Kókó ọ̀rọ̀ tí Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo sọ nígbà tó ta òróró sórí olùdíje sípò Gómìnà APC ní ìpínlẹ̀ Ogun, Solomon Adeola Yayi

Oríṣun àwòrán, Sen Solomon Adeola Yayi/X
Oludasilẹ ijọ Living Faith Church tawọn eeyan mọ si Winners Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo, ti gbawọn ọmọ Naijiria nimọran lati dibo fun ẹni ti yoo mu ilọsiwaju ba orilẹede Naijiria ninu eto idibo to n bọ.
Biṣọọbu naa sọrọ yii lasiko ti oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, Sẹnẹtọ Solomon Adeola Yayi, ṣabẹwo si i.
Oyedepo sọ pe nnkan ti Ọlọrun ba ni ki oun sọ nikan loun maa n sọ.
''Ko si ẹni to tii sọ fun mi pe nnkan ti mo gbọdọ sọ niyii ki n to sọrọ laye.
Idi niyi ti ọpọ eeyan fi n binu si mi, bakan naa ni mi o tii polongo ibo fun ẹnikẹni laye.
N ko si ni i ṣe bẹẹ laelae titi ti mo maa fi kuro laye yii.
Ko si ẹgbẹ oṣelu ti kii wa sọdọ mi fun adura ati imọran, awọn mii maa n telẹ imọran mi.
Awọn mii naa si wa ti wọn maa n kọ eti ikun si imọran ti mo ba fun wọn,'' Biṣọọbu Oyedepo lo sọ bẹẹ.
Biṣọọbu Oyedepo sọ pe awọn to tẹle imọran toun fun wọn n jere rẹ, awọn ti ko si tẹle e naa n jere rẹ ni idakeji.
Oludasilẹ ijọ Winners Chapel ko ṣai rọ awọn ọmọ Naijiria wi pe ki wọn dibo fun ẹni to ba wu wọn.
O rọ awọn eeyan wi pe ki wọn ranti ọjọ ọla awọn ọmọ wọn bi wọn ṣe n dibo.
Oyedepo ni ''ọrọ yii ko ni i ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu kan tabi omiran nitori gbogbo ẹgbẹ oṣelu lawọn ọmọ ẹgbẹ wọn wa ninu ijọ mi.
Koda, awọn oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu wa ninu ijọ yii, bo tilẹ jẹ pe n ko ni bawọn ṣe oṣelu laye.
Alaafia ati ilọsiwaju orilẹede Naijiria ni mo n wa, Naijiria ko wa fun tita.
Eeyan ẹlẹran ara ni wa lorilẹede Naijiria, ẹnikẹni ko nilo lati lowo jaburata ki o to le dije fun ipo aarẹ.
Ẹni to koju oṣunwọn nikan ni a nilo lati jẹ aarẹ orilẹede Naijiria, irufẹ awọn eeyan bẹẹ si wa kaakiri orilẹede yii.
Ẹ jẹ ki gbogbo wa dibo fun ẹni to koju oṣunwọn to le mu ilọsiwaju ba Naijiria.
Ko yẹ ki inira to wa ni Naijiria bayii tẹsiwaju o.
Mo tun fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ko si oloṣelu tabi ijọba kan to n gbowo wa si ijọ yii, ko si nnkan to jọ bẹẹ.''

Oríṣun àwòrán, Sen Solomon AdeolaYayi/X

Oríṣun àwòrán, Sen Solomon AdeolaYayi/X
''Biṣọọbu Oyedepo ti ko ipa ribi ribi lẹka eto ẹkọ, idagbasoke ninu ẹmi ati ṣiṣe aanu fun ọpọ eeyan ti ko rọwọ họri''
Ninu ọrọ rẹ, Sẹnẹtọ Adeola gboṣuba rabandẹ fun oludasilẹ ijọ Winners Chapel papaa julọ lori ipa ribi ribi to n ko lẹka eto ẹkọ, idagbasoke ninu ẹmi ati ṣiṣe aanu fun ọpọ eeyan ti ko rọwọ họri.
Bakan naa ni o tun dupẹ lọwọ pasitọ naa fun adura to gba fun un lasiko to ṣabẹwo si i pẹlu iyawo rẹ, Temitope Adeola.
Sẹnẹtọ Yayi tun ṣabẹwo si gbọngan ile ijọsin nla The Ark ti ijọ Winners Chapel n kọ lọwọ eyi to le gba olujọsin ẹgbẹrun un lọna ọgọrun un lẹẹkan ṣoṣo.
Oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC ni ile ijọsin naa n ṣapejuwe igbagbọ to fẹsẹ mulẹ, ifaraẹnijin ati ifọkansin to rinlẹ.
Yayi ni iru ile ijọsin yii yoo tun jẹ ki ọpọ arinrin ajo afẹ maa wa si ipinlẹ Ogun si i, eyi ti yoo si mu ilọsiwaju ba ipinlẹ naa si i.




























