Ṣé lóòótọ́ ni àjọ EFCC ṣí ìwé ìránti kan ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí wọ́n fi kan Aitku lọ́dún 2006? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC ti ṣi iwe iranti kan ẹsun iwa jibiti ati magomago ti wọn fi kan oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC, Atiku Abubakar.
Ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ, Ọnarebu Ehiozuwa Johnson Agbonayinma lo fẹsun iwa ibajẹ kan Atiku Abubakar, to si n fẹ ki wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ.
Iwe ẹsun naa ni Agbonayinma kọ si EFCC lati gbe ẹsun naa dide pada, to si ni ko yẹ EFCC gbagbe iru ẹsun iwa ibajẹ bẹẹ.
Ninu iwe ẹsun ti Agbonayinma kọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026, lo ti sọ pe iwadii ti EFCC n ṣe lọ labẹ iṣakoso Nuhu Ribadu ko yẹ ko lọ bẹẹ lai fi ẹnu rẹ ko.
Agbẹjọro Agbonayinma, Oloye Hannibal Egbe Uwaifo lo kọwe ẹsun naa ranṣẹ si EFCC, eyi ti wọn gba lọjọ kinni, oṣu Kẹsan, ọdun 2026.
Ọnarebu tẹlẹ naa sọ pe ki EFCC ṣagbeyẹwo abajade igbimọ ile igbimọ aṣofin ilẹ Amẹrika lori ẹsun naa.
Nigba to n sọrọ ninu iwe ẹsun naa, Agbonayinma sọ pe ko yẹ ki ẹjọ naa tẹnu bọ epo lai jẹ pe wọn ri idi okodoro lori rẹ.
"Mo fẹẹ dupẹ lọwọ ọmọ Naijiria, ajọ EFCC, ati gbogbo awọn to n gbadura fun mi ninu ilakaka yii. Ofin wa fun olowo ati mẹkunnu ni," Agbonayinma sọ bẹẹ.
O sọ pe, "Lẹyin ti EFCC ti ṣiṣẹ takuntakun, ko yẹ ki wọn gba ẹsun naa si abẹ tabili wọn."
O tẹsiwaju pe o ṣe pataki fun EFCC lati pada yẹ ẹsun inu oṣu Kẹsan, ọdun 2006 lori Atiku wo, ati abajade igbimkọ ile igbimọ aṣofin ilẹ Amẹrika lọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2010.
Aṣoju-ṣofin tẹlẹ naa sọ pe awọn iwe naa yẹ ko jẹ nnkan ti wọn yoo ṣe agbeyẹwo wọn.
O ni EFCC ti sọ tẹlẹ wi pe o ṣee ṣe ki atiku foju bai le-ẹjọ nigba to ba kuro ni iṣakoso gẹgẹ bi igbakeji aarẹ, ṣugbọn ti ko si ohun to jọ bẹẹ mọ.
Bakan naa lo sọ pe bi EFCC ba kọ lati ṣe atungbeyẹwo ẹsun naa, yoo ja s iwi pe ajọ naa ko fẹẹ mu awọn alẹnulọrọ nidi oṣelu lati ṣalaye bi wọn ṣe lo ipo wọn.
Bẹẹ lo tun fidi rẹ mulẹ pe oun ti kọ iwe ẹsun miran ranṣẹ si Aarẹ Donald Trump ti ilẹ Amẹrika lori ẹsun naa.
Ṣugbọn sibẹ, agbẹnusọ ajọ EFCC, Dele Oyewale ko tii sọ ohunkohun lori iwe ẹsun naa titi digba ti a fi pari akojọpọ iroyin yii.



























