Ó dá mi lójú pé èmi ni gbogbo Oyo yóò dìbò yàn sípò gómìnà ní 2027-Sarafadeen Alli

Sharafadeen Abiodun Alli pẹlu awọn alatilẹyin rẹ. O nawọ soke bii ami ìkíni
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo ọdun to n bọ, Oloye Sarafadeen Alli, ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọmọ Ibadan bii toun ni awọn yoku tawọn jọ n dupo gomina ipinlẹ Oyo, o da oun loju pe oun ni gbogbo Ibadan yoo dibo fun.

‎Ẹ o ranti pe o le ni oludije mẹwaa to fife han lati dupo gomina ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ninu wọn ni Adebayo Adelabu, Rauf Aderemi, Oyedele Akeem, Akeem Agbaje atawọn miran.

Amọ nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Oloye Sarafadeen Alli sọ pe APC gan-an lo fa oun kalẹ, ti Olubadan Ladoja naa si faramọ ọn, nitori ibaṣepọ to ti wa laarin awọn tẹlẹ.

‎"‎Ọgbọn inu ti mo ni ni mo fẹẹ fi ṣe ijọba"

‎Nipa bi yoo ṣe ṣakoso ipinlẹ Oyo bi ipo gomina naa ba ja mọ ọn lọwọ, Sarafadeen Alli sọ pe ninu gbogbo awọn tawọn jọ n dupo gomina ipinlẹ Oyo, oun nikan loun kun oju oṣuwọn ju, nitori iriri toun ti ni ninu oṣelu pọ jọjọ.

‎"Iriri ti mo ni lemi fẹẹ lo lati ri i pe a gbe ipinlẹ Oyo gun oke agba ju bo ṣe wa lọ.

"Ọpọlọpọ nnkan lo ti mẹhẹ nipinlẹ Oyo lonii, to si jẹ pe a nilo ẹni to ni iriri lati tun un ṣe, iru eyi ti emi ni."

Oludije naa ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ọmọ Ibadan ni awọn yoku tawọn jọ n dupo yii, o da oun loju pe oun ni gbogbo Ibadan ati ipinlẹ Oyo lapapọ yoo dibo yan.

O ni boun ko tilẹ lowo lọwọ lati na, iriri ati ọgbọn inu wa lati di ipo naa mu.

Nipa awọn ipo to ti dimu ri, Alli sọ pe ni1991, ilu dibo yan oun gẹgẹ bi Alaga ijọba ibilẹ niluu Ibadan, lati ibẹ loun ti di Akọwe agba fun Rashidi Adewolu Ladoja to jẹ gomina nigba naa.

O ni Aṣoju-ṣofin loun bayii, eyi si ti foun ni imọ to yẹ lati ṣe ijọba ipinlẹ Oyo.

‎ "Baba gbogbo aye ni Olubadan, amọ wọn yoo ṣa faramọ enikan"

Ni itẹsiwaju alaye rẹ nipa pe Olubadan Ladoja fẹran rẹ, Alli sọ pe Baba gbogbo aye ni Olubadan, ọba naa ko si kopa ninu oṣelu mọ.

O ni ṣugbọn Kabiyesi mọ ẹni to daa ju ninu awọn oludije asiko yii.

O fi kun un pe oun ti ba Olubadan ṣiṣẹ ri, ọba naa si ti mọ boun ṣe dangajia to lo ṣe nigbagbọ ninu oun.

‎Oloye Alli sọ pe:

"Ibaṣepọ̀ mi pẹ̀lú Olubadan ló jẹ́ kí wọ́n fẹ́ràn mi nínú gbogbo àwá tí à ń dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo.

O ni irọ ni pe Ọba Rasheed Adewolu Ladoja fa oun lọwọ lọ sọdọ Aarẹ Bola Tinubu lati fonte lu u pe oun ni yoo dupo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Oyo.

Sarafadeen Alli sọ pe aarin oun ati Ọba Ladoja to dan mọnran lo jẹ ki ọba naa fẹran oun to si fi oun ṣe aayo ninu awọn oludije yooku.