Ìgbéyàwó mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló dàrú, àmọ̀ mo dúpẹ́ pé mo ṣe àṣeyọrí níbi iṣẹ́ orin-Àlàájà Salawa Abeni

Oríṣun àwòrán, Queen Salawa Abeni
Gbajugbaja olorin Waka nni, Alhaja Queen Salawa Abẹni, ti ṣalaye pe igba mẹta loun ti ṣegbeyawo, amọ ko si eyi to ri boun ṣe fẹ ko ri ninu wọn.
Alhaja Salawa ṣalaye ọrọ yii lori eto gbajugbaja atọkun, Morayo Brown.
Olorin waka naa to ti pe aadọta ọdun (50) to ti n kọrin, sọ pe oun gbiyanju lori awọn igbeyawo naa, amọ gbogbo rẹ lo tuka.
"O wu mi lati wa labẹ ọkunrin bii iyawo, amọ gbogbo ẹ ko bọ si i"
Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye naa, salawa to sọrọ lede oyinbo, sọ pe:
''Hmm, o dun mi lati kede pe igbeyawo ti mo ṣe laipẹ yii ti wa sopin. Nnkan o ri bo ṣe yẹ, mi o dẹ fẹẹ ku lori ohun ti ko bọ si i, tori ẹ ni mo ṣe pinnu lati tẹsiwaju ninu irinajo aye mi.
" Mo fẹran igbeyawo, o si maa n wu mi lati wa labẹ ọkunrin. Iya mi o lọkọ meji. Lẹyin igbeyawo mi akọkọ ati ikeji, mo gbiyanju lẹẹkẹta si i pẹlu ero pe iyẹn maa yatọ. Amọ ko bọ si i."
Alaaja Salawa tẹsiwaju pe oun dupẹ pe oun ti bi awọn ọmọ ti wọn ti dagba, Alaaaji Kollington Ayinla naa si ni baba wọn.
"Pẹlu gbogbo ẹ naa, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbesi aye mi ati idile mi
"Ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹwaa yii lo maa pe aadọta ọdun ti mo ti n kọrin.
"Mo fẹ kawọn ololufẹ mi waa ba mi gbe Oluwa ga fun iṣododo rẹ. Ẹ ṣe pupọ."
Diẹ nipa Alaaja Salawa Abeni

Oríṣun àwòrán, Queen Salawa Abeni/Instagram
Wọn bi Salawa Abeni Alidu to pada di aya Kollington Ayinla olorin Fuji lọjọ karun-un, oṣu Karun-un ọdun 1961.
Ọmọ Ijebu Waterside nipinlẹ Ogun ni, amọ Epe nipinlẹ Eko ni wọn bi i si.
O bẹrẹ orin waka nigba ti ọjọ ori rẹ ṣi kere, iyẹn lawọn ọdun 70s.
Ọdun 1976 lo gbe awo to ṣe fun Oloogbe Murtala Ramat Mohammed jade, awo naa si ta ju miliọnu kan lọ.
Ọba Lamidi Adeyemi (Alaafin Oyo) to waja lo de e lade Waka lọdun 1992.
Ṣaaju ni Salawa ti fẹ Oloogbe Lateef Adepoju, ko too fẹ Kollington Ayinla ti igbeyawo naa si foriṣanpọn laarin ọdun 1990.
Lẹyin eyi ni olorin Waka naa fẹ ọkunrin ẹṣọ aṣọbode kan to gbe aworan rẹ jade, eyi to fi kede igbeyawo kẹta.
Alhaji Rasheed Adahunse tawọn eeyan tun mọ si Rasheed Agbolade Adahunse ni Salawa fẹ ṣikẹta.
Ọga aṣọbode to ti fẹyinti ni ọkunrin naa.
Ọdun 2019 ni wọn di tọkọtaya, amọ oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni Salawa fi han lasiko ti baba naa n ṣe ayẹyẹ ifẹyinti ati ọjọọbi rẹ niluu Eko.
Abeni, Idunnu Ishola, ni Alaaja Salawa pe ọga aṣọbode yii nigba naa, ko too kede bayii loṣu Kẹwaa ọdun 2026 pe igbeyawo naa ti dopin.

























