Ìyá ta ọmọ oṣù kan ní mílíọ́nù méjì náírà n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe oun ti fi ṣinkun ofin mu iya kan ti wọn lo ta ọmọ rẹ ti ko ju ọmọ oṣu kan lọ ni miliọnu meji naira.
Yatọ si iya naa, ọwọ tun ba afurasi ti wọn lo ta ọmọ naa fun, to jẹ ẹni to ni ile igbẹbi to bimọ si.
Awọn tọwọ ba naa bi ọlọpaa ṣe fi lede ni: Iya ọmọ oṣu kan naa; Cecilia Amos; ẹni ọdun mẹtalelogun (23).
Ẹnikeji ni ẹni to ni ile igbẹbi naa (Ebepraise Health Centre), ti wọn pe orukọ rẹ ni Dokita Adeleke Ebenezer, ẹni ogoji ọdun
Wọn pada ri ọmọ naa gba lọwọ wọn bi ọlọpaa ṣe sọ.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
DSP Olayinka Ayanlade, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo to fi iṣẹlẹ naa lede lọjọ Ẹti, ṣalaye pe o waye nijọba ibilẹ Ido, niluu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo.
Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe ṣalaye, iya kan torukọ rẹ n jẹ Mary Amos, lo mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹwaa, pe ọmọ oun, Cecilia Amos, bimọ obinrin sile igbẹbi Ebepraise Health Centre, lọjọ kẹfa oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii.
Iya naa sọ fun wọn pe ọjọ keje lẹyin to bimọ naa tan lo kuro nile pẹlu ọmọ ikoko naa, ko si le sọ pato ibi to gbe ọmọ si nigba to pada de.
Mary sọ pe idi niyẹn ti ara fi fu oun, pe o ṣee ṣe ki ọmọ oun ti ta ikoko to ṣẹṣẹ bi.
Eyi ni ọlọpaa fi mu Cecilia lati beere ọrọ lọwọ rẹ, Alukoro ọlọpaa Oyo si sọ pe o jẹwọ lasiko tawọn n fi ọrọ wa a lẹnu wo.
O ni Cecilia sọ pe Ebenezer ati afurasi kan, Hassan Oludunni, ni wọn tan oun oun lati ta ọmọ naa fun ẹnikam torukọ rẹ n jẹ Odunayo Folawewo.
"Iwadii fi han pe N2m lo ta ọmọ naa"
Ni itẹsiwaju alaye DSP Ayanlade, o ni iwadii fi han pe miliọnu meji ni Cecilia ta ọmọ rẹ, o si gba miliọnu kan naira, nigba ti Ebenezer ati Oludunni gba idaji miliọnu naira ẹnikọọkan bo ṣe sọ.
Lẹyin itọpinpin iṣẹlẹ yii, wọn ri ọmọ oṣu kan naa gba pada, wọn si mu Ebenezer pẹlu.
Ileeṣẹ ọlọpaa Oyo sọ pe igbesẹ ti bẹrẹ lati mu Folawewo naa, ati gbogbo ẹni to ba lọwọ si rira ọmọ ọwọ naa.
Bi araalu ba ni ifisun ti wọn fẹẹ fi to ọlọpaa leti nipinlẹ Oyo, eyi ni awọn nọmba ti ileeṣẹ ọlọpaa ibẹ fi sita pe ki wọn pe: 615 ti wọn ko ni I fowo pe, tabi 08081768614 ati 07055495413.


























