Wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn àgbà òṣèré tíátá wọlé àdúrà fún Taiwo Hassan Ogogo lórí àìsàn Jẹjẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Solanke Ayomikun Kenny/Facebook Taiwo Hassan Ogogo/Instagram
Lọjọ Ẹti to kọja yii, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni awọn agbaagba nidi oṣere tiata, paapaa ẹka ti Yoruba dide adura fun ọkan lara wọn, Taiwo Hassan tọpọ awọn eeyan mọ si Ogogo.
Ogogo lo wa lori idubulẹ aisan jẹjẹrẹ to ti n ba a finra lati bi ọjọ pipẹ sẹyin.
Inu gbọngan Babajide Olushola Sanwo-Olu ti ileeṣẹ amohunmaworan tipinlẹ Eko, LTV 8 to wa lagbegbe Agidingbi ni eto adura ọhun ti waye, lati fi ifẹ han si ọsere naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin jade sita wi pe Ogogo wa lori idubulẹ aisan jẹjẹrẹ, ati pe aisan naa ti de gongo.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Aje ọsẹ yii ni awọn ọmọ Ogogo meji, Kira ati Lima Hassan, fi omije kede pe baba awọn ti ni aisan jẹjẹrẹ to ti wa ni ipele kẹrin.
Awọn ọmọ mejeeji sọ pe kii ow oni awọn nilo, bi ko ṣe iranlọwọ itọju yala ti oloyinbo tabi ti ibilẹ ni awọn nilo, lati le jẹ ki ara baba awọn ya, ko si pada sori ẹsẹ rẹ mejeeji.
Latigba ti iroyin ọhun ti jade ni ọpọ awọn oniṣegun ibilẹ to le ni ọọdun ti dide, lati sọ pe awọn ṣetan lati ṣe iranlọwọ fun agba oṣere ti aye n gba tiẹ naa.
Ṣugbọn ṣa, awọn agbaagba nidi iṣẹ naa ti wa fi imọriri han si awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn fi ifẹ han si oṣere akẹgbẹ wọn, ti wọn si lawọn ti bẹrẹ igbesẹ fun itọju.
Àwọn wo ló wà níbi ètò àdúrà náà?
Ogunlọgọ awọn agba ati ilu mọ-ọn-ka oṣere ni wọn wa nibi akanṣe eto adura naa to waye lọsan ọjọ Ẹti.
Awọn agbaagba bii Bolaji Amusa (Mr Latin) to jẹ aarẹ ẹgbẹ TAMPAN; Jide Kosoko, Yinka Quadri, Fausat Balogun (Madam Saje), Antar Laniyan Bukky Wright, ati Yomi Fash-Lanso ni wọn wa nibẹ.
Awọn miran ni Hassanat Akinwande, Lateef Adedimeji, Toyosi Adesanya, Yemi Ayebo atawọn miran ti a ko le darukọ tan ni wọn wa nibẹ.
Yatọ si awọn wọnyi, awọn agbaagba nidi ẹsin Isilaamu ni wọn wa nibẹ, lati lewaju eto akanṣe adura ọhun.




























