Wo àwọn ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Victoria Oluwakotanmi, ọmọ Naijiria-America tó gba adé Omidan 'Grand USA 2026'

Oríṣun àwòrán, Instagram | officialmissgrandusa, tori_olu
Ọdọmọbinrin kan ti orirun rẹ jẹ Naijiria,paapaa to ti ilẹ Yoruba wa, Victoria Oluwakotanmi, ti gba ade Omidan Grand USA bayii, lorilẹde America.
Oluwakotanmi, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) to n gbe lorilẹede America tun jẹ ọmọ ilu San Antonio, niluu America pẹlu.
Ipo keji ni Victoria kọkọ ṣe ninu idije awẹlẹwa naa nigba ti aṣekagba rẹ waye lọjọ kẹwaa oṣu Kẹjọ ọdun 2026.
Amọ o pada bọ si ipo kin-in-ni lẹyin tawọn alakooso Miss Grand USA fagile aṣeyọri Mekayla Li, ẹni to ṣe ipo kin-in-ni naa tẹlẹ.
Wọnyi ni awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Victoria Oluwakotanmi

Oríṣun àwòrán, Instagram/@officialmissgrandusa, @crownlegacyllc
- Ọmọ orilẹede Naijiria ati America ni: ọpọ igba lo si ti ṣalaye pe Naijiria ni orirun oun, ati pe arinrinajo silẹ America ni awọn obi oun, amọ ti wọn n gbe l'America.
- Nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin ni baba rẹ lọ si America, gẹgẹ bi ọmọbinrin naa ṣe ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo kan.
O ni abọ̀ ìjẹun ni baba oun tilẹ kọkọ n fọ nigba to de, ko too kawe to si gba oye Ọmọwe ninu iṣẹ nọọsi.
- San Antonio, Texas, tawọn obi rẹ n gbe naa lo dagba si.
- Ọmọ ogun ori omi ni
Ṣaaju ni Victoria ti darapọ mọ iṣẹ ologun oju omi America.
Ọdun 2019 lo darapọ mọ wọn gẹgẹ bii onimọ nipa lilọ bibọ awọn ohun elo, wọn si mọ ọn daadaa ni San Antonio-Fort Sam, Houston.
- Kikopa ninu idije Awẹlẹwa
Oṣu Keji ọdun 2020 ni Oluwakotanmi bẹrẹ irinajo idije awẹlẹwa, eyi to ti kopa nigba naa ni Omidan Adulawọ (Miss Black) ni San Antonio.
O pada gba ti Miss Grand Illinois, o si tun kopa ninu ti Omidan Texas.

Oríṣun àwòrán, Victoria Oluwakotanmi/Facebook
- Iwe to ka
Omidan Grand USA yii kẹkọọ nipa imọ ẹrọ ti a mọ si Chemical Engineering, ni Northwest Vista College.
Ajọ to gbe kalẹ
Oluwakotanmi atawọn obi rẹ da ajọ kan ti wọn pe ni Oluwakotanmi Promise silẹ ni 2018, eyi to wa fun ẹkọ ofẹ ati ilaniloye lori ẹkọ iwe.
Wọn gbe ajọ yii kalẹ ni iranti iya agba rẹ, ẹni ti ko ni anfaani ati lọ sile ẹkọ girama nitori won lo jẹ obinrin.
- Oni ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹjọ 2026 ni awọn alakooso eto naa kede pe :"USA, eyi ni Omidan Grand USA 2026… VICTORIA OLUWAKOTANMI."
- Oluwakotanmi ni yoo gbe ade America yii lọ ṣoju orilẹede naa nibi idije Miss Grand International.



























