Ojúlówó ọmọ Yorùbá ni mí, Atiku Abubakar ni màá tì lẹ́yìn fún ipò ààrẹ ní 2027, àmọ́ kò sí aáwọ̀ láàrin èmi àti Peter Obi - Gbadebo Rhodes-Vivour

Gbadebo Rhodes-Vivour, tii se oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbe oselu African Democratic Congress, ADC nipinlẹ Eko, ti salaye nipa ajọsepọ rẹ lọwọ lọwọ pẹlu Peter Obi, tii se oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ oselu National Democratic Party, NDC.
Rhodes-Vivour ni ko si aawọ kankan laarin oun ati Peter Obi nitori Asiwaju ati ọga oun si ni ninu oselu.
Rhodes-Vivour sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ kan pelu BBC News Yoruba.
Amọ o ni oludije aarẹ ti oun n tẹle lẹyin lasiko yii ni Atiku Abubakar to n soju ẹgbẹ oselu ADC tori ẹgbẹ oselu ko pa oun ati Peter Obi papọ.
"Nigba akọkọ ti mo dije fun ipo oselu lati lọ sile asofin agba, Atiku Abubakar lo n dije fun ipo aarẹ, ti Peter Obi si jẹ igba keji rẹ.
Nibayi ti awọn mejeeji n dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu ọtọọtọ, ẹgbẹ oselu ADC t imo wa, ni maa se, tori naa, Atiku ni oludije sipo aarẹ t imo n sugba rẹ.
Awọn oludije sipo aarẹ mejeeji ni wọn jẹ ẹni ọwọ, ti n ko le sọrọ abuku si, koda, nigba ti mo wa ninu ẹ́gbẹ oselu Labour, mo lọ si Adamawa nibi iwuye Atiku.
Oun si lo n gba awọn eeyan si isẹ julọ nipinlẹ naa tori ọpọlọpọ ileesẹ to ti da silẹ nipinlẹ naa, mo si nifẹ si eleyi tori ọpọ awọn oloselu wa nilẹ yii lo ni owo gọbọi amọ ti wọn n ko lọ soke okun.
Tori pe mo wa ninu ẹgbẹ oselu miran, ko tumọ si pe ma maa sọrọ abuku ransẹ si Peter Obi, rara o, emi kii se iru eeyan bẹẹ."

