Kí ló lè fa kí òkúta rìgìdì tó tóbi tó ọmọ ìkókó wà nínú àpò ilé ìtọ̀ ọkunrin?Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Trincomalee General Hospital
Okuta rigidi ti iwọn rẹ ko din ni 3.1kg, eyi to jẹ iwọn ti awọn ọmọ ikoko mi-in maa n wọn loojọ ti wọn bi wọn ni awọn dokita ti gbe jade bayii ninu ọkunrin kan lorilẹede Sri Lanka.
Apa ibi ti itọ maa n wa ninu eeyan ni okuta ọhun wa, ọsẹ to kọja yii ni wọn si gbe e jade pẹlu iṣẹ abẹ nileewosan ni Trincomalee, Ila Oorun Sri Lanka.
Okuta yii ni igbagbọ wa pe o tobi ju ninu itan awọn ti wọn ti gbe iru rẹ jade lara wọn ri lagbaaye.
Ohun to ṣẹlẹ gan-an
Ẹni ọdun marundinlọgọta (55) ni alaisan ti wọn yọ okuta naa lara rẹ gẹgẹ bawọn dokita to ṣiṣẹ abẹ naa ṣe wi.
Arun rọparọsẹ ni wọn tori ẹ gbe e wa sile iwosan tẹlẹ, amọ nigba to n gba itọju lọ, awọn dokita ri i pe awọn okuta kan wa ninu apo itọ rẹ.
Wọn ṣe akiyesi yii lẹyin ti wọn ri i pe baba naa ko le mi daadaa.
Eyi lo mu wọn ṣeto iṣẹ abẹ fun un, ti wọn si gbe okuta to tobi to ọmọ tuntun jade, bẹẹ ni wọn tun fi we odiwọn ẹyin ẹyẹ ogongo.
"Gẹgẹ bi akọsilẹ ti a ni ṣe fi han, okuta yii lo tobi ju ninu awọn okuta ti wọn ti gbe jade lapo itọ ri lagbaaye."
Dokita Prahalahan Balakrishnan, to lewaju iṣẹ abẹ naa lo ṣalaye bẹẹ fun BBC Sinhala.
O ni o kere tan, okuta naa yoo ti wa ninu apo ile itọ ọkunrin yii lati bii ọdun marun-un si mẹwaa sẹyin.
Bawo ni okuta ṣe n de apo itọ?

Oríṣun àwòrán, Trincomalee General Hospital
Bawo ni okuta ṣe n de apo itọ?
Awọn okuta ninu apo itọ yii maa n parapọ di odidi nigba ti awọn eroja kan ninu itọ ba dipọ, ti wọn di koko.
Eyi maa n saba ṣẹlẹ nigba ti itọ ko ba jade tan ninu apo itọ, to fi awọn itọ kan silẹ nibẹ.
Awọn itọ ti yoo ti toró naa ni yoo pada di okuta apo ile itọ fun eeyan.
Awọn dokita ṣalaye pe awọn okuta kekere ti ko ju deede iyanri tabi koro irẹsi lọ le kọja pẹlu itọ funra wọn.
Ṣugbọn okuta to ba ti gun kọja sẹntimita kan maa n di oju ọna ti itọ n gba ni, o si nilo ki eeyan tete lọ sile iwosan.
Okuta to ba tobi ju sẹntimita mẹrin lọ ni wọn ka si pe o tit obi.
Gẹgẹ bi iwe akọsilẹ itan iṣẹlẹ agbayanu agbaye.




























