọn agunbanirọ to jẹ ọmọ ipinlẹ naa ti wọn ji gbe ni ipinlẹ Imo lasiko ti wọn n lọ lati lọ silẹ baba wọn.
Atẹjade ti Kọmiṣanna ipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade fi lede sọ pe iroyin ijinigbe awọn agunbanirọ naa ba oun lọkan jẹ paapaa lasiko yii ti Naijiria n koju awọn ipenija nla kọja.
Ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ ohun to buru gidi, ti awọn si n ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹṣọ aabo, ijọba ipinlẹ Imo, awọn alaṣẹ ajọ agunbanirọ lati le gba itusilẹ awọn agunbnirọ naa ni kiakia.
Oyelade ninu atẹjade naa fi kun pe awọn ni ifarajin si gbigba itusilẹ awọn eeyan naa ni ayọ ati alaafia, ti awọn ko si ni ko aarẹ ọkan lati ti pe awọn eeyan naa pada sile wọn layọ.
O fi kun pe Gomina Seyi Makinde ti dari gbogbo awọn ohun to yẹ lati ṣawari awọn eeyan naa, to si tẹmpẹlẹmọ pe aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Oyo lo jẹ ijọba logun yala ninu ipinlẹ naa tabi lẹyin odi.
Ijọba wa rọ ẹbi awọn agunbanirọ naa lati ṣe suuru pẹlu ijọba, ti ijọba si ṣọ aridaju rẹ lati tẹsiwaju pẹlu iwadii wọn lati gba awọn naa silẹ.
Bakan naa ni wọn rọ awọn ẹṣọ aabo lati pọn kun akitiyan wọn, ki wọn si foju awọn ọdaran to ṣiṣẹ ibi naa wina ofin.
Wọn ni gbogbo awọn alẹnulọrọ to wa lori iṣẹlẹ naa ni awọn n ba ṣiṣẹ lati dena irufẹ ijinigbe bẹẹ lọjọ iwaju.
Ọlọpaa gba itusilẹ mẹwaa ninu awọn ti wọn ji gbe
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati gba itusilẹ awọn agunbanirọ atawọn eeyan mii tawọn ajinigbe ji gbe nigba ti wọn n ṣe irinajo lọ si ibi ti wọn fẹ lọ sin ilẹ baba wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan mẹwaa ni awọn ti gba itusilẹ wọn ninu awọn eeyan ọhun.
Agbẹnusọ ọlọpaa Imo, Okoye Henry sọ pe opopona Owerri si Onitsha ni wọn ti ji awọn eeyan naa gbe ati pe akitiyan pẹlu awọn ẹṣọ aabo mii ni wọn fi gba itusilẹ awọn eeyan naa silẹ.
O ni nnkan bii aago mẹfa abọ owurọ ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti awọn ajinigbe ji awọn agunbanirọ atawọn ero ọkọ mii ti wọn n ṣe irinajo lati ilu Ibadan lọ si ipinlẹ Akwa Ibom ati Abia gbe.
Okoye ni awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo tete ji giri si ojuṣe wọn eyi to mu ki wọn gba itusilẹ mẹwaa ninu awọn eeyan naa.
O fi kun pe awọn eeyan ti wọn gba itusilẹ wọn ni wọn wa ni alaafia, ti wọn si n gba itọju.
Ohun tí a mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jí àwọn èèyàn gbé nínú bọ́ọ̀sì tó ń kó àwọn àgùnbánirọ̀ láti Ibadan lọ sí àgọ́ NYSC ní Imo àti Akwa Ibom

Oríṣun àwòrán, KOLA SULAIMON/AFP via Getty Images
Awọn agbebọn kan ti ji awọn eeyan mọkandinlogun, pupọ ninu wọn jẹ agunbanirọ to n lọ bẹrẹ eto isinruulu wọn.
Ọkọ bọọsi meji to ko awọn eeyan arinrinajo naa lawọn agbebọn naa dẹbu rẹ ni ipinlẹ Imo ti wọn si ko awọn eeyan inu rẹ lọ.
Awọn ibudo ifinimọle awọn agunbanirọ to wa ni ipinlẹ Imo ati Akwa Ibom ni awọn bọọsi naa n ko awọn eeyan naa lọ ki wọn to ji wọn gbe ni Ọjọbọ.
Ọgbẹni Isaiah Akpan to ṣalaye ọrọ naa fun BBC sọ pe, '"meji ninu awọn ọkọ mi gbe awọn eeyan lati ilu Ibadan lalẹ ana, ọkan ninu rẹ n lọ si agọ ifinimọle NYSC ni Akwa Ibom, ikeji si n lọ si ti Ipinlẹ Imo".
O ni wọn ji gbogbo awọn arinrinajo inu bọọsi akọkọ gbe, wọn si ji mẹrin gbe ninu ikeji.
"Eyi sọ iye awọn ti wọn ji gbe di mọkandinlogun."
Ki ni ọlọpaa sọ?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo, Henry Okoye sọ fun BBC pe ọrọ naa ti kan awọn ọlọpaa leti.




