"Ohun to yẹ kawọn oloselu fi se ipolongo ibo ni ohun ti wọn fẹ se fawọn araalu ati erongba wọn ti orilẹede yii yoo fi dara si"
Nigba to n sọrọ lori ọna to yẹ kawọn oludije maa gba se ipolongo ibo lai lọwọ ọrọ abuku ninu, Gbadebo Rhodes-Vivour sọ pe awọn ọmọ Naijiria ni anfaani lati dibo fun ẹni to ba wu wọn.
"Ohun to yẹ kawọn oloselu fi se ipolongo ibo wọn ni ohun ti wọn fẹ se fawọn araalu, awọn erongba wọn ti orilẹede yii yoo fi dara si.
Awọn eeyan si le pinnu lati dibo fun ẹni ti wọn gbagbọ pe yoo mu ayipada ba igbe aye wọn si rere.
Amọ adura ti a maa gba ni pe ki ibo wa jẹ kika, ki ohun wa si goke, yoo si dara ki wọn gba awọn eeyan to ni erongba rere laaye lati gori aleefa.
"Emi ko le fi owo ra ipo lati de ori aleefa gomina, n ko ni baba isalẹ, Ọlọrun ni baba isalẹ mi"
Nigba ti BBC News Yoruba beere lọwọ Gbadebo Rhodes-Vivour pe ta ni onigbọwọ rẹ, to n gbe owo silẹ fun lati dije fun ipo gomina.
Nigba to n fesi, Oludije sipo gomina nipinlẹ Eko naa salaye pe oun kii se oloselu ti yoo maa pariwo pe oun ni Dọla ati Pọun lati fi se ipolongo ibo amọ oun ni erongba rere fawọn araalu.
"Eto rere ti mo ti mo ni, eyi ti mo la silẹ ni mo n ta ati iran ọjọ ọla to dara fun ipinlẹ Eko eyi ti yoo mu ki igbe aye wọn tubọ dara si.
Ọna kan soso ti mo le gba de ipo ni pe tawọn eeyan ipinlẹ Eko ba ni igbagbọ ninu mi, ti wọn si gbe mi si ipo gomina naa.
Emi ko le fi owo ra ipo fun ara mi lati de ori aleefa gomina, Ọlọrun ni baba isalẹ mi"
"Abuku nla ni ki ẹnikẹni maa sọ pe ilu Eko ko jẹ ti ẹya kankan, abuku ni fun mi ati awọn baba nla mi"
Bakan naa ni Gbadebo Rhodes-Vivour tun sọrọ lori awuyewuye to maa n suyọ lori ayelujara pe ko si ẹya kankan to ni Eko, tabi pe Eko jẹ ilu abinibi wọn tori gbogbo eeyan ni Eko wa fun.
O ni ko si igba kankan ti ilu Eko jẹ ti gbogbo aye tori awọn eeyan kan lo ni ilu naa.
"Ọdun mẹrin mẹrin la maa n gbọ nipa awuyewuye yii, ti ọkunrin kan to jẹ ẹya Igbo, ti wọn n pe ni Chukwu yoo jade sita pe ilu Eko ko si fun ẹnikan, ti gbogbo aye ni.
Nnkan yii ko ri bẹẹ, sebi ọmọ onilẹ kan ni wọn sanwo ilẹ fun, to ba jẹ pe kii se awọn eeyan kan lo ni ilẹ naa, ki lo de ti wọn n fi owo ra a?
Mo wo fidio Ẹyọ kan lasiko ijọba Mobolaji Johnson ni Eko, wọn n ki Ẹyọ pe ọmọ onilẹ a tẹ ẹ jẹjẹ, awọn ajeji yoo tẹ ẹ girigiri.
Eyi tumọ si pe awọn eeyan kan wa to ni ilẹ naa, ti awọn ajeji naa si wa.
Awọn eeyan ilu Eko maa n ko alejo mọra bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan le ri bii aleebu wọn amọ idi ree ti ipinlẹ Eko se jẹ ilu to pataki julọ nilẹ Naijiria.
Ọkunrin adulawọ to lowo julọ ni ibujoko ileesẹ rẹ nilu Eko, o kọ ibudo ifọpo silu Eko, koda, awọn olowo to tobi julọ marun lo wa nibi."
Oludije sipo gomina naa ni agbara ilu Eko niyẹn, eyi to n mu ki owo ti ipinlẹ naa n pa wọle pọ pupọ.
O fikun pe abuku nla gba ni pe ki ẹnikẹni maa sọ sita pe ilu Eko ko jẹ ti ẹya kankan, abuku ni fun oun ati awọn baba nla oun.
Gbadebo ni oun ko ro pe ẹnikẹni le sọ bẹẹ niwaju oun, koda, oun mọ awọn eeyan nla mẹta to ti sọrọ nipa isẹlẹ naa, ọkan ninu wọn ni Mobolaji Johnson to sọ yanya pe ilu Eko ko jẹ ti gbogbo eeyan.
"Ojulowo ọmọ Yoruba ni mi, emi kii se ajeji, kii ṣe oye Yoruba kekere ni mo di mu ni Eko, emi ni Obalufọn gbogbo Eko patapata"
Gbadebo Rhodes-Vivour tun mẹnuba bi awọn eeyan kan se n kede kiri pe oun kii se ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba.
Oludije sipo gomina nipinlẹ naa ni irọ to jinna si ootọ ni ahesọ ọrọ yii tori ọmọ bibi ipinlẹ Eko ni oun, ti oun si jẹ ojulowo ọmọ Yoruba pọnbele.
O wa ke si awọn eeyan to n gbe iroyin kiri pe oun kii se ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, pe ki wọn jawọ ninu titan iroyin eke naa kalẹ.
Gbadebo Rhodes-Vivour sisọ loju rẹ pe kii ṣe oye Yoruba kekere ni oun di mu nipinlẹ Eko, ti oun si n ri pe ihuwasi ati asa Yoruba jẹ ohun ti oun gbe larugẹ.
O ni oun ni agba oye Gbadebo Rhodes-Vivour, to jẹ Obalufọn gbogbo ilu Eko patapata.

Ta ni Gbadebo Rhodes-Vivour?
Gbadebo Rhodes-Vivour, ti ọpọ mọ si GRV ni oludije sipo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour.
Wọn bi Rhodes-Vivour lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun 1983 ni agbegbe Lagos Island, nipinlẹ Eko.
Orukọ baba rẹ ni Olawale Rhodes-Vivour, nigba ti iya rẹ n jẹ Nkechi Rhodes-Vivour.
O kẹkọọ gboye ni fasiti ilu Eko, UNILAG, fasiti Nottingham nilẹ Gẹẹsi ati ibudo imọ ẹrọ to w ani Massachusetts nilẹ Amẹrika.
Ajafẹtọ ọmọniyan ni GRV, o tun jẹ oniṣowo, onwoye ohun to n lọ lawujọ, ayaworan ile ati oloṣelu.
Oun lo ṣagbatẹru eto Nigerians Against GMOs (NAG), o tun n lewaju awọn to n pe fun ẹkọ nipa itan lawọn ile ẹkọ ni Naijiria.
O ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Consultants Collaborative Partnership (CCP) ati Patrick Waheed Consultants ko to da ileeṣẹ ara rẹ silẹ.
O wọ inu eto oṣelu lọdun 2007 lasiko to dije fun ipo alaga ijọba ibilẹ Ikeja labẹ asia ẹgbẹ oṣelu KOWA.
Lọdun 2019, o dije du ipo aṣofin agba lati ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Eko nile igbimọ aṣofin agba labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP, amọ o lulẹ.
Lọjọ mẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, o jawe olubori gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije du ipo gomina labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu Labour lẹyin to kọ ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.
Orukọ iyawo rẹ ni Ify Rhodes-Vivour, to jẹ ọmọ gomina ologun ipinlẹ Kogi ati Bornu nigba kan ri, Augustine Aniebo.

























