Ìṣẹ́ àti òṣì ló mú mi lu ọmọ ní Gbànjo ₦2m, afurasí ṣàlàyé fún ọlọ́pàá

Aworan afọwọya oju obinrin kan to n sunkun.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ iṣẹ ati iya lorilẹede Naijiria jẹ eyi to ti mu ọpọ eeyan maa kọminu, koda awọn ajọ agbaye pẹlu ti da si ọrọ naa lati igba de igba, ṣugbọn ki ni ka ti sọ nigba ti iya kan ba n sọ wi pe oun ta ọmọ oun nitori iṣẹ ati iya to n ba oun finra.

Cecilia Amos, ẹni ọdun mẹtalelogun lo ta ọmọ rẹ to jẹ ọmọ oṣu kan fun miliọnu meji naira ni ipinlẹ Ọyọ.

gẹgẹbi awọn agbofinroṣe sọ, Cecilia ta ọmọ rẹ naa fun oniṣegunoyinbo kan ti orukọ n jẹ Dokita Ebenezer Adeleke to jẹ oludari ileeṣẹ iwosan Ebepraise Health Centre, to wa ni ilu Ido ni ijọba ibilẹ Ido ni ipinlẹ Ọyọ kan naa. iwadii sọ pe ni ileewosan yii kan naa ni arabinrin Cecilia bi ọmọ rẹ ọhun si.

Ọwọ ọlọpaa tẹ Cecilia Amos, ẹni to ni arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Hassan, to jẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ido lo gba oun nimọran lati ta ọmọ naa, ati wi pe iṣẹ ati oṣi to mu oun bi omi lo mu ki oun da ọrọ naa ro ti oun si gba a wọle.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, obinrin Hassan ọhun lo ṣamọna bi wọn ṣe ta ọmọ naa fun obinrin mii ti yoo maa san owo rẹ diẹdiẹ.

Amos ti gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) ninu owo naa, ṣugbọn o ni lẹyin oṣu kan ti oun beere ọmọ naa ni wọn kọ lati jẹ ki oun ri i.

Ọwọ ọlọpaa tun tẹ awọn ọkunrin meji ti wọn n ba ara wọn ṣe ibalopọ akọsakọ

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo tun tẹ ọpọ afurasi lori oniruru iwa ọdaran miran bii ipaniyan, nini ohun ija oloro lai gba aṣẹ ati tita eeyan wa ninu wọn.

Olu ọọfisi ileeṣẹ naa to wa lagbegbe Eleyele, niluu Ibadan ni wọn ti fi oju wọn lede ti awọn afurasi naa si sọrọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Lara awọn ti ọwọ tẹ ni Abdurashid Muzik, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun ati ekeji rẹ, Shuaibu Aremu, ti ọlọpaa fi ẹsun nini ibalopọ akọsakọ kan.

Ninu iroyin mii, ọlọpaa tun fi oju Adewole Adeyemi lede lori ẹsun pe o ni ibọn ni ikawọ rẹ, eyii to ṣokunfa iku ẹnikan.

Adeyemi ṣalaye pe oun mu afurasi ole kan ni adugbo wọn ni Ifesowapo to wa lagbegbe Lalupon, ti oun si fa ole naa le ikọ Agbekoya lọwọ.

O ni lẹyin eeyi ni awọn eeyan kan ti wọn to ọgbọn ya bo oun pe oun mu ọkan lara wọn, lasiko ti wọn n fa ọrọ naa lọwọ ni ibọn ọwọ oun yin ara rẹ to si pa ọkan lara wọn.

Afurasi naa sọ fun ọlọpaa pe baba oun lo ni ibọn naa.

Ọlọpaa ni iwadii n lo lọwọ gbogbo wọn yoo si foju bale ẹjọ laipẹ.