Ọ̀gá àgbà àjọ FRSC Ogun; Oludare Ogunjobi, dágbére fáyé lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tó dépò

Oríṣun àwòrán, Engineer Noimot Salako-Oyedele/Facebook
Ajọ ijọba apapọ to n ri si aabo loju opo; FRSC, ẹka ti ipinlẹ Ogun, ti kede ipapoda olori wọn; Kọmanda Oludare Ogunjobi.
Oni ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni Alukoro FRSC Ogun, Afolabi Odunsi, fi atẹjade to kede iku naa sita.
Oṣu mẹfa lẹyin ti Ogunjobi gba ipo naa lo dagbere faye yii.
"Àdánù nla ni iku Ọga Ogunjobi"
Atẹjade ti Alukoro FRSC ipinlẹ Ogun buwọlu naa ṣalaye, pe lẹyin aisan ranpẹ ni Oloogbe Ogunjobi dagbere faye.
"Adanu nla ni iku rẹ jẹ fun ajọ yii, awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ ati gbogbo FRSC pata.
"A o maa ranti rẹ fun iṣẹ to ṣe, idari ati iṣakoso, titi kan iduroṣinṣin pẹlu ohun ti FRSC duro fun."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.
Wọn fi kun un pe Oloogbe Ogunjobi sa ipa rẹ lati ri i pe aabo wa loju ọna.
Wọn lo gbiyanju nipa lila awujọ loye, ati ki wọn le tẹle ofin irinna gbogbo.
Ajọ naa ba awọn ẹbi Kọmanda Ogunjobi kẹdun, wọn si ni alaye nipa isinku rẹ yoo jade nigba ti asiko ba to.
Ọjọ kọkanla oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni Kọmanda Oludare Ogunjobi, gba ipo olori ẹka naa niluu Abeokuta, ipinlẹ Ogun.
Kọmanda Akinwunmi Fasakin lo kuro nipo naa ti Oloogbe Ogunjobi fi bọ sibẹ, ko too di pe ọlọjọ de lẹyin oṣu mẹfa to gba ipo naa.
























