Láti ọdún 1996 ni mo ti ní àrùn itọ ṣúgà, bí mo ṣe ń tọ́jú ara mi rèé – Jide Kosoko

Oríṣun àwòrán, Prince Jide Kosoko/Instagram
Agbaọjẹ oṣere tiata nni, Ọmọba Jide Kosoko, ti sọ pe lati ọdun 1996 tii ṣe ọgbọn ọdun sẹyin loun ti ni aisan itọ ṣuga.
Ọmọba Kosoko to fi idi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu Africanalist ni oun n tọju ara oun tori oun ko fẹ ku.
Agba oṣere naa sọ pe laipẹ yii ni wọn tun sọ foun pe wọn fẹ wo gbogbo nnkan to wa ninu oun lati mọ boya arun jẹjẹrẹ ti wa ni ibikan.
O ni wọn kọkọ kun oun ni oorun ki wọn to le ṣe iṣẹ naa ninu agọ ara oun.
''Ọrọ agọ ara mi ye mi ju awọn dokita mii gan an lọ.
Ọpọ eeyan ni ko bikita ti wọn n mu siga kiri, igbo lawọn miran tiẹ n mu.
Bakan naa ni ọpọ tun sọ ara wọn di ọmuti, wọn a wa sọ ara wọn di ẹni to n tọrọ owo ti aisan ba de.
Nigba naa ni ọpọ eeyan yoo maa sọ pe awọn oṣere kii ran ara wọn lọwọ.
Onikaluku lo yẹ ko tọju ara rẹ, ko tii pọju ti eeyan ba le na ida 20% owo to ba n ri lori ilera ara rẹ.
Ọpọ awọn ololufẹ wa gan an ni wọn ko mọ bi awa oṣere ṣe n ran ara wa lọwọ si,'' Ọmọba Jide Kosoko lo sọ bẹẹ.
Ọmọba Kosoko tun fidi rẹ mulẹ pe oun wa lara awọn to da ere ori itage silẹ ni Naijiria.
O ni ọdun 1964 loun bẹrẹ iṣẹ tiata nigba toun wa ni ẹni ọdun mẹwaa.
Agba oṣere naa fikun ọrọ wi pe ọdun 1972 loun da ẹgbẹ oṣere toun funra oun silẹ.
Gbajumọ oṣere naa tun ṣalaye pe ẹru n ba ọpọ oṣere nigba ti itakun ayelujara ṣẹṣẹ de.
Amọ, o ni itakun ayelujara ti wa di nnkan tawọn oṣere n lo bayii ti o si n ṣe anfaani fun wọn.
Ọmọba Kosoko ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn kan ṣi n lo itakun ayelujara ọhun lọna aitọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post



























