Èsì àyẹ̀wò òkú Destiny Boy tí ìjọba ṣe ṣàfihàn ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀

Ọdọmọde olorin Fuji, Afeez Adeshina, ti ọpọ mọ si Destiny Boy wọ ẹwu, o si fọwọ kan si agbọn rẹ

Oríṣun àwòrán, Temilola Sobola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Esi ayẹwo oku ọdọmọde akọrin Fuji, Afeez Adeshina, ti ọpọ mọ si Destiny Boy ti ṣafihan nnkan to ṣokunfa iku rẹ.

Lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kinni ọdun 2026 yii ni ọdọmọde olorin naa ku lojiji lẹni ọdun mejilelogun.

Bi iku rẹ si ṣe ka ọpọ eeyan lara lọ je ki wọn rọ ijọba lati ṣe ayẹwo oku rẹ ki wọn si fidi nnkan to ṣekupa a mulẹ.

Oniruuru fidio lo jade lori itakun ayelujara eyi to ṣafihan bi wọn ṣe n gbe oku rẹ lọ si mọṣuari pẹlu owu ni imu ati eti rẹ.

Awọn kan tiẹ sọ pe ile Babalawo lo ku si nitori oṣolẹ ni o ṣe bo ya lati ni okiki tabi lati lowo.

Ẹnikan tun ṣalaye nnkan to ṣee ṣe ko pa Destiny Boy ninu fidio kan nibi to ti ṣalaye pe aisan kan ti n ba ọdọmọde akọrin naa finra fun igba diẹ ki o to gbẹmi rẹ.

Awọn ẹbi rẹ naa jẹrii wi pe o ti pẹ ti aisan kan bii giri ti maa n mu un.

Mama rẹ Saida si sọ fun gbogbo eeyan lori itakun ayelujara wi pe oun ti wa itọju lọ sile iwosan ati lọdọ awọn oniṣegun ibilẹ fun Destiny Boy.

Lẹyin o rẹyin ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun kede wi pe awọn ti mu afurasi kan lori iku akọrin Fuji naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Babaseyi Oluseyi, si sọ pe awọn ti gbe ẹjọ naa lọ si ẹka SCID ọlọpaa fun iwadii kikun.

Esi ayẹwo oku Destiny Boy jade lẹyin oṣu meji

Amọ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa DSP Babaseyi sọ fun iwe iroyin Daily Trust lanaa ọjọ Ẹti wi pe ayẹwo oku Destiny Boy fidi rẹ mulẹ pe apọju oogun Tramadol ati methamphetamine wa lara ọdọmọde olorin naa.

Esi ayẹwo oku rẹ gẹgẹ bi agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ fidi rẹ mulẹ pe apọju oogun yii lo ṣokunfa iku Destiny Boy.

Destiny Boy bẹrẹ si di ilumọọkan lodun 2019 lẹyin to gbe ẹda orin Davido ti akọle rẹ n jẹ ''If'' jade.

Bakan naa ni o tun ṣe ẹda orin awọn akọrin bii Tekno, 2Baba, 9ice, ati Small Doctor.

Oun naa lo gbe awọn orin 'pẹlu akọle ''Lamba', 'One Transaction', 'Gbese', 'Billion Dollar', 'Mio Gbonkankan', ati 'Lowkey' jade.

Destiny Boy ati iyawo rẹ, Iremide bi ọmọ wọn akọkọ loṣu Kọkanla ọdun 2024.

Ta a ni Destiny Boy gan-an?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Afeez Adeshina gan-an ni orukọ rẹ, ṣugbọn Destiny Boy ni orukọ ti gbogbo eeyan mọ ọn si.

Ọmọ ilu Abeokuta ni, agbegbe Obantoko ni wọn ti bi i.

Destiny Boy pọ lọwọ iya rẹ, oun nikan ṣoṣo ni iya naa bi, koda, ọpọ eeyan maa n ro pe anti rẹ ni obinrin naa, nitori iya paapaa ko ti i fi bẹẹ dagba.

Baba rẹ bi awọn ọmọ miran ṣaa. Iya ati baba rẹ ko si fẹra wọn mọ tipẹ.

Bi ọjọ ori Destiny Boy ṣe kere to, oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii lo ṣi ile tuntun to kọ.

Bẹẹ ni a gbọ pe mọto to n lo fẹre to aadọta miliọnu naira (50m).

Ọdun 2024 ni Oloogbe Destiny Boy di ọlọmọ laye, nigba ti ọmọbinrin ti wọn jọ n fẹra wọn bimọ fun un.

Koda, nigba ti yoo ni ki ọmọbinrin naa fẹ oun gẹgẹ bii ọkọ rẹ tootọ, oruka Dayamọndi ẹlẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni wọn lo fi fun un.

Awọn to sunmọ Destiny Boy sọ pe o maa n mu ọti pupọ, eyi ti ọpọ eeyan to fẹran rẹ maa n koro oju si, ti wọn si maa n kilọ fun un.

Musulumi ni Destiny Boy, bo ṣe jẹ onifaaji naa ni wọn tun ni o fẹran ẹsin, to si maa n sin Oluwa.

Bakan naa lo si tun ṣẹ Ifa pẹlu, Oba Edu Ifayomi naa ni wọn lo ṣẹ Ifa fun un.