Agbébọn tún yabo Orí Òkè ìṣọ́ òru ní Kwara, jí èèyàn 15 gbé, pa mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi iroyin ijinigbe to sọ awọn olukọ ati ọpọ akẹkọọ di ẹni igbekun niluu Ogbomoso, nipinlẹ Oyo ṣe n lọ lọwọ, awọn agbebọn tun ti yabo ibudo isọji nipinlẹ Kwara.
Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, SP Adetoun Ejire-Adeyemi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣe wi, eeyan mẹẹẹdogun ni wọn ji gbe lọ, wọn si yinbọn pa eeyan mẹta.
Nibo ati nigba wo leyi ṣẹlẹ?
Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Kwara fi ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, eyi yo fi lede lọjọ Aiku oni lo ti ni :
"Ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Pasitọ Adebayo Abiodun, lo mu ifisun wa lọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun-un ọdun 2026, pe awọn ajinigbe yabo ori Oke Ijo Ajaye ati Igbala, l'Abule Ẹkẹrin, nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, lọjọ Satide, ọjọ kẹtalelogun oṣu Karun-un ọdun 2026.
"Pasitọ Adebayo ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ, lasiko ti eto iṣọ oru naa n bẹrẹ ni awọn janduku kan yade ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.
"Lasiko ti wọn n yinbọn naa ni wọn pa eeyan mẹta ti wọn si gbe mẹẹẹgogun lọ."
DSP Adetoun sọ pe bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe gbọ nipa ifisun naa ni ikọ ọlọpaa ti gbera lọ sibẹ, ti kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, Adekimi Ojo, si ran ikọ ọtẹlẹmuyẹ lọ pẹlu.
Alukoro ọlọpaa ṣapejuwe ikọlu yii bii ohun to buru jai ti ko si ṣe e gba mọra rara.
O fi da ẹbi awọn eeyan ti wọn gbe lọ atawọn ti eeyan wọn di oloogbe loju, pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo mu awọn to wa nidii iṣẹ ibi naa.
Bakan naa lo rọ araalu lati ṣe suuru, ki wọn si foju ṣọri.
O ni ki wọn maa ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo kia bi wọn ba ri nnkan ifura.
SP Adetoun fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa Kwara yoo maa fi to araalu leti bi ohun gbogbo ba ṣe n lọ.


























