Àtúnṣe òpópónà márosè Lekki si Epe bẹ̀rẹ̀ bayii, wo bó ṣe kàn ọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe atunṣe opopona marosẹ Lekki si Epe yoo bẹrẹ lọjọ Ẹto, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Ọjọ marundinlogoji ni ijọba Eko sọ pe atunṣe opopona ọhun yoo fi waye, lati le jẹ ko wa ni eyi ti yoo jẹ alalopẹ.
Oludamọnran pataki fun gomina lori ọrọ akanṣe iṣẹ nipinlẹ naa, Olufemi Daramola lo fidi rẹ mulẹ fawọn araalu.
Daramola rọ awọn awakọ lati wa ọna miran ti wọn yoo gba laaarin asiko ti atunṣe naa yoo fi waye.
Lati agbegbe ti wọn pe ni Bonny Camp si oju ọna Admiralty to wa ni agbegbe Victoria Garden City ni iṣẹ atunsẹ naa yoo ti bẹrẹ, gẹgẹ bo ṣe ṣalaye.
Daramola fidi rẹ mulẹ pe ijọba Eko ti ṣe agbekalẹ ọna ti awọn awakọ yoo maa gba, eyi ti yoo mu adinku ba sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ti yoo ṣẹlẹ.
Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn alẹnulọrọ ti ileeṣẹ to n ri sọrọ akanṣe iṣẹ ati iṣẹ ode ṣagbekalẹ rẹ, eyi to waye l'Ọjọru, ọsẹ yii, oludamọran pataki naa sọ pe agbekalẹ ti wa nilẹ ti yoo dena sunkẹrẹ-fakẹrẹ.
Bakan naa lo sọ pe awọn ileeṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ to ja geere naa tun ni eto ti wọn ti gbe kalẹ fun awọn awakọ lati rin lai si idiwọ.
Daramola jẹ ko di mimọ pe ipade naa lawọn gbe kalẹ lati jẹ ki araalu mọ eto ijọba ṣaaju asiko ti atunṣe opopona ọhun yoo bẹrẹ.
O wa rọ gbogbo araalu ati awọn awakọ, paapaa bi ipinlẹ Eko ṣe n gbaradi fun sunkẹrẹ-fakẹrẹ lasiko pọnpọnṣinṣin ọdun to n bọ.
Siwaju sii lo ṣalaye pe atunṣe opopona naa ni lati mu idagbasoke de ba igbokegbodo ọkọ fun araalu ati gbogbo eeyan, paapaa awọn olokoowo ati ileeṣẹ to wa lawọn agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Kí lọ n ṣẹlẹ̀ lòpópónà náà
Opopona marosẹ Leeki si Epe yii jẹ eyi ti awọn ọkọ nla-nla ati kekere n gba loore-koore, paapaa bi awọn ileeṣẹ nla-nla ṣe pọ lagbegbe naa.
Awọn agbegbe bii Lekki Free Zone, to fi mọ awọn ileeṣẹ bii ileeṣẹ ifọpo Dangote, ileeṣẹ Dangote to n ṣe ajilẹ, Lekki Deep Sea Port ati Eleganza Industrial Estate.
Bakan naa ni opopona marosẹ yii tun n ṣiṣẹ fun awọn ileegbe igbalode ati ile-ẹkọ nla-nla to wa nitosi.
Daramola tun jẹ ko di mimọ ninu ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ naa tun n ṣagbeyẹwo oju ọna omi agbara, ati pe oju irin ti wọn fẹẹ bẹrẹ yoo ṣe iranwọ pupọ fun idagbasoke lagbegbe naa.
Nigba toun naa n sọrọ, alakoso eto iṣẹ akanṣe, Ibiroke Olukoko sọ pe iṣe akanṣe opopona yii yoo fi anfaani nla silẹ fawọn olokoowo lati gbe ọja wọn rin lai ni idiwọ.
O ni eto ọrọ aje yoo tun lọ soke sii, niwọn igba ti opopona to ja geere ba ti wa ni awrọwọto.
Alaga ẹgbẹ awọn olugbe Victoria Island ati Ikoyi, Ọmọọba Akin Fadoju, nigba to n sọrọ, sọ pe ohun kan ṣoṣo to le mu opin de ba omiyale lagbegbe naa ni ki ijọba ṣe oju ọna ti omi yoo gba, paapaa lasiko ojo.
O ni bi ijọba ba ṣe oju ọna omi, adinku yoo de ba omiyale ti awọn eeyan n koju ni gbogbo igba.




























