Ìjọba Amẹrika gbé igbésẹ̀ tuntun lórí ọ̀nà àti gba ìwé ìgbélùú 'green card'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Amẹrika ti rọ awọn ọmọ Naijiria atawọn ọmọ orilẹede mii to n gbe nibẹ ti wọn fẹ gba iwe igbelu 'green card' ki wọn pada si orilẹede wọn lati bẹrẹ igbesẹ naa lakọtun.
Aṣẹ yii lo jade ninu atẹjade kan lati ọọfisi ajọ US Citizenship and Immigration Services, USCIS.
Wọn ni igbesẹ naa ko ṣẹyin ati da erongba aba ilẹ Amẹrika lati maa fun awọn eeyan ni iwe igbelu pada si bi wọn ṣe bẹrẹ rẹ ṣaaju.
Agbẹnusọ USCIS, Zach Kahler sọ pe igbẹsẹ ti ijọba wọn gbe yii yoo ran wọn lọwọ lati din iye eeeyan to n gbe nilẹ naa lọna aitọ ku.
Atẹjade ọhun ni gbogbo eeyan ni ọrọ yii kan yatọ si awọn kan.
To n tumọ si pe gbogbo ọmọ ilẹ okere to wa nilẹ Amẹrika amọ to fẹ gba iwe igbelu lati maa gbe nibẹ fun ọjọ pipẹ yoo nilo lati bẹrẹ igbesẹ ọhun ni nilẹ wọn labẹ akoso ọọfisi ajọ United States Department of State.
Ajọ naa sọ pe awọn n fẹ ki awọn ọmọ ilẹ okere to fẹ maa gbe nibẹ gba ọna to ba ofin mu lai lọ ọna alumọkọrọyi.
O ni "Lati akoko yii lọ, ajeji to ba wa l'Amẹrika to si fẹ gba iwe igbelu gbọdọ pada si orilẹede rẹ lati lọ bẹrẹ igbesẹ naa, ayafi fun awọn abala eeyan kan."
"Ofin yii yoo gba eto irinkerindo silẹ wa laaye lati ṣiṣẹ bo ṣe yẹ dipo ki awọn kan maa lo anfani alafo to wa nibẹ.
"Ti wọn ba bẹrẹ igbesẹ naa lati orilẹede wọn, yoo fun wa lanfani lati mọ awọn to fẹ fi ọgbọn alumọkọrọyi maa gbe ni Amẹrika lọna ti ko ba ofin mu."
Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe ṣalaye, awọn ti igbesẹ tuntun yii yoo ṣe ipalara fun julọ ni awọn alejo to lọ sibẹ fun akoko diẹ bii awọn akẹkọọ, awọn arinrinajo afẹ atawọn oṣiṣẹ to wọ Amẹrika gẹgẹ bii alejo.
Wọn ni "Awọn alejo bii awọn akẹkọọ, awọn to wa ṣiṣẹ fun igba diẹ tabi awọn arinrinajo afẹ wa si Amẹrika fun igba diẹ ni, o si ni eredi ti wọn fi wa.
"Eto wa ni pe ki irufẹ eeyan bẹẹ pada si orilẹede rẹ ti ọjọ ba ti lọ lori fisa ti a fun wọn."


























