Tinubu wọlé ìbò abẹ́nú APC láti díje fún ipò ààrẹ lẹ́ẹ̀kejì, iye ìbò tó rí rèé

Aarẹ Bola Tinubu wọ agbada buluu pẹlu fila

Oríṣun àwòrán, APC Nigeria/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti wọle ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC lati dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria lẹẹkeji.

Tinubu ri ibo to le ni miliọnu mẹwaa eyi to fi la alatako rẹ, Stanley Osifo, mọlẹ ninu eto idibo ọhun.

Gbogbo ibo ti Ọgbẹni Osifo ri ko ju 16,504 lọ lati wọọdu 8,809 kaakiri orilẹede Naijiria lẹyin ti wọn ka gbogbo ibo naa tan.

Sẹnẹtọ Pius Anyim lo kede esi ibo naa lonii ọjọ Aiku ọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun un yii.

Lati igba ti wọn ti n ka ibo naa lo ti foju han pe Aarẹ Tinubu ni yoo bori.

Lẹyin ti Sẹnẹtọ Anyim kede esi ibo naa tan ni Tinubu gba iwe ẹri ati asia ẹgbẹ APC lati dupo aarẹ fun saa keji.

Gọmina mọkanlelọlọgbọn atawọn agbaagba ẹgbẹ lo ko esi ibo abẹnu lati awọn ipinlẹ lọ si Abuja nibi ti wọn ti ka a.

Ni ẹkun iwọ oorun guusu, Tinubu ri ibo 814,988 nipinlẹ Eko, 322,485 l'Ogun, 181,996 l'Ondo, 142,754 l'Oyo, 100,888 ni ipinlẹ Osun, nigba to ri ibo 85,340 l'Ekiti.

Osifo ri ibo 1,186 nipinlẹ Eko ati 929 l'Oyo, nigba ti ko ri ibo kankan lawọn ipinlẹ yooku nilẹ Yoruba.

Ni ẹkun iwọ oorun ariwa, Aarẹ Tinubu ri ibo 618,914 nipinlẹ Kaduna, 500,852 ni Kano, ibo 467,003 ni aarẹ ri ni Katsina, 450,517 ni Gombe, 292,972 ni Kebbi, 301,000 ni Sokoto, bakan naa lo tun ri ibo 321,579 ni Zamfara.

Osifo tun lulẹ ni ẹkun iwọ oorun ariwa lẹyin to ri ibo perete nibẹ.

Ibo 10,999,967 ni Tinubu ri lapapọ, nigba ti Osifo ri 16,504

Ni ẹkun aarin gbungbun ariwa, Tinubu ri ibo 310,990 nipinlẹ Kwara, 285,436 ni Nasarawa, 241,720 nipinlẹ Plateau.

Ibo 197,370 ni aarẹ ri nipinlẹ Kogi, 175,487 ni Niger, ati 374,787 nipinlẹ Benue.

Aarẹ Tinubu ri ibo 36,103 ni Abuja ti i ṣe olu ilu orilẹede Naijiria, nigba ti Osifo ko ri ibo kankan nibẹ.

Aarẹ tun la alatako rẹ mọlẹ lẹkun ila oorun guusu ati ẹkun Guusu.

Ibo 582,960 ni Tinubu ri nipinlẹ Imo, 383,382 ni Enugu, 207,579 ni ipinlẹ Ebonyi, 161,005 ni Abia, ati 43,034 ni ipinlẹ Anambra.

Tinubu ri 407,646 ibo ni ipinlẹ Delta, 389,197 ni Akwa Ibom, 280,082 ni Rivers, ati 227,192 ni ipinlẹ Bayelsa.

Osifo ri ibo1,007 nipinlẹ Abia ati 384 ni Anambra.

Lẹyin ti wọn ko gbogbo ibo naa jọ tan ti wọn si ka a, ibo 10,999,967 ni Tinubu ri, nigba ti Osifo si ri 16,504.